Atakóró wọnú wínní-wínní 3| Fààbú sáyẹ́ǹsì láti ọwọ́ Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀
Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Atakóró wọnú wínní-wínní 1
Atakóró wọnú wínní-wínní 2
Lẹ́yìn ti wó̩n ti s̩àlàyé èyí yékéyéké fun ara wó̩n tí Ìmó̩wùnmí sì ti so̩ wípé ó yé òun yékéyéké, Ìrínìmò̩ bàbá Ìmó̩wùnmí wò ó pé è̩kó̩ tí òun kó̩ o̩mo̩ náà lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ti pọ̀ jù, kò sí fé̩é̩ jẹ́ kí è̩kó̩ kíkọ́ náà sú u. Ó bè̩rè̩ síí pògèdè, o̩mo̩ rè̩ sì ń wò ó tìyanu-tìyanu pé èwo ni bàbá òun tún gbé dé yìí. Ìrínìmò̩ wípé:
“Bí o̩mo̩dé bá sáré tete títí, á rè̩ é̩ á dúró
Bágbà bá sáré tete títí á rè̩ é̩, á dúró
Bó ti wù kí abẹ̀bẹ̀ òyìnbó sáré tó,
Bíná bá lo̩ yóò dúró
Ó yá, ìwọ ohun tí ǹ jù ràìn-ràìn yìí,
Dúró jẹ́jẹ́ ká lè rí o̩.”
Bi Ìrínìmò̩ ti so̩ èyí, ó jọ bíi pé ẹnìkan ré̩rìn-ín nínú ò̀okùn ló̩hùn-ún, Ìmó̩wùnmí wò ó pé irú è̩rín tí ìyá òun máa n rín lèyí, s̩ùgbó̩n kò rẹ̀níkan. Ìrínìmò̩ kọjú só̩mo̩ rè̩, ó sì so̩ pé, “ṣé ò ń fi ohun tí à ń ṣe ré̩rìn-ín ni? Òògùn yìì kò níí jẹ́!” Ọmo̩ọ̀ rè̩ ní òun kó̩ ni òun ré̩rìn-ín, wó̩n sì ń báṣẹ́ wó̩n lọ. Ó jọ bíi pé ẹni tó ń ré̩rìn-ín náà ti gbọ́ àrokò tí wó̩n pa ránṣé sí i. Ó di wélo.
Nígbàti wó̩n yóò sì fi wo ibi tí wínnípin (atom) náà wa, ó ti tóbi tó odidi ilé ńlá kan. Inú Ìmó̩wùnmí ń dùn pé fèrè òun s̩iṣé tí wọ́n rán an. Bí wó̩n ti sún mọ́ ọ, wó̩n rí i pé àwo̩n ohun ródóródó kan ni ohun tí ń jù fìrìfìrì yì i ká tí kò dúró sójú kan. Ìrínìmò̩ bè̩rè̩ ò̩rò̩ rè̩ wípé:
“Àwo̩n ohun tóò ń wò yìí là bá pè ní eléro (electron) nítorí pé agbára rè̩ wà ní èro (negatively charged). Àwo̩n wò̩nyí sì dàbí ayíbiri (planet) bí o ti wí lẹ́ẹ̀kan. Nínú ìs̩o̩wó̩-wà-létò wínnípin, eléro yìí ń sáré yíká kókó kékeré kan tó wà làáárín. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín bí wínnípin àti bí ido-ayíbiiri-móòrùn (solar system) tiwa tiri ni pe àwo̩n eléro tó dúró gé̩gé̩ bíi ayibiiri wà létò létò lójú ìpòòyì won, méjì sì lè wà ní ìfè̩gbé̩kè̩gbé̩ lórí òbìrí-ìyíbiiri (orbit) kan s̩os̩o. Ohun tó wà láàárin gbùngbùn ló̩hùn-ún là ń pè ní e̩lé̩rò̩ (proton) nítorí pé agbára rè̩ wà ní è̩rò̩ (positively charged). A óò sì lo̩ ba eléyìí tó bá yà.”
Ìmó̩wùnmí ya àwòrán gbogbo ohun tó rí náà sínú ìwé pélébé o̩wó̩ọ rè̩ níwọ̀n bó ti s̩e lè gbìyànjú kó jọra tó. Ó sì tún ko̩ orúko̩ àwo̩n ẹ̀yà ara rè̩ si lára báyìi:
Bàba rè̩ wo ohun tó yà sínú ìwé, inú rè̩ sì dùn. Bàbá náà ń bá ò̩rò̩ rè̩ lo̩ báyìí:
“Ìtò lẹ́sẹsẹ eléro lórí òbìrí-ìyíbiiri nínú wínnípin yìí là ń pè ní ìs̩o̩wó̩wàlétò eléro (electron configuration). Mo fẹ́ kóo fi ọkan sóhun tí mo tún fé̩é̩ so̩ láti ìsin yìí lo̩ dáadáa nítorí pé wó̩n s̩e pàtàkì púpò̩. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ni ó dáhùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìníèròjà-ibambaye tó jé̩ ojúlówó (pure element) tí kìí s̩e àdàlú tàbí àbùlà (compound). Òbìrí-ìyíbiiri yìí náà tún jẹ́ ìpele agbára (energy level) inú wínnípin. Òun ló sì fà á tí ohun gbogbo nínú ayé fi ní owúra (mass). Bí a bá wo wínnípin yìí dáadáa, a óò fé̩rè̩ lè so̩ pé òfifò ni gbogbo rè̩, nítorí ká tóó lè de ibi tí ààrin gbùngbùn àti kókó e̩lé̩rò̩ (nucleus) rè̩ wà, wínnípin yóò ti fé̩rè̩ wú ní títóbi tó odidi orílẹ́-èdè kan ká tó lè rí kókó e̩lé̩rò̩ àárin náà bíi o̩sàn-àhómu. Síbẹ̀, àjọṣepọ̀ ńlá ń bẹ láàárín atakókó àárin tó jẹ́ kókó náà àti eléro tí ń yí i ká ló̩nà jíjìn réré sí i. Ìfànfà tó ń wáyé láàárín agbára èro àti è̩rò̩ àwo̩n méjéèjì yìí ló sì jẹ́ kí gbogbo ibi tí a rò wípé ó ṣófo láàárín wó̩n náà jẹ́ gbalasa-àrádòǹfà (electromagnetic field). Inú rè̩ sì ni gbogbo eléro tí wínnípin kan bá ní tí ń yí wà. S̩ùgbó̩n sá, ní ìpele ìpele bí as̩o̩ àlùbó̩sà ni òbìrí-ìyíbiiri àwo̩n eléro náà wa, bé̩è̩ gé̩gé̩ ni wó̩n sì s̩e ní agbára sí. Ìpele èyí tó sún mó̩ àárin ló ní agbára tó kéré jù. Ìpele tó tún po̩wó̩ lé e ló tún lágbára tó pò̩ díè̩ sí, bé̩è̩ títí dé ìpele tó parí sí ìta, ìyẹn nìpele tí òbìrí-ìyíbiiri rè̩ fè̩ jù; òun ló lágbára tó pọ̀ jù.”
Ìmó̩wùnmí tún ya àwòrán mííràn nípa nǹkan wò̩nyí:
Òbìrí-ìyíbiiri tó kẹ́yìn yìí ló dà bí ọgbà tàbi ìkaraun(shell) tó s̩e ìpinyà àti ààlà láàárín wínnípin kan sí èkejì. E̩lé̩rò̩ àti eléro sì ti fi agbára-aradonfa mu ara wó̩n dúró lójú òbìrí-ìyíbiiri kan títí láé àfi bí ọ̀kan bá ṣèèsì tasè̩ àgè̩rè̩ wo̩ gbalasa wínnípin (valence) òmíràn. Ó s̩eé s̩e kí èyí wáyé, yálà ó s̩èès̩ì s̩e̩lè̩ nínú àbámáyé ni tàbí o̩mo̩-ènìyàn mò̩ó̩mò̩ s̩okùnfàa rè̩. Ìtasè̩-àgè̩rè̩ eléro wo̩ gbalasa wínnípin òmíràn ni ìbè̩rè̩ pẹ̀pẹ̀ ohun gbogbo tiis̩e ẹlé̩mìí, ìmò̩ó̩mò̩ s̩okùnfàa rè̩ ló sì bí gbogbo è̩ro̩ tí ń lo iná-mò̩nàmó̩ná láti s̩is̩é̩, ìyẹn gbogbo è̩ro̩-alonás̩is̩é̩ (electronics).
Ìwọ o̩mo̩ọ̀ mi, mo wá fé̩ kó mo̩ ohun kan nípa inú wínnípin àti àyíká rè̩, èyí sì ni pé, bí ò̩nà eléro ti jìnà sí ata-kókó-àárin (nucleus) tó ní agbára rè̩ pọ̀ tó, bó sì ti súnmó̩o̩ sí ni agbára àrádòǹfà (electromagnetic force) náà s̩e ń dín kù sí. Ìtumọ̀ èyí ni pé, agbára-ìjá-fáfá àwo̩n eléro tó wà nínú kò tó tàwo̩n eléro tó jìnà sáàárín. Fún àpe̩e̩re̩, bí a bá fún àwo̩n òbìrí-ìyíbiiri náà ní àpèlé láti orí èyí tó wà nínú àti èyí tó pọwọ́ lé e títí dé èyí tó wà lóde, ipò-agbára èyí tó wà lóde ni yóò pọ̀ ju, òun sì ló ni eléro tó pọ̀ jù.
Níbí ni Ìmó̩wùnmí ti fi ìfẹ́ rè̩ han láti mò̩ ohun tí ń bẹ nínú atakókó tó wà láàárin gbùngbùn wínnípin, bàbá rè̩ sì wípé ó ti yá láti rìnrìn àjò lo̩ sí àárin gbùngbùn náà. S̩ùgbó̩n bàbáa rè̩ so̩ fún un pé, kí àwo̩n tóó lè rí ohun tó wà láàárín gbùngbùn náà dáradára, àwo̩n yóò ní láti mú kí wínnípin náà fẹ̀ tó odidi orílé-èdè kan. Bàbáa rè̩ sí wì fún ún kó fo̩n fèrè o̩wó̩ọ rè̩ lé̩è̩kan sí i, àtipé bí fèrè náà bá fo̩n lẹ́ẹ̀kan, iye ìlọ́po ló̩nà e̩gbe̩gbè̩rún ni wínnípin náà yóò fi fẹ̀ si.
Ìmó̩wùnmí fo̩n fèrè o̩wó̩ọ rè̩ tan ni gbogbo agbègbè tí wó̩n wà bè̩rè̩ síí tóbi kọjá kèrémí. Opẹ́lọpé pé wó̩n wa nínú o̩kò̩ọ bàtà tí wó̩n ń pè ní ò̩ge̩re̩re̩. Òun ni kò jẹ́ kí gbogbo àwo̩n òkò eléro tí ń kọjá lára wó̩n s̩e wó̩n lọ́ṣẹ́. Bàbá náà so̩ fún o̩mo̩ rè̩ pé tí kìí bá s̩e ti o̩kò̩ ò̩ge̩re̩re̩ tí àwo̩n wò̩ yìí ni, yóò gba àwo̩n tó ogúnjó̩ láti rìn láti gbàgede wínnípin dé àárin gbùngbùn rè̩ nítorí bí wínnípin náà ti fè̩ tó báyìí. Ó ní s̩ùgbó̩n o̩kò̩ ò̩ge̩re̩re̩ náà yóò gbé àwo̩n ní kíákíá dé àárin gbùngbùn.
Wọ́n gbéra, wó̩n de obiri-iyibiiri tó kángun sí gbàgede atàkókó-àárín wínnípin náà, wó̩n kò lè kọjá nítorí ohun kan ń sáré lójú òpó náà. Bàbá náà tún ki ògèdè tó pa lẹ́ẹ̀kan mọ́lẹ̀, lẹ́yìn èyí sì ni àwọn ohun tí ń sáré náà dúró. Níbí ni wó̩n ti rí i pé eléro tó múra wo̩n ní méjì-méjì ló ń sáré àsáyípo náà. Bí wó̩n ti kọjá obiri-iyibiiri náà ni àwo̩n eléro ọ̀hún tún bè̩rè̩ sí sáré, ènìyàn kò sì lè gba ibè̩ ko̩já mó̩ láìs̩̩e pé àwo̩n eléro náà dúró. Báyìí ni wó̩n s̩e títí tí wó̩n fi lo̩ dé àárin gbùngbùn wínnípin náà, níbẹ̀ ni wó̩n sì ti rí atakókó àárin náà pé àwo̩n è̩yà ohun méjì kan ló dìpò̩ mó̩ ara wo̩n. Ìkín-ní ni e̩lé̩rò̩ (proton), èkejì sì ni alè̩rò̩ (neutron) gé̩gé̩ bí bàbá rè̩ ti wí fún un. Bàbá rè̩ s̩àlàyé ní kíkún pé:
“Àárin gbùngbùn wínnípin la dé yìí o̩mo̩ mi. Bí o bá wò ó dáadáa, wàá rí i pé àwo̩n ohun kan dìpò̩ níbi tó jẹ́ ẹ̀yà méjì, èkínní tíí s̩e e̩lé̩rò̩ ni agbára rè̩ wà ní è̩rò̩, èyí jé̩ ìdà kejì agbára tó wà nínú eléro tá ti rí síwájú. Èkejì tíí s̩e alè̩rò̩ yìí ló wà nínú gbogbo wínnípin tí e̩lé̩rò̩ rè̩ ju ẹyọkan lo̩ nítorí e̩lé̩rò̩ méjì kò lè lè̩pò̩ mó̩ ara wo̩n. Nítorí naa, wó̩n nílò alè̩rò̩ tí agbára rè̩ wà ní ìwò̩ntun-wò̩nsì èro àti è̩rò̩ (neutral). Eléyìí ni kò níí jẹ́ kí agbára è̩rò̩ tó wà láàárin wínnípin náà pọ̀ ju láti lè dúró s̩ins̩in.”
Ìmó̩wùnmí fèsì pé, “Ìtumò̩ ohun tí è̩ ń wí fún mi látàárò̩ ni wípé, eléro fó̩nká gbàgede, e̩lé̩rò̩ dì pọ̀ sáàárín, alè̩rò̩ ló le̩ e̩lé̩rò̩ àárín pò̩.” Bàbá rè̩ní “O káre láé.” Bàbá náà sì ń bá ò̩rò̩ rè̩ lo̩ wípé:
“Jé̩ kí n wá so̩ fún o̩ nípa àwo̩n as̩ò̩tò̩pé (isotopes). Èròjáyé àbámáyé ni wó̩n lóòótó̩, s̩ùgbó̩n wó̩n s̩e ò̩tò̩ nítorí pé atakókó-àárín wo̩n ní alè̩rò̩ tó pò̩ jù e̩lé̩rò̩ lo̩. Às̩e̩ àbámáyé ni pé iye kan náà ni e̩lé̩rò̩ àti alè̩rò̩ gbó̩dò̩ jé̩ nínú atakókó àárín kí àpapọ gbogbo agbára atakókó àárín lè wà ní è̩rò̩. Bí alè̩rò̩ bá ti wà pò̩ ju e̩lé̩rò̩ lo̩ nínú atakókó àárín, wínnípin náà di as̩ò̩tò̩pé nìye̩n. Ìyẹn ni pé, eléro rẹ̀ pé bí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe ara ọ̀tọ̀ nítorí alẹ̀rọ̀ rẹ̀ lé níye.”
Gbogbo bí ẹ̀kọ́ yìí ti ń lọ ni inú Ìmó̩wùnmí ń dùn nítorí ó yé e yéké-yéké. Ó sì ń fẹ́ láti mọ̀ síi. Bàbáa rẹ̀ ṣàkíyèsí èyí, inú òun pàápàá sì ń dùn. Bàbá náà sọ fún ọmọ rẹ̀ kó fọn fèrè náà sọ́kan lára àwọn e̩lé̩rò̩ tó dì mọ́ra wọn nínú atakókó àárín. Ìmó̩wùnmí sì ṣe bẹ́ẹ̀, e̩lé̩rò̩ náà bẹ̀rẹ̀ síí wú, ohun mẹ́ta kan sì ń fi agbára jà nínú e̩lé̩rò̩ náà bíi pé wọ́n fẹ́ẹ́ jáde síta nínú ìgbèkùn. Àyàa Ìmó̩wùnmí já!