Nípa wa

Ẹni tí a jẹ́

Ikọ̀ ọ̀dọ́ Yorùbá ni wá, a sì jẹ́ akẹ́kọ̌gboyè nínú Ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè (Linguisics), ìmọ̀ ìjìnlẹ̀-èrò (Philosophy), Físíìsì (Physics), Kẹ́mísírì (Chemistry), àti Ìmọ̀ ẹ̀dá oníyè tíntìntín (Microbiology).

Ohun tí Science in Yorùbá ń gbìnyàjú láti ṣe

Nǹkàn mẹ́ta gbòógì ni à ń gbìnyànjú láti ṣe, a sì mọ̀ pé ṣíṣe àwọn nǹkàn wọ̀nyí yóò gba fífi gbogbo ọjọ́ ayé ẹni ṣeé. Sùgbọ́n ìròyìn ayọ̀ ni pé a ti ṣetán láti fi gbogbo agbára wa ṣeé. Àwọn àfojúsùn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ọ̀hún nì yí:

Àfojúsùn kíní: Túmọ̀ gbogbo àwọn ìwé kíkà tí ó jẹ́ ti sáyẹ́ǹsì ní àwọn ilé ìwé girama ní Nigeria sí èdè Yorùbá. Àwọn ìlànà tí à ń lò ni ìwọ̀nyí:

 i. wá ọ̀rọ̀ Yorùbá fún àwọn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì; tí èyí kò bá ṣeéṣe, kí á

ii. wa ọ̀rọ̀ Yorùbá tí a lè mú ìtumọ̀ rẹ̀ gbòòrò tí yóò fi lè ní itúmọ̀ tí ó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì làí mú wàhálà dání; tí èyí kò bá ṣeéṣe, kí á

iii. yá ọ̀rọ̀ lò láti inú èdè Gẹ̀ẹ́sì nípa lílo àwọn ìlànà ìjìnlẹ̀ bii ìyátumọ̀lò (calquing), ìyọ́rọ̀lò (loanword), abbl.

iv. lo ìlànà yí bí a ṣe tòó sílẹ̀ gẹ́lẹ́.

Àfojúsùn kejì. Fi ìtumọ̀ yí kọ́ àwọn akẹ́kọ̌ ní ilé ìwé pẹ̀lú àfojúsùn láti mú kí ìmọ̀ wọn tún lé kún síi nípa lílo ìlànà isalẹ:

i. lo ìlànà ẹ̀kọ́ jíje-àǹfààní ọ̀pọ̀ èdè  (Translanguaging pedagogy) tí ó ṣe àmúlò Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì

ii. ṣe àlàyé àwọn èrò ìjìnlẹ̀ nípa lílo Yorùbá, kí á sì fi àwọn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ sílẹ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, nígbà tí ó ṣe pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn akẹ́kọ̌ yí yóò fi ṣe ìdánwò wọn.

iii. má fún àwọn akẹ́kọ̌ yí ní àkọsílẹ̀ ní èdè Yorùbá láti má jẹ́ kí nǹkàn dàrú mọ́ wọn lójú

iv. àwọn èrò ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ti sàlàyé ní Gẹ̀ẹ́sì nìkan ni kí á tún àlàyé rẹ̀ ṣe ní èdè Yorùbá.

v. ohun tí ó ṣe pàtàkì jù ni pé kí àwọn akẹ́kọ̌ gbọ́ àgbọ́yé itúmọ̀ àwọn èrò ìjìnlẹ̀ ni èdè Yorùbá, kí wọn ó sì lè ronú nípa wọn lọ́nà tí wọn yóò fi lè fí gbé nǹkan ṣe

vi. Fún idi eyi, àlàyé tí a ṣe ní èdè Yorùbá gbọdọ̀ jẹ́ àfikún sí èyí tí a ṣe ní èdè Gẹ̀ẹ́sì

vii. Ṣe àfihàn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa lílo àwọn ohun ìkẹ́kọ̀ọ́, lọ́nà àti le mú àwọn akẹ́kọ̌ ronú jinlẹ̀ lórí àwọn èrò ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì

viii. kọ́ àwọn olùkọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè mú ìlànà yí wọ yàrá ìkàwé wọn lọ́nà àti lè mú àgbọ́yé àwọn akẹ́kọ̌ wọn gbòòrò síi.

Àfojúsùn kẹta. Sẹ akitiyan láti mú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì wọ inú àṣà Yorùbá, kí àwọn ọmọ Yorùbá, tí wọ́n kàwé òyìnbó àti àwọn tí wọn kò ka irú ìwé yìí, le ní àǹfààní sí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì, nípa ṣiṣe àwọn ohun wọnyii:

i. sẹ àwọn ohun wíwò àti gbígbọ́ bíi fídíò, àwòrán, abbl, kí á sì fi wọ́n sí orí ayélujára.

ii. Béèrè ìmọ̀ran lọ́wọ́ àwọn ènìyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lọ́nà àti le mú àwọn ìjíròrò kan wáyé tí wọ́n

le mú kí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí níí fi Yorùbá sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì, tí èyí yóò sì mú kí ìtumọ̀ tí à ń ṣe mọ́yán lórí síi.

iii. Ṣe àkóso àká (archive) ayélujára Yorùbá tí ó wà fún ìmọ̀ gbogboogbò lórí èyíkéyǐ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì (STEM).

Iṣẹ́ àkànṣè tó ń lọ lọ́wọ́

1. Àká (archive) ayélujára Yorùbá tí ó wà fún ìmọ̀ gbogboogbò lórí èyíkéyǐ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì (STEM): Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, à ń ṣe àtẹ̀jáde orísírísǐ àwọn àròkọ alàlàyé (explainer article) lórí gbogbo ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì. Ẹ yẹ ààyè ayélujára yí wò fún àwọn àròkọ yí.

2. Ìpolongo lórí àwọn ìkànnì ìbánidọ́rẹ̌ ayélujára (social media):

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, à ń ṣe àwọn àwòrán, àti àwọn fídíò, èyí tí à ń tẹ̀ jáde lórí Facebook, YouTube, Instagram àti Twitter.

Iṣẹ́ àkànṣè tí a ti ṣe

1. Kíkọ́ àwọn olùkọ́ ìlú ìbàdàn nípa bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ohun èèlò ẹ̀kọ́ (tí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Kémísírì ní Fásitì Tulane pèsè fún wọn) nínú yàrá ìkàwé wọn (Osù kejì, 2020).

2.Títúmọ̀ ìwé Basic Science 1 (láti ọwọ́ Learn Africa PLC) tí ó wà fún JSS1 sí èdè Yorùbá, èyí tí Àjọ Mellon ní  Fásitì Tulane ṣe agbátẹrù rẹ̀ (2017-2019).

Ikọ̀

Olùdásilẹ̀/ Olóòtú
Taofeeq Adebayo
Assistant Professor of Linguistics, California State University, San Bernardino

Àwọn olùbásisẹpọ̀
Raji Lateef, Lecturer, Department of General Studies (Yoruba Unit), Lagos State University of Science and Technology
Bode Ọjẹ, Broadcasting Corporation of Oyo State (BCOS), Ibadan
Eriifeoluwa Mofoluwawo, MSc, Chemistry, University of Ibadan
Jegede Samuel, M.Sc., Microbiology, University of Ibadan
Awelewa Samuel Ayodele, Ph.D. student in Physics, Kent State University
Olugbenga Olabiyi, Ph.D. student in Physics, University of Utah
Lateef Adeleke
Alabi Sheriff
Afuye Olubayode
Tawkalitu Badmus
Babatunde Popoola
Adéníran AbdBasit Adéyẹmí

Pín-in ká
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •