Mọnamọna alaisunra (Static electricity)

Here is a quick science trick you can do right now (Eyi ni idan imọ ijinlẹ kan ti ẹ le se papa niisin niisin)

Here is a quick science trick you can do right now (Eyi ni idan imọ ijinlẹ kan ti ẹ le se papa niisin niisin) #staticelectricity #yoruba #science #scienceinyoruba

Posted by Science in Yoruba on Sunday, November 12, 2023

Mọnamọna ninu ọpọlọ (Electricity in the brain)

We are all electricity generators (Ẹrọ amunawa ni gbogbo wa)

We are all electricity generators (Ẹrọ amunawa ni gbogbo wa)

Posted by Science in Yoruba on Tuesday, August 8, 2023

Iṣẹ́ (Work) 2| Olugbenga Ọlabiyi

Lámèétọ́: Taofeeq Adebayo
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ní báyìí, kí ni à ń pè ní iṣẹ́ nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ tí Físíìsì? Iṣẹ́ jẹ́ àmúlò ipá (force) láti mú ìṣípòpadà (motion) bá nǹkan.  Èyí túmọ̀ sí pé ìsọdipúpọ̀ ìwọ̀n ipá (amount of force) àti ìwọ̀n-ìjìnà (distance) ní ọ̀gangan-àyè (direction) tí ipá ń lọ. Àwọn apẹẹrẹ isẹ́ máa ń farahàn nínú àwọn ìṣe (act) wọ̀nyí:

  1. Ẹni tó ń ti ọmọ-lanke (trolley) láti ibìkan sí ibòmíràn nínú ilé-ìtajà ńlá.
  2. Tí a bá gbé ẹrù láti ilẹ̀ sí orí tábìlì.
  3. Tí a bá gbé ẹrù sórí láti ibìkan dé ibòmíràn.

Àwọn àpẹẹrẹ tí a se yìí ń se àkọ̀júwe iṣẹ́ (work) ní ìbámu pẹ́lù bí àwọn onímọ̀ Físíìsì ṣe gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀.

Níbàyí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìṣẹ (acts) tí a ò le kà sí iṣẹ́, tàbí ká ṣọ wípé àwọn àpẹẹrẹ tí kò sàpèjúwe iṣẹ́. Àwọn nìwọ̀nyí:

  1. Ẹni to gbe apẹrẹ eṣo sori, to wa duro soju kan fun igba pipẹ tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí .

Fún àlàyé yéké, àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ fi yéwa wípé kò sí iṣẹ́ nínú kí a dúró sójú kan pẹ̀lú ẹrù lórí fún ìgbá pípẹ́ tàbí ìgbà díẹ̀.

Níparí, mo ní ìgbàgbọ́ wípé òye ohun tí à ń pè ní iṣẹ́ ti yé wa. Mo sì  nígbàgbọ́ pé a ti rí ìyatọ̀ tó wà láàrin ohun tí gbogbo wa mọ̀ sí iṣẹ́ àti ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ń pè ní iṣẹ́. Ótún di ọjọ́ mì ọjọ́ ire.

Ẹ ṣeé pùpọ́!

Iṣẹ́ (Work) 1| Olugbenga Ọlabiyi

Lámèétọ́: Taofeeq Adebayo
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ǹjẹ́ kíni àwọn ònimọ̀-ìjìnlẹ̀ ń pè ní iṣẹ́ (work)? Àwọn ìṣe (acts) àwa ẹ̀dá wo ni ó  ń ṣe àpẹẹrẹ iṣẹ́? Bákan náà, àwọn ìṣe wo ni a ò leè kà sí iṣẹ́? A ó màá fi ìdáhùn sí àwọn ìbéèré wọ̀nyí nínú ẹ̀kọ́ yìí. Nítorínà, ẹ fì ìkàlẹ̀ síi; ẹ mú kálámù àti ìwé yín láti se àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ bá rí gbámú.

Kí a tó wọ inú tìfuntẹ̀dọ̀ ohun tí àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ń pè ní iṣẹ́ (nínú apá 2), ẹ jẹ́ kí á kọ́kọ́ ṣọ̀rọ̀ lérèfé nípa ǹkan tí gbogbo wa mọ̀ sí iṣẹ́ (work). Iṣẹ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ kan gbòógì tí a máa ń lò ní gbogbo ìgbà. Orísirísi ọ̀nà ni ẹ̀dá ènìyàn ń gbà lo ọ̀rọ̀ tí à ń pè ní “iṣẹ̀”. Fún àpẹẹrẹ:

  1. Mò ń lọ síbi iṣẹ̀
  2. Tádé ń sisẹ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ girama ní agbègbè mi
  3. Ọlá ṣe àlàyé bí ẹ̀rọ amúsẹ́yá (machine) rẹ̀ se ń se isẹ́
  4. Ọlá ṣe iṣẹ́ ọpọlọ

Pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí, a ó ripé ọ̀rọ̀ tí à ń pè ní iṣẹ́ (work) máa ń farahàn nínú ìse wa, pàápàá jùlọ a máa ń se àmúlò iṣẹ́ nípa agbára káká (physical strength) tàbí ọgbọ́n àtinúdá (mental effort).

Níbìyí la o fi àgbàdá ètò rọ̀ sí lòní. A ó máa tẹ̀sìwájú nínú apá 2.

Ẹ seun púpọ̀!