Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Biology)| Raji Lateef
Lámèétọ́: Taofeeq Adebayọ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ
Látìgbà láéláé ni àwọn ènìyàn ti máa ń fẹ láti mọ̀ síi nípa àwọn nǹkan tó wà ní àyíkáa wọn, pàápàá àwọn ohun abẹ̀mí. Èyí ló fa ẹ̀kọ́ nípa àwọn ẹ̀dá-oníyè – Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Biology).
Oríkì (Definition) àti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Branches of Biology)
Ara ọ̀rọ̀ Gíríkì méjì ni wọ́n ti ṣẹ̀dá Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè, tí ń ṣe ‘Biology.’ Àkọ́kọ́ ni bios tó túmọ̀ sí ẹ̀mí nígbà tí èkejì tó jẹ́ logos túmọ̀ sí ẹ̀kọ́. Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀mí (life). A lè rí Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀kọ́ nípà àwọn ewé (plants) àti àwọn ẹran (animals).
Ẹ̀ka méjì gbòógì ni Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè ní. Èyí kò sọ pé kò sí àwọn ẹ̀ka mííràn:
- Ẹ̀kọ́ Ẹranko (Zoology): Èyí ni ẹ̀kọ́ nípa gbogbo àwọn ìran ẹran (animals).
- Ẹkọ́ Ewé (Botany) ni ẹ̀kọ́ nípa gbogbo ìran ewé àti igi.
Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ka méjì òkè yìí, àwọn ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè mííràn ló wà ní ìsàlẹ̀ yìí:
- Ẹkọ́lọ́jì (Ecology) ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun abẹ̀mí (living things) – yálà ewé àbí ẹran – àti àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àyíká.
- Mọfọ́lọ́jì (Morphology) ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn àbùdá-òde (external features) àwọn ewé àti ẹran.
- Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́-ìrísí-inú (Anatomy): Ẹ̀yí ni ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè mííràn tó ń ṣàlàyé àwọn ìrísí inú (internal structures) àwọn ewé àti ẹran.
- Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́ran (Genetics): Èyí ni ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì tó jẹ́ ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè tó ń ṣàlàyé nípa àwọn àbùdá àjogúnbá (heredity) àti ìyàtọ̀/àìjọra (variations) àwọn àbùdá bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ẹ̀dá oníyè (living things).
- Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́-Ìṣesí Ẹ̀dá-oníyè (Physiology): Èyí ló ń ṣàlàyé nípa àwọn ìṣesí, ìwúlò tàbí àǹfàní (functions) àwọn ewé àti ẹran (living things).
Orísun: Essential Biology for Senior Secondary School (Ninth Edition)
Orísun àwòrán: https://english-online.org.ua/materials/13468