Atakóró wọnú wínní-wínní 4| Fààbú sáyẹ́ǹsì láti ọwọ́ Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀

Lámèétọ́: Raji Lateef
Olóòtú: Taofeeq Adebayo

Atakóró wọnú wínní-wínní 1
Atakóró wọnú wínní-wínní 2
Atakóró wọnú wínní-wínn 3

Bí e̩lé̩rò̩ ti wú bàǹtù tán, Ìmó̩wùnmí rí i pé ohun alágbára mẹ́ta kan wà nínú rẹ̀ lọ́hùn-ún tó ń yí bírípe-bírípepe lu ipá-okùn ńlá kan nínú rè̩. Bàbáa rè̩ bẹ̀rẹ̀ àlàyé wípé, “níbi tí a dé yìí lagbára ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ gbé e dé sàn-án-sàn-án nípa ìwádìí ohun tó kéré jọjọ, àforírò tàbí tí ẹ̀rí díẹ̀ wà fun ni gbogbo èyí tó kù nítorí è̩rí s̩ò̩wó̩n fún wo̩n. Àwọn ohun mẹ́ta wọ̀nyí là bá máa pè ní kín-ún agbára nítorí níbi, kò sí ọ̀rọ̀ pé ohun kan lówúra mọ́, agbára ni owúra, owúra sì ni agbára. Okun kín-ún yìí náà wà nínú alè̩rò̩ pè̩lú. Ìwásókè-wásílẹ̀ lagbára inú kín-ún kọ̀ọ̀kan fi yàtọ̀ síra.”

Wọ́n sún mọ́ etí obiri eléro láti wo kín-ún mẹ́tẹ̀èta inú rẹ̀ dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò wo inú rẹ̀. Bàbá Ìmó̩wùnmí ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ wípé: “Ṣé o ránt́i Egúngún Aroyeyo?” Ìmó̩wùnmí ni bẹ́ẹ̀ ni. Bàbá ní, “Nígbàkígbà tí egúngún náà bá ń jó, ó lè lọ́ biiri bí òkòtó tó ń jó ràn-ìn-ràn-ìn, ó sì lè tàkìtì.” Ìmó̩wùnmí tún ní béè ni. “Kín-ún tóò ń wò yí lè ṣe nǹkan méjì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo: ó lè jó ràn-ìn-ràn-ìn kó tún tàkìtì pò̩ lé̩è̩kan náà. Méjéèjì yìí ló ń sọ bí kín-ún yóò ṣe gbagbára sí.

Bí kín-ún kan nínú mẹ́ta bá wá dorí kodò (D), táwọn méjì tó kù sì síjú-sókè (U), ó níye agbára tó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ rẹ̀ ti wà nínú àwòrán tí n óó yà fún ọ sí ìsàlẹ̀ yìí.” Bàbá gba ìwé lọ́wọ́ Ìmó̩wùnmí ó ya àwòrán ìjóràn-ìn àti ìgbágbára-sí-kín-ún. Ìmó̩wùnmí ń wò bi agbára kín-ún náà ti pò tó. Ó fẹ́é fi agbára jáde pẹ̀lú ìbínú ńlá nínú e̩lé̩rò̩ ṣùgbọ́n ewé-agbéjẹ́ẹ́ tí bàbá rẹ̀ ti mú u mọ́lẹ̀ kò jẹ́ kó lè ṣe ohun kan. Ọgbọ́n kan wá si Ìmó̩wùnmí lórí. Bàbáa rẹ̀ ń fi ojú ẹ̀gbẹ́ kan wò ó láìmọ̀, ó sì ń rẹ̀rín músẹ́.

Lójijì ni Ìmó̩wùnmí fọn fèrè o̩wó̩ọ rè̩. Ó fẹ́ kí kín-ún wu, kí òun lè wo ohun tó ḿ bẹ nínú rè̩, s̩ùgbó̩n ìjayà tó rí lójú bàbáa rè̩ bà á lẹ́rù púpò̩. Bàbáa rè̩ wípé “kí ló dé tó s̩e èyí láìso̩ fún un? Págà! S̩àǹgbàfó̩! Mo dáràn, àfi ká tètè darí relé.”

Wọn kò kúkú bó̩ sílẹ̀ nínú o̩kò̩ ò̩ge̩re̩re̩ tí wó̩n wà láti ìgbà yìí wá. Wó̩n dari o̩kò̩ náà padà síbi tí wó̩n ti ń bọ̀, wó̩n sì bè̩rè̩ sí sá lo̩ sí ìta-gbangba pada pè̩lú eré burúkú. Gbogbo bí wó̩n ti ń lo̩ ni ohun gbogbo ń dà wó lulẹ̀ léyìn-in wọn. Àrá ń sán, òǹfà sì ń fà wó̩n padà sẹ́yìn. Rògbòdìyàn wà níbi gbogbo nínú wínnípin náà. Gbogbo àwo̩n eléro tí wó̩n ń ko̩já rè̩ lákò̩ó̩kó̩ ti di òkò eléruku dúdú. Ìrínìmò̩ bè̩rè̩ síí darí o̩kò̩ náà sí-ì-hín-sọ́-ọ̀-hún kó má baà forí gbárí pè̩lú àwo̩n òkò náà. Wàhálà dé bá o̩mo̩ àti baba. Bé̩è̩ ni ohun gbogbo ń kéré síi, tí òǹfà alágbára kan sì ń fà wó̩n padà sáàárin gbùngbùn wínnípin náà. Tipátipá ni wó̩n fi rí o̩kò̩ náà wà jáde láti inú wínnípin bọ́ sínú òkùnkùn lóde. Wó̩n rí àwo̩n wínnípin tó kù bí wó̩n ti lo̩ be̩e̩re̩, s̩ùgbó̩n ohun abàmì mííràn tún s̩e̩lè̩.

Bí to̩mo̩tibàbá s̩e ń dúpẹ́ pé àwó̩n ja àjàbọ́ó nínú kóro wínnípin náà, bé̩è̩ ni wó̩n rí gbogbo wínnípin bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ síí hùwà bákan náà.  Rògbòdìyàn ti wà nínú àwọn náà pẹ̀lú bó tilè jé wípé bàbá àto̩mo̩ kò wọ inú gbogbo wọn lọ. “Kí ló lè fa èyí?”, O̩mo̩ béèrè lọ́wọ́ bàbáa rẹ̀, ṣùgbọ́n bàbá ní òun kò mọ̀ ohun tó lè fà á. Okùn ńlá kan bẹ̀rẹ̀ síí fà wọ́n bí ẹní n fa doro-omi láti inú kàǹga.

Wó̩n jáde síta, wó̩n sì lo̩ pàdé ìyá o̩mo̩ náà níbi tó ti ń dúró dè wó̩n tè̩rín-tè̩rín. O̩mo̩ náà bè̩rè̩ síí so̩ ohun tí ojú rẹ̀ rí àti ohun tó s̩e̩lè̩ fún ìyá rè̩, pàápàá jùlo̩, ibití rògbòdìyàn ti dé nígbà tí òun fo̩n fèrè pé kí e̩lé̩rò̩ wú kí òun baà lè rí ohun tí ḿ be̩ nínú rè̩. Ìyá ní “s̩é lóòótó̩.” Ìyá àti bàbá wo ojú ara wo̩n, wó̩n sì fi ojú sò̩rò̩ síra pè̩lú è̩rín wípé mò̩-sínú-mò̩-síkùn. Wó̩n jáde nínú Ìkò̩lé-Òfeefèé, àko̩mò̩nà kán wà tí o̩mo̩ náà kò s̩e àkíyèsí nígbà tí wó̩n kó̩kó̩ wo̩lé.Àko̩mò̩nà náà kà báyìí wípé:

“NÍBÍ NI A TI Ń FI ÀWÒRÁN ÒFEEFÈÉ S̩ÀLÀYÉ ÌMÒ̩ ÌJÌNLÈ̩ NÍ KÍKÚN.”

Gbogbo bi wó̩n ti padà sílé lọ́jọ́ náà, inú ìrònú ni Ìmó̩wùnmí wà. Ó ń ronú ohun tó sẹlẹ̀ nígbà tí àwo̩n wínnípin bẹ̀rẹ̀ síí hùwà bákan náà bíi pé ọ̀kan ṣoṣo ni wọ́n. Ò̩ràn náà kan Ìmó̩wùnmí lóminú gan-an ni. 

Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, o̩mo̩débìrin náà so̩ fún bàbá rè̩ pé ó dàbí e̩ni pé òun ti mo̩ ohun tí ń s̩e̩lè̩. Ó ní lẹ́yìn tóun ti tún ka ìwé kún ìwé, tí òun sì ní ìmò̩ síi nípa ìmò̩-ìjìnlè̩, òun ní àrígbèrò (4) kan pé bóyá ni kìí s̩e pé wínnípin jé̩ bíi odidi ò̩salalu kan yàtò̩ sí ìdo-ayíbiiri bí wó̩n ti gbèrò té̩lè̩ rí. Ìye̩n ni pé odidi ò̩salalu (5) kékeré kan ni wínnípin, ohun tó bá sì ń s̩e̩lè̩ sí ọkan ń s̩e̩lè̩ sí èkejì lásìkò kan náà.

Bàbá rè̩ ya e̩nu nígbà tó gbó̩ èrò Ìmó̩wùnmí, ó wípé, káre láé.

Àyànkọ (note)
1. kín-ún – quarks
2. Owúra – mass. matter. Lówúra – has mass
3. Agbára ni owúra, owúra sì ni agbára – mass equals energy and energy equals mass.
4. Àrígbèrò – hypothesis
5. ò̩salalu – universe (uni=one, versus=turned, thus one version of different things that turned into one big whole), rendered in Yoruba here, ò̩salalu means one thing that spreads all out.

Pín-in ká
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *