Science in Yorùbá ń gbìnyànjú láti ṣe ìdásílẹ̀ àká ayélujára (online archive) níbi tí àwọn ọmọ Yorùbá yóò tí ní àǹfààní sí ìmọ̀ gbogboogbò (general knowledge) lórí èyíkéyǐ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì ní èdè abínibí wọn. Ǹjẹ́ ẹ jẹ ọmọ Yorùbá tí o n kọ ẹ̀kọ́ tabi ṣiṣẹ lórí èyíkéyǐ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì? Ǹjẹ́ yóò wù yín kí àwọn ọmọ Yorùbá, tí wọ́n kàwé àti àwọn tí wọn ko kàwé, ó ní àǹfààní si ìmọ̀ gbogboogbò nípa ẹ̀ka ẹ̀kọ́ yin? Ǹjẹ́ yóò wù yín kí àwọn ọmọ Yorùbá ó kà (kí wọn ó sì wo fídíò) nípa ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí ẹ dì mú? Ẹ fi àròkọ alálàyé (explainer article) sọwọ́ sí wa lórí scienceinyoruba@gmail.com nípa lílo ìlànà tí a tẹ̀ sí ìsàlẹ̀, a ó sì tẹ́ẹ̀ jáde lórí scienceinyoruba.org lẹ́yìn tí a bá tí gbéè yẹ̀wò dáadáa.
A. Èdè
Ọ̀nà méjì ni ẹ lè gbà:
1. Yorùbá
Èdè tí a yàn láàyò jù ní èdè Yorùbá. Bí ẹ ó bá fi Yorùbá kọ àròkọ alálàyé yín, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn ohun wọ̀nyí:
i. Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ (terminologies)
Ọ̀nà méjì ni ẹ lè gbà lórí lílo ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀
a. Lo ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ bí wọ́n ṣe wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. A ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú yín láti wá ọ̀rọ̀ Yorùbá fún wọn, sùgbọ́n ẹ ríi dájú pé ẹ fún wọn ní ìnípọn (boldface). Àpẹẹrẹ:
Kí ni àwọn onìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ń pè ní pure element?
b. Pèsè ọ̀rọ̀ Yorùbá fún àwọn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Bí ẹ ó bá ṣe èyí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sí inú àkámọ́ (parenthesis) lẹ́yin ọ̀rọ̀ Yorùbá tí ẹ pèsè, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀. A ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú yín láti wá ọ̀rọ̀ Yorùbá míràn fún wọn tí èyí tí ẹ pèsè ko ba kun oju osunwọn to. Àpẹẹrẹ:
Kí ni àwọn onìmọ̀ ìjìnlẹ̀ n pe ni èròjà alailabula (pure element)?
ii. Àmì ohùn (Tones)
A mọ rírì àròkọ (article) tí ó ní àmì ohùn ní ààyè tí ó yẹ kí ó wà, sùgbọ́n tí ẹ kò bá lè fi àmì sí orí àwọn ọ̀rọ̀ nínú àròkọ yín, ikọ̀ wa yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú yín láti fi àmì ohùn síi. Orúkọ ẹni tí ó fi àmì ohùn síi yóò wà ní ìsàlẹ̀ àròkọ yín.
2. Gẹ̀ẹ́sì
Ẹ tún lè fi àròkọ alálàyé yín sọwọ́ sí wa ní èdè Gẹ̀ẹ́sì; Ikọ̀ wa yóò túmọ̀ rẹ̀ sí Yorùbá. Bí èyí bá sẹlẹ̀, Orúkọ ẹni tí o túmọ̀ rẹ̀ sí Yorùbá yóò wà ní ìsàlẹ̀ àròkọ yín.
B. Gigun àròkọ alálàyé (Explainer article length)
1. Àròkọ alálàyé kò gbọdọ̀ gún ju ojú ewé kan lọ, tí ó ní àlàfo-ìlà méjì (double space)
2. tí àròkọ yín bá gùn ju ojú ewé kan lọ, a lè pín-in sí Apá kíní, Apá kejì, abbl.
3. Ẹ sì lè bẹ̀rẹ̀ àròkọ alálàyé tí ó ní Apá kí ni, Apá kejì, abbl
D. Àwọn tí à ń ṣe àròkọ alálàyé fún
Àwọn tí à ń ṣe àròkọ alálàyé fún jẹ́ ìsọ̀rí àwọn èèyàn wọ̀nyí: àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n ka èyíkéyǐ nínú ẹ̀ka ìwé òyìnbó, àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n ka irúfẹ́ ìwé míràn tí kìí ṣe ti òyìnbó (àpẹẹrẹ: kéwú), àwọn ọmọ Yorùbá tí kò lọ ilé ìwé (tàbí ilé kéwú) kankan. Èyí túmọ̀ sí pé àgbékalẹ̀ yín gbọdọ̀ rọrùn fún gbogbo ọmọ Yorùbá.
E. Fídíò
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé a lè má lè ṣe fídíò fún gbogbo àròkọ ní kété tí a bá tẹ̀ wọ́n jáde, àfojúsùn wa ni láti ṣe fídíò fún gbogbo àròkọ tí a bá tẹ̀ jáde. Bí a bá ṣe fídíò fún àròkọ tí ẹ fi sọwọ́ sí wa, a ó fi orúkọ yín sí inú fídíò náà gẹ́gẹ́ bíi onígègé àrà.
Ẹ. Ojúlówó àròkọ
Gbogbo àròkọ tí ẹ bá fi sọwọ́ sí Science in Yorùbá gbọdọ jẹ́ ti yín. Ojú burúkú ni a fi wo fífi iṣẹ́ ẹlòmíràn pe tẹni (plagiarism).
F. Àdéhùn
Fífi àròkọ alálàyé ráńsẹ́ sí Science in Yorùbá túmọ̀ sí
1. pé ojúlówó iṣẹ́ yín ni ẹ fi ráńṣé sí wa;
2. pé a ó tẹ àròkọ yín jáde lórí scienceinyorub.org pẹ̀lú orúkọ yín; àti
3. pé ó ṣeé ṣe kí a ṣe fídíò fún àròkọ yín.
G. Àwọn ohun tí ẹ lè ṣe àmúlò