Èròjà aláìlábùla (pure elements)

Ki ni awọn onimọ ijinlẹ n pe ni èròjà alailabula (pure element)? Bi a ba wo ayika, orisirisi nnkan  ni a o rii ti o yi wa ka. Bi a ṣe n ri awọn nnkan didi  ni a o maa rii awọn nkan olomi. Bi a ṣe n ri awọn nkan to jẹ gaasi ni a o màa ri awọn ohun miran ti wọn  o fara jọ gaasi rara. Bi a ba waa ro arojinlẹ, o ye ki a le beere awọn ibeere kan Kilo de ti igi fi jẹ ohun lile ti omi si jẹ ohun to n san? Kilo de ti awọn ohun elepo  fi maa n fa jọọ ti eyi ko si ri bẹẹ fun omi? Kilo de ti awọn igi fi le dagba sii ti okuta ko si le tobi ju bi o ṣe wa lọ? Ki a to le dahun gbogbo awọn ibeere yi, a ni lati mọ itumọ ohun ti wọn n pe ni eroja alailabula.

Eroja alailabula ni eroja kẹmika ti o jẹ pe ohun nikan ni o pilẹ ohun kan. Ẹ jẹ ki a fi góòlù ṣe apejuwe. Ti a ba fọ góòlù si wẹwẹ debi kẹmika to kere ju ninu góòlù, kẹmika góòlù naa ni a o ba nibẹ. Eyi tumọ si pe góòlù jẹ eroja alailabula. Eyi ko ri bẹẹ fun omi. Ti a ba fọ omi si wẹwẹ debi awọn kẹmika to kere ju ti o jẹ pe awọn ni wọn pilẹ omi, eroja alailabula meji ọtọọtọ Ọksijin (oxygen) ati Haidirojiini (hydrogen)  ni a o ba nibẹ. Eyi tumọ si pe omi kii ṣe eroja alailabula. Akanpọ eroja (compound) nii ṣe.

Orisirisi eroja alailabula ni awọn onimọ  ijinlẹ ti ṣe awari wọn. Apẹẹrẹ awọn eroja alailabula yi ni wúra (gold), baba (copper), fadaka (silver) imi ọjọ (sulphur), ọksijin (oxygen) ati haidrojin (hydrogen).

Ọgọfa-din-meji (118) ni awọn eroja alailabula ti a ti ṣe awari wọn. Ninu eyi, mẹrinlelaadọrun (94) ni o jẹ pe wọn jẹ eroja alailabula aitọwọda,  nigba ti awọn eroja alailabula  mẹrinlelogun (24) yoku jẹ atọwọda. Gbogbo awọn eroja alailabula yi ni awọn onimọ ijinlẹ to sinu  atẹ eroja alailabula (Periodic table).

Ohun gbogbo ti o wa ni orilẹ aye pata lo jẹ pe awọn eroja alailabula yi  ni o pilẹ wọn. Fun apẹẹrẹ bi a ba fọ ọmọ ẹda eniyan si wẹwẹ debi awọn kẹmika to kere julọ, a o rii pe ọksijin, kabọn (carbon),  haidirojin (hydrogen) ati naitrojin (nitogen) ni o ko mẹrindinlọgọrun ninu ida ọgọrun (96%)  gbogbo ohun ti a n pe ni ara ọmọ eda eniyan.

Awọn eroja alailabula yi ati bi a ṣe kan wọn pọ ni o n sọ bi nnkan ti wọn pilẹ rẹ yoo ṣe ri.  Fun itẹsiwaju lori ẹkọ yii, ẹ jẹ ka pade lori apa keji

Pín-in ká
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *