Àwọn sìgìdì (robots)| Taofeeq Adebayọ

Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Àmì ohùn: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

Bí èèyàn bá kọ́kọ́ gbọ́ tí a dárúkọ sìgìdì, ohun tí yóò kọ́kọ́ wá sí èèyàn lọ́kàn ni àwọn ère tí àwọn bàbá wa ń lò láti ọjọ́ aláyé ti dáye. Sùgbọ́n níbi tójú là dé yì, a ó rii pé orísirísi àwọn sìgìdì míràn ló ti gbòde kan. Fún ìdí èyí, a ó se ìyàtọ̀ láàrin sìgìdì àbàláyé (effigy) tí àwọn baba wa ń lò fún orísirísi nǹkan àti sìgìdì ìgbàlódé tí a fi ìmọ̀ ẹ̀rọ gbé jáde. Àwọn sìgìdì ìgbàlódé ni ó jẹ wá lógún nínú ẹ̀kọ́ yì.

Kí ni à ń pè ní sìgìdì (ìgbàlódé)? Sìgìdì jẹ́ ẹ̀ro ìgbàlódé èyí tí o lè dá iṣẹ́ tó gba làákàyé ṣe fúnra rẹ̀ láì nílò ìrànlọ́wọ́. Ẹ̀rọ ayárabíàsá (computer) ni á fi máa ń pàṣẹ fún sìgìdì. Èrọ ayárabíàsá yí lè jẹ́ apàṣẹ òkèèrè (remote control) tàbí èyí tí a dé mọ́ sìgìdì lára. A lè ṣe sìgìdì láti fi ara jọ ènìyàn tàbí ẹranko, sùgbọ́n àwọn sìgìdì tó pọ̀jù ni àwọn èyí tí wọ́n gbé kalẹ̀ fún iṣẹ́ ṣíṣe.

Àwọn sìgìdì

Ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ (technology) tí ó ń rí sí bí a ṣe ń hun sìgìdì, bí a ṣe ń tò wọ́n pọ̀, bí a ṣe ń pàṣẹ fún wọn, bí wọn ṣe ǹ lo ìmọ̀ tí a kó sí wọn lórí, bí a ṣe ń mú wọn ṣiṣẹ́ àti bí a ṣe ń fi wọ́n ṣiṣẹ́ ni à ń pè ní ìmọ̀ sìgìdì (robotics). Ohun tí ó jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ yí lógún ni bí a ṣe lè fi sìgìdì rọ́pò ọmọ ẹ̀dá ènìyàn, paapaa julọ ní ibi tó léwu, níbi iṣẹ́, àti bí a ṣe lèè mú àwọn sìgìdì ní ìrìsí ènìyàn, hùwà bí ènìyàn, tàbí kí wọ́n ronú bi ènìyàn.

Sìgìdì lè jẹ́ adáṣẹ́ṣe (autonomous) tí kò nílò àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ènìyàn kí ó tó sisẹ́. Àpẹẹrẹ èyí ni sìgìdì agbálẹ̀ (self-driving vacuum). Sìgìdì tún lè jẹ́ adáṣẹ́ṣe-nílò-àsẹ (semi-autonomous), tí ó lè dá àwọn iṣẹ́ kan ṣe fúnra rẹ̀ sùgbọ́n tó nílò àṣẹ ènìyàn láti ṣe àwọn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan.

Orísirísi sìgìdì (ìgbàlódé) ló wà: sìgìdì adára-bíèèyàn (humanoid robot), sìgìdì afara-jẹranko (animal robot), sìgìdì oníṣẹ́ (task-performing robot), atbbl. Irúfẹ́ àwọn sìgìdì yí ni a ó máa ṣàgbéyẹ̀wò nínú apá kejì.

Pín-in ká
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  

One thought on “Àwọn sìgìdì (robots)| Taofeeq Adebayọ

  1. Abdulkareem says:

    Mo ń gbádùn yin gidi gan-an

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *