Hóró (cell)| Raji Lateef & Taofeeq Adebayọ

Lámèétọ́: Adedoyin Adegbaye
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

Nínú ìmọ̀ ẹ̀dá oníyè (biology), hóró (cell) ni ẹyọ tó kéré jù tó le dá sẹ̀mí tó sì jẹ́ pé òhun ló pilẹ̀ gbogbo ẹ̀dá alààyè. Ẹ̀yà mẹ̀ta gbòógì ni hóró ní: kókó (nucleus), oje hóró (cytoplasm), ati iwọ̀ọ hóró (cell membrane).  

Hóró

Iwọ̀ọ hóró ni ó yí hóró po, òun ni ó sì n darí àwọn èròjà tó ń wọ́lé sinú hóró àti àwọn èyí tó ń jáde láti inú rẹ. Kókó jẹ́ ẹ̀yà pàtàkì ti ó wa nínú hóró tí ó jẹ́ pé nínú rẹ̀ ni a ti máa ń rí púpọ̀ nínú DNA (kẹ́míkà atọ́ka ìrandíràn) hóro. Inú kókó ni èso kókó (nucleolus) wà, inú rẹ̀ náà sì ni ìpèsè (production) púpọ̀ nínú àwọn RNA (áásììdì òjíṣẹ́) ti máa ń wáyé. Oje hóró ni èrojà olómi tí ó wà nínú hóró. 

Ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ẹ̀yà hóró míràn ló wà nínú oje hóró tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Díẹ̀ nínú wọn ni: èròjà okùn-ìran (chromatin), hihò kókó (nucleopore), abbl. Inú oje hóró ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsesí kẹ́míkà (chemical process) ti má ń wáyé. Nínú oje hóró náà ni ipèsè púpọ̀ ninu àwọn purotéènì ti máa ń ṣẹlẹ̀. 
Ẹ̀mí (life) ni a lè fi ṣàlàyé àwọn àbùdá tì àwọn ẹ̀dá-oníyè (living organism) ní tàbí iṣẹ́ tí wọn kápá làti ṣe, bíi ìrìn, íjẹ-ímu, ìbímọ, ìdàgbàsókè, abbl. Gbogbo àwọn ẹ̀dá-oníyè ni wọ́n ní agbára láti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, yálà wọ́n jẹ́ ẹ̀dá-oníyè oníhóró-kan (unicellular organism) tàbí ẹ̀dá-oníyè oníhórópúpọ̀ (multicellular organism). Hóró ni ọ̀pá-òdiwọ̀n tó kéré jùlọ tí a lè fi ṣe òdiwọ̀n ẹ̀mí tí ẹ̀dá-oníyè n lò fún àgbéjáde àwọn àbùdáa wọn. Èyí túmọ̀ sí pé tí a bá ṣe àtúpalẹ̀ àkóónú  ẹ̀dá-oníyè oníhórópúpọ̀, hóró ni a óò bá nípele tó kéré jùlọ:

Ohun tí àtẹ yìí ń ṣàlàyé ni pé àkójọpọ̀ hóró ni a óò bá nínú ìṣù-ara, nígbà tí a óò bá àkójọpọ̀ ìṣù-ara nínú ẹ̀yà-ara. Àtòpọ̀ ẹ̀yà ara ni yóò fún wa ni ètò-ara (system), tí a óò sì wáá bá oríṣìíríṣìí ètò ara nínú odidi ẹ̀da oníyè. Àwọn hóró tí ara ọmọ ẹ̀dá ènìyàn kó sìnú ju ọgbọ̀n trílíọ̀ọ̀nù (trillion) lọ.

Àwọn ẹ̀yà hóró

 1. iwọ̀ hóró: cell membrane  
 2. apààrè {a-pa-ààrè(killer of strange item)}: lysosome
 3. oje hóró: cytoplasm
 4. kókó: nucleus
 5. iwọ̀ kókó: nuclear membrane
 6. afọ̀dọ̀ti hóró vacuole
 7. apèsè-agbára mitochondrion
 8. apèsè puroteènì ribosome
 9. èso kókó nucleoid
 10. oje hóró-òun-kókó protoplasm

Àti eranko àti ewéko ni hóró wọn ni àwọn ẹ̀yà 1-10, ṣùgbọ́n nínú ti ewéko nì a óò ti má ṣe alábàápàdé ẹ̀yà 11 àti 12: 

 1. odii hóró cell wall
 2. asọ̀mọ́lẹ̀dikẹ́míka chloroplast
Pín-in ká
 •  
 •  
 •  
 •  
 •  
 •  
 •  

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *