Àwọn àbùdá òde tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) ní| Ọjọgbọn Lawrence Adewọle (OAU) & A. A. Fabeku

Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Àwọn àbùdá òde (physyical characteristics) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní ni:

(i) Àwọ̀: Àwọ̀ ni ó ń jẹ́ kí á mọ̀ bóyá funfun (white) ni nǹkan kan tàbí gbúre (pink) t̀abí pupa (red) tàbí òfèéfèé (yellow) tàbí omi ọsàn (orange) tàbí sànyán (brown) tàbí dúdú (black) tàbí aró (blue) tàbí eerú (grey) tàbí ẹsẹ̀ àlùkò (purple) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

(ii) Ìtọ́wò: Ìtọ́wò ni ó ń jẹ́ kí á mọ bí nǹkan kan bá dùn tàbí ó korò tàbí ó kan.

(iii) Òórùn: Òórun lè jẹ́ òórùn dídùn, òórùn kíkan, òórùn ìdíbajẹ, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

(iv) Yíyòòrò: Yíyòòrò níí ṣẹ pẹ̀lú pé ṣé nǹkan kan lè yòòrò tàbí kí ó yọ́ kí ó di omíyòòrò (1). 

(v) Líle: Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé ṣé nǹkan tí a ń ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ le, ṣé ó sòro láti tẹ̀, ṣé ó ṣòro láti gé tàbí pé ṣé ó ṣòro láti kán. 

(vi) Ọ̀rìn (dẹńsítì): Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú fífúyẹ́ tàbí wíwúwo nǹkan kan tí a bá fi ojú àlàfo (2) tí nǹkan náà gbà wò ó. Dẹ́ńsítì níí ṣe pẹ̀lú fífúyẹ́ tàbí títóbi nǹkan. A lè rí nǹkan tí ó tóbi tí ó sì fúyẹ́ a sì lè rí nǹkan tí ó kéré tí ó sì wúwo. Tí a bá fi ojú àbùdá báyìí wo nǹkan, ojú dẹ́ńsítì ni a fi ń wo nǹkan náà nìyẹn.

(vii) Ìrára-yí-padà (3): Awọn ohun-ẹ̀dá (substance) kan wà tí ìrísi wọn rọrùn láti yí padà. Bí apẹẹrẹ, alugbinrin (4) kan tí ó rọrùn láti yí padà sí ìrísí mìíràn ni òjé (5). Ìyẹn ni pé tí ìrísí rẹ̀ bá rí pẹlẹbẹ, ó rọrùn láti yí padà sí ìrísí tí ó dà bí okùn, bẹ́ẹ̀ ni, bí irísí rẹ̀ bá dà bí okùn, ó rọrùn láti yí i padà sí pẹlẹbẹ. 

(viii) Ìrísí Ìdì (6): Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé bóyá ohun-ẹ̀dá (substance) kan ti dì tí ó sì ní ìwò (7) kan tàbí òmíràn. 

(ix) Bí ìwò nǹkan ṣe rí nígbà tí ìgbóná ojú ọjọ́ bá bá ti inú ilé dọ́gba (room temperature) (8): Ní àsìkò tí ìgbóná ojú ọjọ bá bá ti inú ilé dọ́gba, ṅ̀jẹ́ a lè sọ pé ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) kan jẹ́ ohun tí ó dì (9) tàbí tí ó jẹ́ olómi(10) tàbí kí ó jẹ òyì/gáàsì (gas) (11). 

(x) Ọ̀gangan Yíyọ́ (12): Ọ̀gangan yíyọ́ yìí ni ibi tí ìgbóná (13) yóò dé tí ohun-ẹ̀dá (substance) yóò fi yọ́ tàbí tí yóò fi yòrò. Bí àpẹẹrẹ, ìgbóná tàbí iná tí yóò mú òrí (shea-butter) yọ́ tàbí tí yóò mú un yòrò kò lè tó èyí tí yóò mu irin yọ́. Ìyẹn ni pé iná tí yóò mú irin yọ́ yóò ju ti òrí lọ. Ọ̀gangan yíyọ́ ni ibi tí nǹkan abara-líle máa ń gbóná dé kí ó tó yọ di olómi. 

(xi) Ọ̀gangan Híhó (14): Ọ̀gangan híhó ni ibi tí iná yóò se nǹkan dé tí nǹkan olómi náà yóò fi máa hó. Ọ̀gangan híhó yìí ni nǹkan olómi ti máa ń di nǹkan aláfẹ́fẹ́, ìyẹn òyì/gáàsì (gas). Bí àpẹẹrẹ, epo máań tètè hó lórí iná ju omi lọ. Èyí fi hàn pé ìgbóná tí yóò mu epo yí padà sí òyì (gáàsì)́ kò lè tó ti omi.

Yàtọ̀ sí ìtọ́wò (taste) àti òórùn (odour) tí wọ́n ṣòro láti ṣe ìgbéléwọ̀n (15) bí wọ́n ṣe tó, gbogbo àwọn àbùdá yòókù ni a lè lò láti fi ìyàtọ̀ hàn láàrin ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) kan sí òmíràn.

Àyànkọ (note)

  1. ‘Solution’ ni a ń pè ní omíyòòrò.
  2. ‘Volume’ ni a ń pè ní àlàfo tí nǹkan gbà.
  3. ‘Malleability’ ni a pè ní ìrára-yí-padà.
  4. Metal’ ni a ń pè ní alugbinrin. Alugbinrin dúró fún ohun tí ó lè dún bí irin bí a bá lù ú.
  5. ‘Lead’ ni a ń pè ní òjé.
  6. ‘Crystalline form’ ni a ń pè ní ìdì.
  7. ‘Shape’ ni a ń pè ní ìwò.
  8. ‘Physical shape at room temperature’ ni eléyìí dúró fún. Ní àsìkò yìí ni a máa ń sọ pé nǹkan kan kò gbóná jù bẹ́ẹ̀ ni kò tutù jù.
  9. ‘Solid’ ni a pè ní ohun tí ó dì. Èyí ni nǹkan tí ó jẹ abara-líle tí ó ṣeé gbámú.
  10.  ‘Liquid’ ni a pè ní olómi.
  11.  Nǹkan aláfẹ́fẹ́ ni gáàsì, bí àpẹẹrẹ, isó, afẹ́fẹ́ tàbí ooru. Gáàsì kò ṣeé gbé dání bẹ́ẹ̀ ni kò ṣeé gbámu. A lè gbé omi (liquid) dáni ṣụgbọ́n kò ṣeé gbámú. A lè gbá nǹkan tí ó ba dì (solid) mú a sì lè gbé e dáni.
  12.  ‘Melting point’ ni a pè ní ọ̀gangan yíyọ.
  13.  ‘Temperature’ ni a pè ní ìgbóná.
  14.  ‘Boiling point’ ni a ń pè ní ọ̀gangan híhó.
  15.  ‘Quantitative evaluation’ ni a  pè ní ìgbéléwọ̀n bí wọ́n ṣe tó. Bí wọ́n ṣe tó yìí lè jẹ́ nípa kíkà tàbí wíwọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, a kò lè ka òórùn bẹ́ẹ̀ ni a kò lè ka bí títọ́ tí a tọ́ nǹkan wò ṣe tó.
Pín-in ká
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  

One thought on “Àwọn àbùdá òde tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) ní| Ọjọgbọn Lawrence Adewọle (OAU) & A. A. Fabeku

  1. Taofeeq Adebayo says:

    Imọ ijinlẹ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *