Ayé Nẹ́ptúùn (Neptune)| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́: Alabi Sherif
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ó yá ẹ dáhun ìbéèrè yìí: ayé wo ló jìnà jù sí òòrùn nínú sàkáání òòrùn wa? Ẹ tún wá nǹkan fìdí lé bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú apá kẹtàlá yìí lórí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Níbáyìí, ẹ bá wa kálọ sí orí ayé tí a mọ́ orúkọ rẹ̀ sí Nẹ́ptúùn.

Nẹ́ptúùn ni ó súnmọ́ òòrùn sìkẹjọ. Nẹ́ptúùn yí kan náà ni ó jìnà sí òòrùn jù nínú gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn (solar system) wa. Òótọ́ ni pé àwọn abara òfuurufú (celestial body) kan wà bíi Plútò tí àwọn tún jìnà ju Nẹ́ptúùn lọ, sùgbọ́n àwọn abara òfuurufú yíì kíì ṣe ayé; aràrá ayé (dwarf planet) ni wọ́n.

Ìgbóná-tutù (temperature) tó wọ́pọ̀ jù lórí Nẹ́ptúùn jẹ́ Sẹ́síọ́sì igba-lé-mẹ́wàá òdì (-210 Celsius). Wákàtí mẹ̀rìndínlógún lórílẹ̀ ayé wa yí ni ọjọ́ kan lórí Nẹ́ptúùn. A ó ka bíi ọdún márùn-dín-láàdọ́sǎn (165) lórílẹ̀ ayé kí ọdún kan ó tó pé lórí rẹ̀.

Bí a bá fi ojú àyípo (circumference) wòó, Nẹ́ptúùn ló tóbi sìkẹrin nínú sàkáání òòrùn wa. Yóò tó mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ilé-ayé tí à ń gbé orí rẹ̀ yí tí yóò parapọ̀ kí á tó leè mú Nẹ́ptúùn ẹyọ kan jáde.

Gẹ́gẹ́ bíi Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn jẹ́ ayé ràbàtà oní-yìnyín (ice giant). Àwọn ayé ràbàtà (giants) mẹ́rin ló wà ní sàkáání òòrùn wa. Àwọn ayé ràbàtà yi ni Júpítà, Sátọ̀n, Yúránọ́ọ̀sì àti Nẹ́ptúùn. Nẹ́ptúùn ló kéré jù láàrin àwọn ayé wọ̀nyìí.

Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn kò ní orílẹ̀ kankan tí ènìyàn le dúró lé lórí. Alagbalúgbú òyì (gas) ló yí orí rẹ̀ po. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn náa ní àwọn òrùka. Àwọn òrùka mẹ́fà gbòógì ló pagbo yíi ká.

Bákanáà, mẹ́rìnlá ní àwọn òsùpá tí ìwádǐ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ń rábàbà yípo Nẹ́ptúùn.

Gẹ́gẹ́ bí Mẹ́kíúrì, Àgùàlà, Júpítà, Sátọ̀n àti Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn kò leè jẹ́ ibùgbé fún àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wọ́n.

Pín-in ká
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *