Ayé Sátọ̀n| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́ (proofreader): Bọde Ọjẹ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ẹ tún káàbọ̀ padà sí orí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Nínú apá kọkànlá yí, a ó máa tẹ̀ sí wájú sí orí ayé tí a mọ orúkọ rẹ̀ sí Sátọ̀n (Saturn).

Sátọ̀n ni ayé tí ó súnmọ́ òòrùn sìkẹfà. Sátọ̀n yí kan náà ni ó tóbi sìkejì nínú gbogbo àwọn ayé mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tó wà ní sàkáání òòrùn wa (our solar system). Gẹ́gẹ́ bíi Júpítà, Sátọ̀n jẹ ayé ràbàtà oní gáàsì (gas giant). Háídrójìn àti hílíọ́ọ̀mù ni gáàsì tí ó pọ̀ jù nínú àwọn ohun tó pilẹ̀ Sátọ̀n. Yóò ju ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta (700) ilé ayé wa yí lọ tí yóò parapọ̀ kí á tó le rí Sátọ̀n eyọ kan mú jáde.

Sátọ̀n dá yàtọ̀ láàrin àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn wa bí ó se jé pé òhun ló ní àwọn òrùka (rings) tó pọ̀ jù tí ó sì rinlẹ̀ jù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé yúránọ̀ọ̀sì náà ní àwọn òrùka, àwọn òrùka yúránọ́ọ̀sì kò rinlẹ̀ bíi ti Sátọ̀n. Yìyín àti àpáta èyí tí àwọn ohun bíi eruku ti yí lára ni ó parapọ̀ di àwọn òrùka Sátọ̀n. Àwọn ẹrun yìyín ati àpáta tí à ń sọ yí le kéré jọjọ, wọ́n sì leè tóbi tó odidi ilé. Mẹ́tàléláàdọ́ta (53) àwọn òsùpá ni ìwadìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ pé wọ́n ń rábàbà yípo (orbit) Sátọ̀n. Àwọn òsùpá Sátọ̀n mọ́kàndílọ́gbọ̀n (29) ni à ń dúró kí ìwadìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fi ìdí wọn múlẹ̀.

Ní ìwọ̀n bí Sátọ̀n ṣe jìnà sí òòrùn sí, yóò gba ìtànsán òòrùn ní ọgọ́rin ìṣẹ́jú kí ó tó dé orí Sátọ̀n. Ìsẹ́jú mẹ́jọ àti ogún ìṣẹ́jú àáyá ló má ń gba ìtànsán òòrùn láti rin ìrìn àjò láti orí òòrùn sí orílẹ̀ ayé. Nínú gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn wa, ọjọ́ lórí Sátọ̀n ló kéré sìkejì. Wákàtí mẹ́wǎ àti ìṣéjú méjìlélógójì tí à ń kà lórílẹ̀ ayé ni ọjọ́ kan lórí rẹ̀. Bákan náà, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, oṣù mẹ́rin àti bíi ọjọ́ mẹ́rìnlélógún tí à ń kà lórílẹ̀ ayé ni ọdún kan lórí rẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátọ̀n ní ààrin gbùngbùn (core) tó jẹ́ ohun líle, àwọn gáàsì tó dàbí omi ló yíi po. Èyí túmọ̀ sí pé Sátọ̀n kò ní orílẹ̀ tí ènìyàn le dúró lé lórí gẹ́gẹ́ bíi ayé wa yí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò súnmọ́ kí ìgbóná-tutù (temperature) orí Sátọ̀n fi ààyè gba ẹ̀dá abẹ̀mí, ó ṣeéṣe kí àwọn òsùpá rẹ̀ seé gbé fún àwọn ẹ̀dá alààyè.

Ǹjẹ́ ẹ́ gbádùn àkójọpọ̀ ìmọ̀ yí? Bí ó bá rí bákan náà, ẹ jẹ́ ká tún pàdé lórí apá kejìlá ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé níbi tí a ó ti máa ṣe àgbéyẹ̀wò ayé yuranọọsi.

Pín-in ká
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  
  •  

3 thoughts on “Ayé Sátọ̀n| Taofeeq Adebayo

  1. Ajayi segun says:

    Eku ise opolo sir

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *