Báwo ni kí a ṣe pe “million”, “billion” ni Yoruba?

How do you say 1 million in Yoruba? How about 1 billion? 1 trillion? 1 quadrillion? 1 quintillion?…

How do you say 1 million in Yoruba? How about 1 billion? 1 trillion? 1 quadrillion? 1 quintillion?…

Posted by Science in Yoruba on Wednesday, October 18, 2023

Atakóró wọnú wínní-wínní 4| Fààbú sáyẹ́ǹsì láti ọwọ́ Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀

Lámèétọ́: Raji Lateef
Olóòtú: Taofeeq Adebayo

Atakóró wọnú wínní-wínní 1
Atakóró wọnú wínní-wínní 2
Atakóró wọnú wínní-wínn 3

Bí e̩lé̩rò̩ ti wú bàǹtù tán, Ìmó̩wùnmí rí i pé ohun alágbára mẹ́ta kan wà nínú rẹ̀ lọ́hùn-ún tó ń yí bírípe-bírípepe lu ipá-okùn ńlá kan nínú rè̩. Bàbáa rè̩ bẹ̀rẹ̀ àlàyé wípé, “níbi tí a dé yìí lagbára ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ gbé e dé sàn-án-sàn-án nípa ìwádìí ohun tó kéré jọjọ, àforírò tàbí tí ẹ̀rí díẹ̀ wà fun ni gbogbo èyí tó kù nítorí è̩rí s̩ò̩wó̩n fún wo̩n. Àwọn ohun mẹ́ta wọ̀nyí là bá máa pè ní kín-ún agbára nítorí níbi, kò sí ọ̀rọ̀ pé ohun kan lówúra mọ́, agbára ni owúra, owúra sì ni agbára. Okun kín-ún yìí náà wà nínú alè̩rò̩ pè̩lú. Ìwásókè-wásílẹ̀ lagbára inú kín-ún kọ̀ọ̀kan fi yàtọ̀ síra.”

Wọ́n sún mọ́ etí obiri eléro láti wo kín-ún mẹ́tẹ̀èta inú rẹ̀ dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò wo inú rẹ̀. Bàbá Ìmó̩wùnmí ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ wípé: “Ṣé o ránt́i Egúngún Aroyeyo?” Ìmó̩wùnmí ni bẹ́ẹ̀ ni. Bàbá ní, “Nígbàkígbà tí egúngún náà bá ń jó, ó lè lọ́ biiri bí òkòtó tó ń jó ràn-ìn-ràn-ìn, ó sì lè tàkìtì.” Ìmó̩wùnmí tún ní béè ni. “Kín-ún tóò ń wò yí lè ṣe nǹkan méjì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo: ó lè jó ràn-ìn-ràn-ìn kó tún tàkìtì pò̩ lé̩è̩kan náà. Méjéèjì yìí ló ń sọ bí kín-ún yóò ṣe gbagbára sí.

Bí kín-ún kan nínú mẹ́ta bá wá dorí kodò (D), táwọn méjì tó kù sì síjú-sókè (U), ó níye agbára tó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ rẹ̀ ti wà nínú àwòrán tí n óó yà fún ọ sí ìsàlẹ̀ yìí.” Bàbá gba ìwé lọ́wọ́ Ìmó̩wùnmí ó ya àwòrán ìjóràn-ìn àti ìgbágbára-sí-kín-ún. Ìmó̩wùnmí ń wò bi agbára kín-ún náà ti pò tó. Ó fẹ́é fi agbára jáde pẹ̀lú ìbínú ńlá nínú e̩lé̩rò̩ ṣùgbọ́n ewé-agbéjẹ́ẹ́ tí bàbá rẹ̀ ti mú u mọ́lẹ̀ kò jẹ́ kó lè ṣe ohun kan. Ọgbọ́n kan wá si Ìmó̩wùnmí lórí. Bàbáa rẹ̀ ń fi ojú ẹ̀gbẹ́ kan wò ó láìmọ̀, ó sì ń rẹ̀rín músẹ́.

Lójijì ni Ìmó̩wùnmí fọn fèrè o̩wó̩ọ rè̩. Ó fẹ́ kí kín-ún wu, kí òun lè wo ohun tó ḿ bẹ nínú rè̩, s̩ùgbó̩n ìjayà tó rí lójú bàbáa rè̩ bà á lẹ́rù púpò̩. Bàbáa rè̩ wípé “kí ló dé tó s̩e èyí láìso̩ fún un? Págà! S̩àǹgbàfó̩! Mo dáràn, àfi ká tètè darí relé.”

Wọn kò kúkú bó̩ sílẹ̀ nínú o̩kò̩ ò̩ge̩re̩re̩ tí wó̩n wà láti ìgbà yìí wá. Wó̩n dari o̩kò̩ náà padà síbi tí wó̩n ti ń bọ̀, wó̩n sì bè̩rè̩ sí sá lo̩ sí ìta-gbangba pada pè̩lú eré burúkú. Gbogbo bí wó̩n ti ń lo̩ ni ohun gbogbo ń dà wó lulẹ̀ léyìn-in wọn. Àrá ń sán, òǹfà sì ń fà wó̩n padà sẹ́yìn. Rògbòdìyàn wà níbi gbogbo nínú wínnípin náà. Gbogbo àwo̩n eléro tí wó̩n ń ko̩já rè̩ lákò̩ó̩kó̩ ti di òkò eléruku dúdú. Ìrínìmò̩ bè̩rè̩ síí darí o̩kò̩ náà sí-ì-hín-sọ́-ọ̀-hún kó má baà forí gbárí pè̩lú àwo̩n òkò náà. Wàhálà dé bá o̩mo̩ àti baba. Bé̩è̩ ni ohun gbogbo ń kéré síi, tí òǹfà alágbára kan sì ń fà wó̩n padà sáàárin gbùngbùn wínnípin náà. Tipátipá ni wó̩n fi rí o̩kò̩ náà wà jáde láti inú wínnípin bọ́ sínú òkùnkùn lóde. Wó̩n rí àwo̩n wínnípin tó kù bí wó̩n ti lo̩ be̩e̩re̩, s̩ùgbó̩n ohun abàmì mííràn tún s̩e̩lè̩.

Bí to̩mo̩tibàbá s̩e ń dúpẹ́ pé àwó̩n ja àjàbọ́ó nínú kóro wínnípin náà, bé̩è̩ ni wó̩n rí gbogbo wínnípin bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ síí hùwà bákan náà.  Rògbòdìyàn ti wà nínú àwọn náà pẹ̀lú bó tilè jé wípé bàbá àto̩mo̩ kò wọ inú gbogbo wọn lọ. “Kí ló lè fa èyí?”, O̩mo̩ béèrè lọ́wọ́ bàbáa rẹ̀, ṣùgbọ́n bàbá ní òun kò mọ̀ ohun tó lè fà á. Okùn ńlá kan bẹ̀rẹ̀ síí fà wọ́n bí ẹní n fa doro-omi láti inú kàǹga.

Wó̩n jáde síta, wó̩n sì lo̩ pàdé ìyá o̩mo̩ náà níbi tó ti ń dúró dè wó̩n tè̩rín-tè̩rín. O̩mo̩ náà bè̩rè̩ síí so̩ ohun tí ojú rẹ̀ rí àti ohun tó s̩e̩lè̩ fún ìyá rè̩, pàápàá jùlo̩, ibití rògbòdìyàn ti dé nígbà tí òun fo̩n fèrè pé kí e̩lé̩rò̩ wú kí òun baà lè rí ohun tí ḿ be̩ nínú rè̩. Ìyá ní “s̩é lóòótó̩.” Ìyá àti bàbá wo ojú ara wo̩n, wó̩n sì fi ojú sò̩rò̩ síra pè̩lú è̩rín wípé mò̩-sínú-mò̩-síkùn. Wó̩n jáde nínú Ìkò̩lé-Òfeefèé, àko̩mò̩nà kán wà tí o̩mo̩ náà kò s̩e àkíyèsí nígbà tí wó̩n kó̩kó̩ wo̩lé.Àko̩mò̩nà náà kà báyìí wípé:

“NÍBÍ NI A TI Ń FI ÀWÒRÁN ÒFEEFÈÉ S̩ÀLÀYÉ ÌMÒ̩ ÌJÌNLÈ̩ NÍ KÍKÚN.”

Gbogbo bi wó̩n ti padà sílé lọ́jọ́ náà, inú ìrònú ni Ìmó̩wùnmí wà. Ó ń ronú ohun tó sẹlẹ̀ nígbà tí àwo̩n wínnípin bẹ̀rẹ̀ síí hùwà bákan náà bíi pé ọ̀kan ṣoṣo ni wọ́n. Ò̩ràn náà kan Ìmó̩wùnmí lóminú gan-an ni. 

Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, o̩mo̩débìrin náà so̩ fún bàbá rè̩ pé ó dàbí e̩ni pé òun ti mo̩ ohun tí ń s̩e̩lè̩. Ó ní lẹ́yìn tóun ti tún ka ìwé kún ìwé, tí òun sì ní ìmò̩ síi nípa ìmò̩-ìjìnlè̩, òun ní àrígbèrò (4) kan pé bóyá ni kìí s̩e pé wínnípin jé̩ bíi odidi ò̩salalu kan yàtò̩ sí ìdo-ayíbiiri bí wó̩n ti gbèrò té̩lè̩ rí. Ìye̩n ni pé odidi ò̩salalu (5) kékeré kan ni wínnípin, ohun tó bá sì ń s̩e̩lè̩ sí ọkan ń s̩e̩lè̩ sí èkejì lásìkò kan náà.

Bàbá rè̩ ya e̩nu nígbà tó gbó̩ èrò Ìmó̩wùnmí, ó wípé, káre láé.

Àyànkọ (note)
1. kín-ún – quarks
2. Owúra – mass. matter. Lówúra – has mass
3. Agbára ni owúra, owúra sì ni agbára – mass equals energy and energy equals mass.
4. Àrígbèrò – hypothesis
5. ò̩salalu – universe (uni=one, versus=turned, thus one version of different things that turned into one big whole), rendered in Yoruba here, ò̩salalu means one thing that spreads all out.

Àwọn òògùn olóró àti ewu wọn 1| Ibrahim Abdul-Azeez & Lateef Adeleke

Lámèétọ́: Raji Lateef
Olóòtú: Taofeeq Adebayo
Òsùbà àwòrán: gabriel12/Shutterstock

Òògùn olóró (hard drugs) máa ń sáàbà túmò̩ sí àwo̩n òògùn tí ó léwu tí ó sì le sokùnfà kí èèyàn gbára lé wo̩n. Òògun bíi ẹroíìnì (Heroin) àti kokéènì (cocaine) le ju àwo̩n òògùn tí a fi ojú lílẹ ̣wò lo̩ bíi igbó. Sùgbọ̀n sá o, lìlò ọ̀rọ̀ àpéjúwe “líle” àti “lílẹ” fún òògùn olóró kò níí ìfe̩sè̩rinlè̩ òfin tàbí ìmò̩ òògùn. Àwo̩n òògùn yíì ní agbára láti se okùnfà àwo̩n ìpalára àfojúrí àti ti ajẹmọ-ọpọlọ.

Àwo̩n òògùn líle ní agbára tó n sọ́ wọ́n di bárakú fún ènìyàn. Àpe̩e̩re̩ wo̩n nì: kokéénì (cocaine), opiéèti [opiates] (aidirokọ́dọ̀n [hydrocodone], àti mọfììn [morphine]), bẹnsodiasifíìnì [benzodiazephines] (diasipáàmù [diazepam], lọrasipáàmù [lorazepam]), mẹtamfẹtamíìnì [methamphetamine], ògógóró, nikotíìnì [nicotine].

Èrò lóríi bí àwo̩n ènìyàn ṣe ń so̩ òògùn olóró di bárakú kò tíì yé ò̩pò̩ ènìyàn. Sísò̩ òògùn di bárákú jé̩ ààrùn tó ṣòro kojú nítori àbùdá ìṣàwárí àti lílo irú òògùn bẹ́ẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí ìṣòro àtikápá àìlè kóra ẹni níjàánu lórí lílo àwọn òògùn bẹ́ẹ̀ láìbíkítà àwọn aburú tó lè gbẹ̀yìn irú ìsesí bé̩è̩. Àtúnlò òògùn kan nígbàdégbà lè fa ìyípadà ìṣesí o̩po̩lo̩ tí yóò sì dènà agbárá ìkóra eni níjanu fún e̩ni tí òògùn ti di bárakú fún ní gbogbo ìgbà tó bá ti ní ìmọ̀lára tàbí tí ẹ̀mí ẹ̀ bá ti fà sí àtilo òògùn bẹ́ẹ̀. Àwọn ìyípadà ìṣesí ọpọlọ bẹ́ẹ̀ lè máa wáyé nígbàdégbà. Ìdí nìyí tí ìkúdùn òògùn fi jé̩ ààrùn tó se ni láàánú nítorí ó jẹ́ àrùn onífàsẹ́yìn.

Síbè̩síbè̩, a kò ṣàìlè rí àwo̩n àbùdá àbímó̩, ajẹmọ́-agbègbè, àti ajẹmọ́-ìdàgbàsókè tó jé̩ ò̩pò̩ lára àwo̩n àbùdá tí ó máa ń fa ìkúdùn òògùn. Bí ènìyàn bá ti ní àbùdá tó léwu yìí sí, be̩e̩ ni ipá àti so̩ òògùn di bárakú yóò se pò̩ sí fún irú e̩ni bé̩è̩.

Lílo òògùn olóró  máa ń fa ò̩pò̩ ìpalára tó lágbára. Lára ìpalára bẹ́ẹ̀ ni ìlóró [ì-ní-oró] (toxicity) òògùn nínú ara. Ìlóró òògùn jẹ́ ìjẹyọ àwo̩n ìpalára alágbára ajẹmọ́-òògùn lára, èyí tí o le pada bèèrè fun ìjáwó̩ nínú òògun láìtó̩jó̩ tàbí dídí ìwò̩n ìlòo wọn kù.

Ayé Nẹ́ptúùn (Neptune)| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́: Alabi Sherif
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ó yá ẹ dáhun ìbéèrè yìí: ayé wo ló jìnà jù sí òòrùn nínú sàkáání òòrùn wa? Ẹ tún wá nǹkan fìdí lé bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú apá kẹtàlá yìí lórí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Níbáyìí, ẹ bá wa kálọ sí orí ayé tí a mọ́ orúkọ rẹ̀ sí Nẹ́ptúùn.

Nẹ́ptúùn ni ó súnmọ́ òòrùn sìkẹjọ. Nẹ́ptúùn yí kan náà ni ó jìnà sí òòrùn jù nínú gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn (solar system) wa. Òótọ́ ni pé àwọn abara òfuurufú (celestial body) kan wà bíi Plútò tí àwọn tún jìnà ju Nẹ́ptúùn lọ, sùgbọ́n àwọn abara òfuurufú yíì kíì ṣe ayé; aràrá ayé (dwarf planet) ni wọ́n.

Ìgbóná-tutù (temperature) tó wọ́pọ̀ jù lórí Nẹ́ptúùn jẹ́ Sẹ́síọ́sì igba-lé-mẹ́wàá òdì (-210 Celsius). Wákàtí mẹ̀rìndínlógún lórílẹ̀ ayé wa yí ni ọjọ́ kan lórí Nẹ́ptúùn. A ó ka bíi ọdún márùn-dín-láàdọ́sǎn (165) lórílẹ̀ ayé kí ọdún kan ó tó pé lórí rẹ̀.

Bí a bá fi ojú àyípo (circumference) wòó, Nẹ́ptúùn ló tóbi sìkẹrin nínú sàkáání òòrùn wa. Yóò tó mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ilé-ayé tí à ń gbé orí rẹ̀ yí tí yóò parapọ̀ kí á tó leè mú Nẹ́ptúùn ẹyọ kan jáde.

Gẹ́gẹ́ bíi Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn jẹ́ ayé ràbàtà oní-yìnyín (ice giant). Àwọn ayé ràbàtà (giants) mẹ́rin ló wà ní sàkáání òòrùn wa. Àwọn ayé ràbàtà yi ni Júpítà, Sátọ̀n, Yúránọ́ọ̀sì àti Nẹ́ptúùn. Nẹ́ptúùn ló kéré jù láàrin àwọn ayé wọ̀nyìí.

Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn kò ní orílẹ̀ kankan tí ènìyàn le dúró lé lórí. Alagbalúgbú òyì (gas) ló yí orí rẹ̀ po. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn náa ní àwọn òrùka. Àwọn òrùka mẹ́fà gbòógì ló pagbo yíi ká.

Bákanáà, mẹ́rìnlá ní àwọn òsùpá tí ìwádǐ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ń rábàbà yípo Nẹ́ptúùn.

Gẹ́gẹ́ bí Mẹ́kíúrì, Àgùàlà, Júpítà, Sátọ̀n àti Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn kò leè jẹ́ ibùgbé fún àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wọ́n.

Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Biology)| Raji Lateef

Lámèétọ́: Taofeeq Adebayọ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

Látìgbà láéláé ni àwọn ènìyàn ti máa ń fẹ láti mọ̀ síi nípa àwọn nǹkan tó wà ní àyíkáa wọn, pàápàá àwọn ohun abẹ̀mí. Èyí ló fa ẹ̀kọ́ nípa àwọn ẹ̀dá-oníyè – Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Biology).

Oríkì (Definition) àti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Branches of Biology)

Ara ọ̀rọ̀ Gíríkì méjì ni wọ́n ti ṣẹ̀dá Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè, tí ń ṣe ‘Biology.’ Àkọ́kọ́ ni bios tó túmọ̀ sí ẹ̀mí nígbà tí èkejì tó jẹ́ logos túmọ̀ sí ẹ̀kọ́. Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀mí (life). A lè rí Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀kọ́ nípà àwọn ewé (plants) àti àwọn ẹran (animals).

Ẹ̀ka méjì gbòógì ni Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè ní. Èyí kò sọ pé kò sí àwọn ẹ̀ka mííràn:

  1. Ẹ̀kọ́ Ẹranko (Zoology): Èyí ni ẹ̀kọ́ nípa gbogbo àwọn ìran ẹran (animals).
  2. Ẹkọ́ Ewé (Botany) ni ẹ̀kọ́ nípa gbogbo ìran ewé àti igi. 

Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ka méjì òkè yìí, àwọn ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè mííràn ló wà ní ìsàlẹ̀ yìí: 

  1. Ẹkọ́lọ́jì (Ecology) ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun abẹ̀mí (living things) – yálà ewé àbí ẹran – àti àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àyíká.
  2. Mọfọ́lọ́jì (Morphology) ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn àbùdá-òde (external features) àwọn ewé àti ẹran.
  3. Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́-ìrísí-inú (Anatomy): Ẹ̀yí ni ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè mííràn tó ń ṣàlàyé àwọn ìrísí inú (internal structures) àwọn ewé àti ẹran.
  4. Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́ran (Genetics): Èyí ni ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì tó jẹ́ ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè tó ń ṣàlàyé nípa àwọn àbùdá àjogúnbá (heredity) àti ìyàtọ̀/àìjọra (variations) àwọn àbùdá bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ẹ̀dá oníyè (living things).
  5.  Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́-Ìṣesí Ẹ̀dá-oníyè (Physiology): Èyí ló ń ṣàlàyé nípa àwọn ìṣesí, ìwúlò tàbí àǹfàní (functions) àwọn ewé àti ẹran (living things).

Orísun: Essential Biology for Senior Secondary School (Ninth Edition)
Orísun àwòrán: https://english-online.org.ua/materials/13468

Atakóró wọnú wínní-wínní 3| Fààbú sáyẹ́ǹsì láti ọwọ́ Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀

Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Atakóró wọnú wínní-wínní 1
Atakóró wọnú wínní-wínní 2

Lẹ́yìn ti wó̩n ti s̩àlàyé èyí yékéyéké fun ara wó̩n tí Ìmó̩wùnmí sì ti so̩ wípé ó yé òun yékéyéké, Ìrínìmò̩ bàbá Ìmó̩wùnmí wò ó pé è̩kó̩ tí òun kó̩ o̩mo̩ náà lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ti pọ̀ jù, kò sí fé̩é̩ jẹ́ kí è̩kó̩ kíkọ́ náà sú u. Ó bè̩rè̩ síí pògèdè, o̩mo̩ rè̩ sì ń wò ó tìyanu-tìyanu pé èwo ni bàbá òun tún gbé dé yìí. Ìrínìmò̩ wípé:

“Bí o̩mo̩dé bá sáré tete títí, á rè̩ é̩ á dúró
Bágbà bá sáré tete títí á rè̩ é̩, á dúró
Bó ti wù kí abẹ̀bẹ̀ òyìnbó sáré tó,
Bíná bá lo̩ yóò dúró
Ó yá, ìwọ ohun tí ǹ jù ràìn-ràìn yìí, 
Dúró jẹ́jẹ́ ká lè rí o̩.”

Bi Ìrínìmò̩ ti so̩ èyí, ó jọ bíi pé ẹnìkan ré̩rìn-ín nínú ò̀okùn ló̩hùn-ún, Ìmó̩wùnmí wò ó pé irú è̩rín tí ìyá òun máa n rín lèyí, s̩ùgbó̩n kò rẹ̀níkan. Ìrínìmò̩ kọjú só̩mo̩ rè̩, ó sì so̩ pé, “ṣé ò ń fi ohun tí à ń ṣe ré̩rìn-ín ni? Òògùn yìì kò níí jẹ́!” Ọmo̩ọ̀ rè̩ ní òun kó̩ ni òun ré̩rìn-ín, wó̩n sì ń báṣẹ́ wó̩n lọ. Ó jọ bíi pé ẹni tó ń ré̩rìn-ín náà ti gbọ́ àrokò tí wó̩n pa ránṣé sí i. Ó di wélo.

Nígbàti wó̩n yóò sì fi wo ibi tí wínnípin (atom) náà wa, ó ti tóbi tó odidi ilé ńlá kan. Inú Ìmó̩wùnmí ń dùn pé fèrè òun s̩iṣé tí wọ́n rán an. Bí wó̩n ti sún mọ́ ọ, wó̩n rí i pé àwo̩n ohun ródóródó kan ni ohun tí ń jù fìrìfìrì yì i ká tí kò dúró sójú kan. Ìrínìmò̩ bè̩rè̩ ò̩rò̩ rè̩ wípé:

“Àwo̩n ohun tóò ń wò yìí là bá pè ní eléro (electron) nítorí pé agbára rè̩ wà ní èro (negatively charged). Àwo̩n wò̩nyí sì dàbí ayíbiri (planet) bí o ti wí lẹ́ẹ̀kan. Nínú ìs̩o̩wó̩-wà-létò wínnípin, eléro yìí ń sáré yíká kókó kékeré kan tó wà làáárín. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín bí wínnípin àti bí ido-ayíbiiri-móòrùn (solar system) tiwa tiri ni pe àwo̩n eléro tó dúró gé̩gé̩ bíi ayibiiri wà létò létò lójú ìpòòyì won, méjì sì lè wà ní ìfè̩gbé̩kè̩gbé̩ lórí òbìrí-ìyíbiiri (orbit) kan s̩os̩o. Ohun tó wà láàárin gbùngbùn ló̩hùn-ún là ń pè ní e̩lé̩rò̩ (proton) nítorí pé agbára rè̩ wà ní è̩rò̩ (positively charged). A óò sì lo̩ ba eléyìí tó bá yà.”

Ìmó̩wùnmí ya àwòrán gbogbo ohun tó rí náà sínú ìwé pélébé o̩wó̩ọ rè̩ níwọ̀n bó ti s̩e lè gbìyànjú kó jọra tó. Ó sì tún ko̩ orúko̩ àwo̩n ẹ̀yà ara rè̩ si lára báyìi:

Bàba rè̩ wo ohun tó yà sínú ìwé, inú rè̩ sì dùn. Bàbá náà ń bá ò̩rò̩ rè̩ lo̩ báyìí:

“Ìtò lẹ́sẹsẹ eléro lórí òbìrí-ìyíbiiri nínú wínnípin yìí là ń pè ní ìs̩o̩wó̩wàlétò eléro (electron configuration). Mo fẹ́ kóo fi ọkan sóhun tí mo tún fé̩é̩ so̩ láti ìsin yìí lo̩ dáadáa nítorí pé wó̩n s̩e pàtàkì púpò̩. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ni ó dáhùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìníèròjà-ibambaye tó jé̩ ojúlówó (pure element) tí kìí s̩e àdàlú tàbí àbùlà (compound). Òbìrí-ìyíbiiri yìí náà tún jẹ́ ìpele agbára (energy level) inú wínnípin. Òun ló sì fà á tí ohun gbogbo nínú ayé fi ní owúra (mass). Bí a bá wo wínnípin yìí dáadáa, a óò fé̩rè̩ lè so̩ pé òfifò ni gbogbo rè̩, nítorí ká tóó lè de ibi tí ààrin gbùngbùn àti kókó e̩lé̩rò̩ (nucleus) rè̩ wà, wínnípin yóò ti fé̩rè̩ wú ní títóbi tó odidi orílẹ́-èdè kan ká tó lè rí kókó e̩lé̩rò̩ àárin náà bíi o̩sàn-àhómu. Síbẹ̀, àjọṣepọ̀ ńlá ń bẹ láàárín atakókó àárin tó jẹ́ kókó náà àti eléro tí ń yí i ká ló̩nà jíjìn réré sí i. Ìfànfà tó ń wáyé láàárín agbára èro àti è̩rò̩ àwo̩n méjéèjì yìí ló sì jẹ́ kí gbogbo ibi tí a rò wípé ó ṣófo láàárín wó̩n náà jẹ́ gbalasa-àrádòǹfà (electromagnetic field). Inú rè̩ sì ni gbogbo eléro tí wínnípin kan bá ní tí ń yí wà. S̩ùgbó̩n sá, ní ìpele ìpele bí as̩o̩ àlùbó̩sà ni òbìrí-ìyíbiiri àwo̩n eléro náà wa, bé̩è̩ gé̩gé̩ ni wó̩n sì s̩e ní agbára sí. Ìpele èyí tó sún mó̩ àárin ló ní agbára tó kéré jù. Ìpele tó tún po̩wó̩ lé e ló tún lágbára tó pò̩ díè̩ sí, bé̩è̩ títí dé ìpele tó parí sí ìta, ìyẹn nìpele tí òbìrí-ìyíbiiri rè̩ fè̩ jù; òun ló lágbára tó pọ̀ jù.”

Ìmó̩wùnmí tún ya àwòrán mííràn nípa nǹkan wò̩nyí:

Òbìrí-ìyíbiiri tó kẹ́yìn yìí ló dà bí ọgbà tàbi ìkaraun(shell) tó s̩e ìpinyà àti ààlà láàárín wínnípin kan sí èkejì. E̩lé̩rò̩ àti eléro sì ti fi agbára-aradonfa mu ara wó̩n dúró lójú òbìrí-ìyíbiiri kan títí láé àfi bí ọ̀kan bá ṣèèsì tasè̩ àgè̩rè̩ wo̩ gbalasa wínnípin (valence) òmíràn. Ó s̩eé s̩e kí èyí wáyé, yálà ó s̩èès̩ì s̩e̩lè̩ nínú àbámáyé ni tàbí o̩mo̩-ènìyàn mò̩ó̩mò̩ s̩okùnfàa rè̩. Ìtasè̩-àgè̩rè̩ eléro wo̩ gbalasa wínnípin òmíràn ni ìbè̩rè̩ pẹ̀pẹ̀ ohun gbogbo tiis̩e ẹlé̩mìí, ìmò̩ó̩mò̩ s̩okùnfàa rè̩ ló sì bí gbogbo è̩ro̩ tí ń lo iná-mò̩nàmó̩ná láti s̩is̩é̩, ìyẹn gbogbo è̩ro̩-alonás̩is̩é̩ (electronics). 

Ìwọ o̩mo̩ọ̀ mi, mo wá fé̩ kó mo̩ ohun kan nípa inú wínnípin àti àyíká rè̩, èyí sì ni pé, bí ò̩nà eléro ti jìnà sí ata-kókó-àárin (nucleus) tó ní agbára rè̩ pọ̀ tó, bó sì ti súnmó̩o̩ sí ni agbára àrádòǹfà (electromagnetic force) náà s̩e ń dín kù sí. Ìtumọ̀ èyí ni pé, agbára-ìjá-fáfá àwo̩n eléro tó wà nínú kò tó tàwo̩n eléro tó jìnà sáàárín. Fún àpe̩e̩re̩, bí a bá fún àwo̩n òbìrí-ìyíbiiri náà ní àpèlé láti orí èyí tó wà nínú àti èyí tó pọwọ́ lé e títí dé èyí tó wà lóde, ipò-agbára èyí tó wà lóde ni yóò pọ̀ ju, òun sì ló ni eléro tó pọ̀ jù.

Níbí ni Ìmó̩wùnmí ti fi ìfẹ́ rè̩ han láti mò̩ ohun tí ń bẹ nínú atakókó tó wà láàárin gbùngbùn wínnípin, bàbá rè̩ sì wípé ó ti yá láti rìnrìn àjò lo̩ sí àárin gbùngbùn náà. S̩ùgbó̩n bàbáa rè̩ so̩ fún un pé, kí àwo̩n tóó lè rí ohun tó wà láàárín gbùngbùn náà dáradára, àwo̩n yóò ní láti mú kí wínnípin náà fẹ̀ tó odidi orílé-èdè kan. Bàbáa rè̩ sí wì fún ún kó fo̩n fèrè o̩wó̩ọ rè̩ lé̩è̩kan sí i, àtipé bí fèrè náà bá fo̩n lẹ́ẹ̀kan, iye ìlọ́po ló̩nà e̩gbe̩gbè̩rún ni wínnípin náà yóò fi fẹ̀ si.

Ìmó̩wùnmí fo̩n fèrè o̩wó̩ọ rè̩ tan ni gbogbo agbègbè tí wó̩n wà bè̩rè̩ síí tóbi kọjá kèrémí. Opẹ́lọpé pé wó̩n wa nínú o̩kò̩ọ bàtà tí wó̩n ń pè ní ò̩ge̩re̩re̩. Òun ni kò jẹ́ kí gbogbo àwo̩n òkò eléro tí ń kọjá lára wó̩n s̩e wó̩n lọ́ṣẹ́. Bàbá náà so̩ fún o̩mo̩ rè̩ pé tí kìí bá s̩e ti o̩kò̩ ò̩ge̩re̩re̩ tí àwo̩n wò̩ yìí ni, yóò gba àwo̩n tó ogúnjó̩ láti rìn láti gbàgede wínnípin dé àárin gbùngbùn rè̩ nítorí bí wínnípin náà ti fè̩ tó báyìí. Ó ní s̩ùgbó̩n o̩kò̩ ò̩ge̩re̩re̩ náà yóò gbé àwo̩n ní kíákíá dé àárin gbùngbùn.

Wọ́n gbéra, wó̩n de obiri-iyibiiri tó kángun sí gbàgede atàkókó-àárín wínnípin náà, wó̩n kò lè kọjá nítorí ohun kan ń sáré lójú òpó náà. Bàbá náà tún ki ògèdè tó pa lẹ́ẹ̀kan mọ́lẹ̀, lẹ́yìn èyí sì ni àwọn ohun tí ń sáré náà dúró. Níbí ni wó̩n ti rí i pé eléro tó múra wo̩n ní méjì-méjì ló ń sáré àsáyípo náà. Bí wó̩n ti kọjá obiri-iyibiiri náà ni àwo̩n eléro ọ̀hún tún bè̩rè̩ sí sáré, ènìyàn kò sì lè gba ibè̩ ko̩já mó̩ láìs̩̩e pé àwo̩n eléro náà dúró. Báyìí ni wó̩n s̩e títí tí wó̩n fi lo̩ dé àárin gbùngbùn wínnípin náà, níbẹ̀ ni wó̩n sì ti rí atakókó àárin náà pé àwo̩n è̩yà ohun méjì kan ló dìpò̩ mó̩ ara wo̩n. Ìkín-ní ni e̩lé̩rò̩ (proton), èkejì sì ni alè̩rò̩ (neutron) gé̩gé̩ bí  bàbá rè̩ ti wí fún un. Bàbá rè̩ s̩àlàyé ní kíkún pé:

“Àárin gbùngbùn wínnípin la dé yìí o̩mo̩ mi. Bí o bá wò ó dáadáa, wàá rí i pé àwo̩n ohun kan dìpò̩ níbi tó jẹ́ ẹ̀yà méjì, èkínní tíí s̩e e̩lé̩rò̩ ni agbára rè̩ wà ní è̩rò̩, èyí jé̩ ìdà kejì agbára tó wà nínú eléro tá ti rí síwájú. Èkejì tíí s̩e alè̩rò̩ yìí ló wà nínú gbogbo wínnípin tí e̩lé̩rò̩ rè̩ ju ẹyọkan lo̩ nítorí e̩lé̩rò̩ méjì kò lè lè̩pò̩ mó̩ ara wo̩n. Nítorí naa, wó̩n nílò alè̩rò̩ tí agbára rè̩ wà ní ìwò̩ntun-wò̩nsì èro àti è̩rò̩ (neutral). Eléyìí ni kò níí jẹ́ kí agbára è̩rò̩ tó wà láàárin wínnípin náà pọ̀ ju láti lè dúró s̩ins̩in.”

Ìmó̩wùnmí fèsì pé, “Ìtumò̩ ohun tí è̩ ń wí fún mi látàárò̩ ni wípé, eléro fó̩nká gbàgede, e̩lé̩rò̩ dì pọ̀ sáàárín, alè̩rò̩ ló le̩ e̩lé̩rò̩ àárín pò̩.” Bàbá rè̩ní “O káre láé.” Bàbá náà sì ń bá ò̩rò̩ rè̩ lo̩ wípé:

“Jé̩ kí n wá so̩ fún o̩ nípa àwo̩n as̩ò̩tò̩pé (isotopes). Èròjáyé àbámáyé ni wó̩n lóòótó̩, s̩ùgbó̩n wó̩n s̩e ò̩tò̩ nítorí pé atakókó-àárín wo̩n ní alè̩rò̩ tó pò̩ jù e̩lé̩rò̩ lo̩. Às̩e̩ àbámáyé ni pé iye kan náà ni e̩lé̩rò̩ àti alè̩rò̩ gbó̩dò̩ jé̩ nínú atakókó àárín kí àpapọ gbogbo agbára atakókó àárín lè wà ní è̩rò̩. Bí alè̩rò̩ bá ti wà pò̩ ju e̩lé̩rò̩ lo̩ nínú atakókó àárín, wínnípin náà di as̩ò̩tò̩pé nìye̩n. Ìyẹn ni pé, eléro rẹ̀ pé bí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe ara ọ̀tọ̀ nítorí alẹ̀rọ̀ rẹ̀ lé níye.”

Gbogbo bí ẹ̀kọ́ yìí ti ń lọ ni inú Ìmó̩wùnmí ń dùn nítorí ó yé e yéké-yéké. Ó sì ń fẹ́ láti mọ̀ síi. Bàbáa rẹ̀ ṣàkíyèsí èyí, inú òun pàápàá sì ń dùn. Bàbá náà sọ fún ọmọ rẹ̀ kó  fọn fèrè náà sọ́kan lára àwọn e̩lé̩rò̩ tó dì mọ́ra wọn nínú atakókó àárín. Ìmó̩wùnmí sì ṣe bẹ́ẹ̀, e̩lé̩rò̩ náà bẹ̀rẹ̀ síí wú, ohun mẹ́ta kan sì ń fi agbára jà nínú e̩lé̩rò̩ náà bíi pé wọ́n fẹ́ẹ́ jáde síta nínú ìgbèkùn. Àyàa Ìmó̩wùnmí já!

Iṣẹ́ (Work) 2| Olugbenga Ọlabiyi

Lámèétọ́: Taofeeq Adebayo
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ní báyìí, kí ni à ń pè ní iṣẹ́ nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ tí Físíìsì? Iṣẹ́ jẹ́ àmúlò ipá (force) láti mú ìṣípòpadà (motion) bá nǹkan.  Èyí túmọ̀ sí pé ìsọdipúpọ̀ ìwọ̀n ipá (amount of force) àti ìwọ̀n-ìjìnà (distance) ní ọ̀gangan-àyè (direction) tí ipá ń lọ. Àwọn apẹẹrẹ isẹ́ máa ń farahàn nínú àwọn ìṣe (act) wọ̀nyí:

  1. Ẹni tó ń ti ọmọ-lanke (trolley) láti ibìkan sí ibòmíràn nínú ilé-ìtajà ńlá.
  2. Tí a bá gbé ẹrù láti ilẹ̀ sí orí tábìlì.
  3. Tí a bá gbé ẹrù sórí láti ibìkan dé ibòmíràn.

Àwọn àpẹẹrẹ tí a se yìí ń se àkọ̀júwe iṣẹ́ (work) ní ìbámu pẹ́lù bí àwọn onímọ̀ Físíìsì ṣe gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀.

Níbàyí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìṣẹ (acts) tí a ò le kà sí iṣẹ́, tàbí ká ṣọ wípé àwọn àpẹẹrẹ tí kò sàpèjúwe iṣẹ́. Àwọn nìwọ̀nyí:

  1. Ẹni to gbe apẹrẹ eṣo sori, to wa duro soju kan fun igba pipẹ tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí .

Fún àlàyé yéké, àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ fi yéwa wípé kò sí iṣẹ́ nínú kí a dúró sójú kan pẹ̀lú ẹrù lórí fún ìgbá pípẹ́ tàbí ìgbà díẹ̀.

Níparí, mo ní ìgbàgbọ́ wípé òye ohun tí à ń pè ní iṣẹ́ ti yé wa. Mo sì  nígbàgbọ́ pé a ti rí ìyatọ̀ tó wà láàrin ohun tí gbogbo wa mọ̀ sí iṣẹ́ àti ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ń pè ní iṣẹ́. Ótún di ọjọ́ mì ọjọ́ ire.

Ẹ ṣeé pùpọ́!