Aga agbaṣẹ-ohun (Voice-controlled chair)
Voice-controlled chairVoice-controlled chair (Aga agbaṣẹ-ohun)
Posted by Science in Yoruba on Thursday, November 9, 2023
Voice-controlled chairVoice-controlled chair (Aga agbaṣẹ-ohun)
Posted by Science in Yoruba on Thursday, November 9, 2023
Sìgìdì nínú Mọ́sáláásíSìgìdì nínú Mọ́sáláásí
Posted by Science in Yoruba on Sunday, October 22, 2023
àkàtàm̀pó = slingshotàkàtàm̀pó = slingshot
Posted by Science in Yoruba on Saturday, May 6, 2023
Sìgìdì Atlas tún ti ní àrà tuntun
Posted by Science in Yoruba on Wednesday, January 18, 2023
Ǹjẹ́ yóò wù yín láti fi ẹ̀mí pàṣẹ fún ẹ̀rọ alágbéká yín? (Would you like to control your phone with your mind?) #yoruba #Yorubaland #yorubanimi #science #scienceinyoruba #STEMinindigenouslangs #yoruba #yorubanimi #YorubaNation #yorubaculture #STEM #scienceeducation #sciencecommunication
Posted by Science in Yoruba on Saturday, December 3, 2022
Awọn ohun àtinúdá wo lo ti orilẹ Africa jade latari arun Korona? (Which creative things emerged from Africa as a result of Covid 19)?Awọn ohun àtinúdá wo lo ti orilẹ Africa jade latari arun Korona? (Which creative things emerged from Africa as a result of Covid 19)?
Posted by Science in Yoruba on Wednesday, May 13, 2020
Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Àmì ohùn: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ
Bí èèyàn bá kọ́kọ́ gbọ́ tí a dárúkọ sìgìdì, ohun tí yóò kọ́kọ́ wá sí èèyàn lọ́kàn ni àwọn ère tí àwọn bàbá wa ń lò láti ọjọ́ aláyé ti dáye. Sùgbọ́n níbi tójú là dé yì, a ó rii pé orísirísi àwọn sìgìdì míràn ló ti gbòde kan. Fún ìdí èyí, a ó se ìyàtọ̀ láàrin sìgìdì àbàláyé (effigy) tí àwọn baba wa ń lò fún orísirísi nǹkan àti sìgìdì ìgbàlódé tí a fi ìmọ̀ ẹ̀rọ gbé jáde. Àwọn sìgìdì ìgbàlódé ni ó jẹ wá lógún nínú ẹ̀kọ́ yì.
Kí ni à ń pè ní sìgìdì (ìgbàlódé)? Sìgìdì jẹ́ ẹ̀ro ìgbàlódé èyí tí o lè dá iṣẹ́ tó gba làákàyé ṣe fúnra rẹ̀ láì nílò ìrànlọ́wọ́. Ẹ̀rọ ayárabíàsá (computer) ni á fi máa ń pàṣẹ fún sìgìdì. Èrọ ayárabíàsá yí lè jẹ́ apàṣẹ òkèèrè (remote control) tàbí èyí tí a dé mọ́ sìgìdì lára. A lè ṣe sìgìdì láti fi ara jọ ènìyàn tàbí ẹranko, sùgbọ́n àwọn sìgìdì tó pọ̀jù ni àwọn èyí tí wọ́n gbé kalẹ̀ fún iṣẹ́ ṣíṣe.
Ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ (technology) tí ó ń rí sí bí a ṣe ń hun sìgìdì, bí a ṣe ń tò wọ́n pọ̀, bí a ṣe ń pàṣẹ fún wọn, bí wọn ṣe ǹ lo ìmọ̀ tí a kó sí wọn lórí, bí a ṣe ń mú wọn ṣiṣẹ́ àti bí a ṣe ń fi wọ́n ṣiṣẹ́ ni à ń pè ní ìmọ̀ sìgìdì (robotics). Ohun tí ó jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ yí lógún ni bí a ṣe lè fi sìgìdì rọ́pò ọmọ ẹ̀dá ènìyàn, paapaa julọ ní ibi tó léwu, níbi iṣẹ́, àti bí a ṣe lèè mú àwọn sìgìdì ní ìrìsí ènìyàn, hùwà bí ènìyàn, tàbí kí wọ́n ronú bi ènìyàn.
Sìgìdì lè jẹ́ adáṣẹ́ṣe (autonomous) tí kò nílò àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ènìyàn kí ó tó sisẹ́. Àpẹẹrẹ èyí ni sìgìdì agbálẹ̀ (self-driving vacuum). Sìgìdì tún lè jẹ́ adáṣẹ́ṣe-nílò-àsẹ (semi-autonomous), tí ó lè dá àwọn iṣẹ́ kan ṣe fúnra rẹ̀ sùgbọ́n tó nílò àṣẹ ènìyàn láti ṣe àwọn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan.
Orísirísi sìgìdì (ìgbàlódé) ló wà: sìgìdì adára-bíèèyàn (humanoid robot), sìgìdì afara-jẹranko (animal robot), sìgìdì oníṣẹ́ (task-performing robot), atbbl. Irúfẹ́ àwọn sìgìdì yí ni a ó máa ṣàgbéyẹ̀wò nínú apá kejì.