Àwọn àbùdá òde tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) ní| Ọjọgbọn Lawrence Adewọle (OAU) & A. A. Fabeku

Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Àwọn àbùdá òde (physyical characteristics) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní ni:

(i) Àwọ̀: Àwọ̀ ni ó ń jẹ́ kí á mọ̀ bóyá funfun (white) ni nǹkan kan tàbí gbúre (pink) t̀abí pupa (red) tàbí òfèéfèé (yellow) tàbí omi ọsàn (orange) tàbí sànyán (brown) tàbí dúdú (black) tàbí aró (blue) tàbí eerú (grey) tàbí ẹsẹ̀ àlùkò (purple) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

(ii) Ìtọ́wò: Ìtọ́wò ni ó ń jẹ́ kí á mọ bí nǹkan kan bá dùn tàbí ó korò tàbí ó kan.

(iii) Òórùn: Òórun lè jẹ́ òórùn dídùn, òórùn kíkan, òórùn ìdíbajẹ, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

(iv) Yíyòòrò: Yíyòòrò níí ṣẹ pẹ̀lú pé ṣé nǹkan kan lè yòòrò tàbí kí ó yọ́ kí ó di omíyòòrò (1). 

(v) Líle: Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé ṣé nǹkan tí a ń ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ le, ṣé ó sòro láti tẹ̀, ṣé ó ṣòro láti gé tàbí pé ṣé ó ṣòro láti kán. 

(vi) Ọ̀rìn (dẹńsítì): Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú fífúyẹ́ tàbí wíwúwo nǹkan kan tí a bá fi ojú àlàfo (2) tí nǹkan náà gbà wò ó. Dẹ́ńsítì níí ṣe pẹ̀lú fífúyẹ́ tàbí títóbi nǹkan. A lè rí nǹkan tí ó tóbi tí ó sì fúyẹ́ a sì lè rí nǹkan tí ó kéré tí ó sì wúwo. Tí a bá fi ojú àbùdá báyìí wo nǹkan, ojú dẹ́ńsítì ni a fi ń wo nǹkan náà nìyẹn.

(vii) Ìrára-yí-padà (3): Awọn ohun-ẹ̀dá (substance) kan wà tí ìrísi wọn rọrùn láti yí padà. Bí apẹẹrẹ, alugbinrin (4) kan tí ó rọrùn láti yí padà sí ìrísí mìíràn ni òjé (5). Ìyẹn ni pé tí ìrísí rẹ̀ bá rí pẹlẹbẹ, ó rọrùn láti yí padà sí ìrísí tí ó dà bí okùn, bẹ́ẹ̀ ni, bí irísí rẹ̀ bá dà bí okùn, ó rọrùn láti yí i padà sí pẹlẹbẹ. 

(viii) Ìrísí Ìdì (6): Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé bóyá ohun-ẹ̀dá (substance) kan ti dì tí ó sì ní ìwò (7) kan tàbí òmíràn. 

(ix) Bí ìwò nǹkan ṣe rí nígbà tí ìgbóná ojú ọjọ́ bá bá ti inú ilé dọ́gba (room temperature) (8): Ní àsìkò tí ìgbóná ojú ọjọ bá bá ti inú ilé dọ́gba, ṅ̀jẹ́ a lè sọ pé ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) kan jẹ́ ohun tí ó dì (9) tàbí tí ó jẹ́ olómi(10) tàbí kí ó jẹ òyì/gáàsì (gas) (11). 

(x) Ọ̀gangan Yíyọ́ (12): Ọ̀gangan yíyọ́ yìí ni ibi tí ìgbóná (13) yóò dé tí ohun-ẹ̀dá (substance) yóò fi yọ́ tàbí tí yóò fi yòrò. Bí àpẹẹrẹ, ìgbóná tàbí iná tí yóò mú òrí (shea-butter) yọ́ tàbí tí yóò mú un yòrò kò lè tó èyí tí yóò mu irin yọ́. Ìyẹn ni pé iná tí yóò mú irin yọ́ yóò ju ti òrí lọ. Ọ̀gangan yíyọ́ ni ibi tí nǹkan abara-líle máa ń gbóná dé kí ó tó yọ di olómi. 

(xi) Ọ̀gangan Híhó (14): Ọ̀gangan híhó ni ibi tí iná yóò se nǹkan dé tí nǹkan olómi náà yóò fi máa hó. Ọ̀gangan híhó yìí ni nǹkan olómi ti máa ń di nǹkan aláfẹ́fẹ́, ìyẹn òyì/gáàsì (gas). Bí àpẹẹrẹ, epo máań tètè hó lórí iná ju omi lọ. Èyí fi hàn pé ìgbóná tí yóò mu epo yí padà sí òyì (gáàsì)́ kò lè tó ti omi.

Yàtọ̀ sí ìtọ́wò (taste) àti òórùn (odour) tí wọ́n ṣòro láti ṣe ìgbéléwọ̀n (15) bí wọ́n ṣe tó, gbogbo àwọn àbùdá yòókù ni a lè lò láti fi ìyàtọ̀ hàn láàrin ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) kan sí òmíràn.

Àyànkọ (note)

  1. ‘Solution’ ni a ń pè ní omíyòòrò.
  2. ‘Volume’ ni a ń pè ní àlàfo tí nǹkan gbà.
  3. ‘Malleability’ ni a pè ní ìrára-yí-padà.
  4. Metal’ ni a ń pè ní alugbinrin. Alugbinrin dúró fún ohun tí ó lè dún bí irin bí a bá lù ú.
  5. ‘Lead’ ni a ń pè ní òjé.
  6. ‘Crystalline form’ ni a ń pè ní ìdì.
  7. ‘Shape’ ni a ń pè ní ìwò.
  8. ‘Physical shape at room temperature’ ni eléyìí dúró fún. Ní àsìkò yìí ni a máa ń sọ pé nǹkan kan kò gbóná jù bẹ́ẹ̀ ni kò tutù jù.
  9. ‘Solid’ ni a pè ní ohun tí ó dì. Èyí ni nǹkan tí ó jẹ abara-líle tí ó ṣeé gbámú.
  10.  ‘Liquid’ ni a pè ní olómi.
  11.  Nǹkan aláfẹ́fẹ́ ni gáàsì, bí àpẹẹrẹ, isó, afẹ́fẹ́ tàbí ooru. Gáàsì kò ṣeé gbé dání bẹ́ẹ̀ ni kò ṣeé gbámu. A lè gbé omi (liquid) dáni ṣụgbọ́n kò ṣeé gbámú. A lè gbá nǹkan tí ó ba dì (solid) mú a sì lè gbé e dáni.
  12.  ‘Melting point’ ni a pè ní ọ̀gangan yíyọ.
  13.  ‘Temperature’ ni a pè ní ìgbóná.
  14.  ‘Boiling point’ ni a ń pè ní ọ̀gangan híhó.
  15.  ‘Quantitative evaluation’ ni a  pè ní ìgbéléwọ̀n bí wọ́n ṣe tó. Bí wọ́n ṣe tó yìí lè jẹ́ nípa kíkà tàbí wíwọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, a kò lè ka òórùn bẹ́ẹ̀ ni a kò lè ka bí títọ́ tí a tọ́ nǹkan wò ṣe tó.

Ipá (force)| Olugbenga Ọlabiyi

Lámèétọ́: Lateef Adeleke
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

A ti sọ̀rọ̀ nípa ìsípòpadà (motion), èyí tí ó túmọ̀ sí ìpapòdà láti ibìkan sí ibòmíràn. Ní báyǐ, a fẹ́ ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tó ń fa ìpapòdà nkán láti ibìkan sí ibòmíràn. Kí ni ohun tó ń se okùnfà ìṣípòpadà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fi yé wa pé ipá (force) ni ó ń ṣe okùnfà bí nkan se n lọ síwájú, sẹ́yìn tàbí bí ó se ń  yí ní òbírípo (rotation). Ǹjẹ́ kínni ipá tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yíí?

Ipá ni a lè pè ní ohun tí ó le mù kí ǹkan kúrò ní ojú kan tàbí kí ìyára (velocity) rẹ̀ yí padà. Ipá jẹ́ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ṣòro láti se àlàyé sùngbọ́n ó jẹ́ ọ̀rọ́ tí a máa ńlò ní ìgbà dé ìgbà. Síwájú si, ipá jẹ́ ohun tí ó lágbára tí ó sì le mú kí nkàn tó wà lójúkan sún (move). Bákan náà, ipá le sè àyípadà ètò ọkọ̀ tí ó wà lórí ìrìn. Fún àpẹẹrẹ, abọ́ ìmùkọ wa yíò wà ní ibi tí a fi sí àfi tí a bá lo ipá. Bẹ́ẹ̀ni, ipá le è ṣe àyípadà eré (speed) ọkọ̀ tó ń lọ, yàlá láti yára síi (speed up) tàbí lọ́ra (slow down). Láfikún, ipá le rọ irin, ó le è tẹ agolo, ó le è da ètò nǹkàn rú, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìsọ̀rí méjì ni à le pín ipá sí. Àwọn nì wọ̀nyí:

  1. Ipá ìfarakínra (contact force). Èyi jẹ́ ipá tí ó gbọ́dọ̀ fara kan ohun tí a fẹ́ lò ó fún. Àpẹẹrẹ: fífa (pulling) nǹkan, tìti (pushing) nǹkan, ìfàle líle (tension), ipá ìfaragbora (frictional force), ̣ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
  2. Ipá áìfarakínra (non-conatct force)/ force field (pápá ipá): irú ipá yìí jẹ́ èyí tí kò ní lò kí á fi  ara kan ohun tí a fẹ́ lò ó fún. Èyí ni àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀: ípá òòfà-laáláatóròkè (gravitational force), ipá òòfà (magnetic force), ipá òjíjí (electrical force), àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìráraràn– ì-rí-ara-ràn– (elasticity)| Raji Lateef

Lámèétọ́: Taofeeq Adebayọ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

Ìráraràn– ì-rí-ara-ràn– (elasticity) ni agbára tí ohun abaralíle (solid) kan ni láti padà sí ìrísí (shape) àti ìwọ̀n (size) ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti ṣe àmúkúrò ipá òde (external force) to ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀. Òǹràn (elastic material) ni ohun tí ó lè padà sí ipò àti ìwọ̀n ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti yọ ipá (force) tó mú ìyípadà bá a. 

Bí ipá òde tí a lò lórí nǹkan abarálíle kan (tó ní àbùdá ìráraràn) bá lágbára tó bẹ́ẹ̀ tí àyípadà fi bá ìrísíi rẹ̀, nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò padà sípò bí a bá yọ ipà tí a lò. Èyí ni yóò mú rọ́bà tí a fà pàdà bọ́ sípò rẹ̀ lẹ́yìn tí a jù ú sílẹ̀. Bákan náà ni wáyà tẹ́ẹ́rẹ́ (string wire) yóò nà (stretch) dé ààyè kan lẹ́yìn tí a fi ẹrù sí ẹnu rẹ̀ ṣùgbọ́n yóò padà sí ìrísí rẹ̀ ìpìlẹ̀ bí a bá yọ ẹrù ẹnu rẹ̀ kúrò. 

Àwọn ohun abaralíle tí wọ́n ní agbára láti padà bọ̀ sí ipò àti ìwọ̀n ìpìlẹ̀ wọn lẹ́yìn tí a yọ ipá tó mú àyípadà bá wọn kúrò ni a lè rí bíi ajẹmọ́-ìráraràn (elastic) nígbà tí a óó pe àbùdá tó ń mú irú ìṣesí báyìí wá ní àbùdáa ìráraràn. 

Òfin Hooke (Hooke’s Law)
Bí a bá lo ipá lórí okùn aláàwéfò (spring) tàbí okùn tẹ́ẹ́rẹ́ (string), okùn náà yóò gùn síi níwọ̀n. Bí a bá yọ ipa orí okùn  náà kúrò, yóò padà sí ipò rẹ̀ ìpìlẹ̀. Bí a bá lé ipa orí irú okùn bẹ́ẹ̀ kún ní ìlọ́po méjì, gígùn okùn  náà yóò lé kún ní ìlọ́po méjì. Bí ipá yìí ṣe ń lékún síi ni okùn náà yóò máa gùn síi títí tí okùn náà yóò fi dé òpin ìráraràn (elastic limit). Ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín ipá orí okùn aláàwéfò àti àlékún tó ń bá irú okùn bẹ́ẹ̀ ni òfin Hooke ń ṣàlàyé.

Ìṣípòpadà (motion)| Gbenga Ọlabiyi

Lámèétọ́: Bọde Ọjẹ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Kí ni à ń pè ní ìṣípòpadà (motion)? Ìsípòpadà jẹ́ ìpapòdà láti ibìkan dé ibòmíràn. Fún àpeere, ohun ti ọkọ̀ tó n lọ láti ìlú Èkó ṣí ìlú Ìbàdàn ń se ni pé ó ń pa ipò dà. Fún ìdí èyí, a lè sọ pé ọkọ̀ yi wa lórí  ìṣípòpadà. Irúfẹ́ ìṣípòpadà gbòógì mẹ́rin ni ó wà:

Ìṣípòpadà aláìlétò (random motion): èyí ni ìpapòdà ohun kan láti ibìkan sí ibòmíràn láì ní pàtó ibìkan ti o dorí kọ. Ọ̀nà púpọ̀ la lè fi se àpẹẹre irú ìṣípòpadà yíì. Àkọ́kọ́ ni èèta (particle) èéfín tí ó ń jáde sínu afẹ́fẹ́ tí a bá sun igbó tàbí tí a bá ń dá iná igi. Tí a bá wò ó dáadáa, a ó ríi pé ó sòro fún wa láti mọ pàtó bí àwọn èèta yíì ṣe ń lọ láti bìkan sí ibòmíràn. Ohun tó tún dàbí rẹ̀ ni ìkọlùkọgbà láàrin àwọn èèta omi tí ó ń hó tàbí láàrin àwọn èèta òyì (gas).

Ìṣípòpadà atibìkandébòmíràn (translational motion). A lè fi àpẹẹrẹ ìṣípòpadà yí hàn nípa ọkọ̀-ojúrin tó ń lọ láti ibùdó kan sí òmíràn. Bákan náà, labalábá tó ń fò láti ọ̀dọ̀ òdòdó kan sí òmíràn náà ń se àkọ̀júwe ìṣípòpadà atibìkandébòmíràn.

Ìsípòpadà lááláámìlooloo (oscillatory motion): èyí ni ìṣípòpadà ǹkan tó ń lọ síwájú lọ sẹ́yìn tàbí sí ọ̀tún sí òsì. Ẹrù tí  a so rọ̀ s’ókè tí ó ń lọ sí ọ̀tún lọ sí òsì ń ṣe àkọ̀júwe ìṣípòpadà láámìlooloo.

Irúfẹ́ ìṣípòpadà kẹrin ni ìṣípòpadà olóbìrípo (rotational motion) tí àárín rẹ̀ wà lórí ìlà-àkóso ìyípo (axis of rotation) rẹ̀ . Fún àpẹẹrẹ, ohun tí ilé-ayé (earth) tí ó ń yí ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìlà-àkóso ìyípo rẹ̀ ń ṣe ni ìṣípòpadà olóbìrípo . Àpẹẹrẹ míràn tí a lè tọ́ka sí ni táyà ọkọ́ tó wà lórí ìrìn.

Làkótán, a lérò wípé ẹ ti fi ìmò kún ìmò bẹ́ sì ni ẹti fi òye kún òye. A ó ri pé òye ìṣípòpadà ṣe pàtàkì. Pàápàá jùlọ àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ ń fara hàn nínú ìṣe wa yálà ní ilè tàbí lóko. Sùgbọ́n ká tó lọ, kí gan-an ni ó ń se okùnfà ìṣípòpadà?  A ó máa dáhùn ìbéérè yíi àti ohun tó rọ̀ mọ́ọ nínú apákejì.

Ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) | Samuel Awẹ́lẹ́wà

Kí ni à ń pè ní ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter)?  Ohun tí ò gba ààyè tí ó sí gbé ìwọ̀n ni à ń pè ní ọ̀gbààyègbéwọ̀n.

Fùn àpẹẹrẹ, bí a bá da omi sìnú abọ́ ófífo, omi yóò gba ààyé nínú abọ́ náà. Bàkàn náà, yóò fi kún ìwúwo (weight) abọ́ yìí.  Nítorí náà omi jẹ́ àpẹrẹ ọ̀gbààyègbéwọ̀n.

Ọ̀gbààyègbéwọ̀n máa ń  fi ara hàn ní orísǐrísǐ ipò. Àwọn ipò tí ó wọ́pọ̀ jú ni ipò dídì (solid), ipò sísàn (liquid) àti ipò gáàsì (gas).

Omi nìkan lè fi ara hàn ní ipò mẹ́ẹ̀tẹ̀ẹ̀ta yí. Yìnyín (èyí tíí ṣe omi tí ìgbóná (temperature) rẹ̀ kò tó sẹ́síọ̀sì òdo (0 degree Celsius)) jẹ́ ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní ipò dídì.  Omi tí à ń mu àti èyí tí a fi ń fọ aṣọ jẹ́ ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní ipò ṣíṣàn. Nígbà tí a bá gbe omi sórí iná tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí níí hó, omi abáfẹ́fẹ́rìn (water vapor) tó ń jáde láti inú rẹ jẹ́ ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní ipò gáàsí.

Nínú àpẹẹrẹ yìí, a óò ṣe àkíyèsí pé bí ohunkóhun bá ṣe gbóná tàbí tútù sí, ni yóò sọ ipò ọ̀gbààyègbéwọ́n tí ohun naa yoo wà.

Nípa òǹkọ̀wé

Samuel Awẹlẹwa jẹ́ akẹ́kọ̌gboyè nipa ẹ̀kọ́ Físíìsì ní Fásitì Ibadan.

Lámèétọ́ (Proofreader): Ẹ̀ríìfẹ́ Mofólúwawò