Category: Ìmọ̀ Oníyè (Biology)
Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Biology)| Raji Lateef
Lámèétọ́: Taofeeq Adebayọ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ
Látìgbà láéláé ni àwọn ènìyàn ti máa ń fẹ láti mọ̀ síi nípa àwọn nǹkan tó wà ní àyíkáa wọn, pàápàá àwọn ohun abẹ̀mí. Èyí ló fa ẹ̀kọ́ nípa àwọn ẹ̀dá-oníyè – Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Biology).
Oríkì (Definition) àti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Branches of Biology)
Ara ọ̀rọ̀ Gíríkì méjì ni wọ́n ti ṣẹ̀dá Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè, tí ń ṣe ‘Biology.’ Àkọ́kọ́ ni bios tó túmọ̀ sí ẹ̀mí nígbà tí èkejì tó jẹ́ logos túmọ̀ sí ẹ̀kọ́. Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀mí (life). A lè rí Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀kọ́ nípà àwọn ewé (plants) àti àwọn ẹran (animals).
Ẹ̀ka méjì gbòógì ni Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè ní. Èyí kò sọ pé kò sí àwọn ẹ̀ka mííràn:
- Ẹ̀kọ́ Ẹranko (Zoology): Èyí ni ẹ̀kọ́ nípa gbogbo àwọn ìran ẹran (animals).
- Ẹkọ́ Ewé (Botany) ni ẹ̀kọ́ nípa gbogbo ìran ewé àti igi.
Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ka méjì òkè yìí, àwọn ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè mííràn ló wà ní ìsàlẹ̀ yìí:
- Ẹkọ́lọ́jì (Ecology) ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun abẹ̀mí (living things) – yálà ewé àbí ẹran – àti àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àyíká.
- Mọfọ́lọ́jì (Morphology) ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn àbùdá-òde (external features) àwọn ewé àti ẹran.
- Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́-ìrísí-inú (Anatomy): Ẹ̀yí ni ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè mííràn tó ń ṣàlàyé àwọn ìrísí inú (internal structures) àwọn ewé àti ẹran.
- Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́ran (Genetics): Èyí ni ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì tó jẹ́ ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè tó ń ṣàlàyé nípa àwọn àbùdá àjogúnbá (heredity) àti ìyàtọ̀/àìjọra (variations) àwọn àbùdá bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ẹ̀dá oníyè (living things).
- Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́-Ìṣesí Ẹ̀dá-oníyè (Physiology): Èyí ló ń ṣàlàyé nípa àwọn ìṣesí, ìwúlò tàbí àǹfàní (functions) àwọn ewé àti ẹran (living things).
Orísun: Essential Biology for Senior Secondary School (Ninth Edition)
Orísun àwòrán: https://english-online.org.ua/materials/13468
Jẹjẹrẹ (cancer)| Taofeeq Adebayo
Lámèétọ́: Adedoyin Adegbaye
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Jẹjẹrẹ (cancer) jẹ́ àrùn tí ó máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn hóró (cell) kan nínú ara bá tóbi síi láìní ìjánu, tí wọ́n sì tàn ká lọ sí àwọn ẹ̀yà ara míràn.
Kò sí ibi tí jẹjẹrẹ kò ti lè jẹ yọ nínú àgọ́ ara ọmọ ẹ̀dá ènìyàn. Ẹ jẹ́ ká rántí pé gbogbo ẹ̀yà ara wa ló jẹ́ pé àwọn hóró (cells) ni wọ́n pilẹ̀ wọn. Èyíkèyí nínú àwọn hóró yìí ló lè lùgbàdì jẹjẹrẹ.
Ìdàgbàsókè ọmọ ẹ̀dá ènìyàn nííṣe pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ (process) méjì gbòógì kan: ìdàgbà hóró (cell growth) àti hóró pínpín (cell division). Ìdàgbà hóró ni bí hóró ṣe máa ń tóbi síi tí yóò sì dẹ́kun títóbi tí ó bá ti tóbi dé ààyè kan. Hóró pínpín ni bí hóró ẹyọ kan ṣe máa ń pín di méjì, mẹ́rin àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Fún àpẹẹre, ọmọ kékeré tí ó dàgbà di àgbàlagbà ni o jẹ́ pé àgọ́ ara rẹ̀ ti la àwọn ìgbésẹ̀ méjèèjì yí kọjá: àwọn hóró ara rẹ̀ ti tóbi síì wọ́n sì ti pín síi di púpọ̀, tí ó fi jẹ́ pé orí rẹ̀ tó kéré tẹ́lẹ̀ ti wá di títóbi báyìí.
Àwọn hóró a máa bàjẹ́, bẹ́ẹ̀ wọn a máa kú. Nígbà tí èyi bá sẹlẹ̀, àwọn hóró tuntun á rọ́pò wọn nípaṣè hóró pínpín àti ìdàgbà hóró. Àpẹẹrẹ tí a lè fi ṣe àlàyé èyí ni bí ènìyàn bá ní egbò tí egbò yí sì san. Awọ tuntun tí ó wà lójú àpá náà jẹ́ àwọn hóró tuntun, nígbà tí èépá tí a já kúrò lójú rẹ̀ jẹ́ àwọn hóró tí wọ́n ti di òkú.
Ní ìgbà míràn ìgbésè elétò yí le forisánpọ́n, tí àwọn hóró tó ti bàjẹ́ yóò sì máa tóbi síi tí wọn ó sì máa pín di púpọ̀ bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí wọn ó kú ni. Àwọn hóró bíbàjẹ́ yíì lè sarajọ di ìṣù èèmọ̀ (tumor). Ìṣù èèmọ̀ ni àkójọpọ̀ àwọn ìṣù ara (tissues) tí wọ́n tóbi ju bí ó ṣe yẹ lọ, tí títóbi yí kò sì wúlò fún nǹkankan nínú àgọ́ ara. Irúfẹ́ ìṣù èèmọ̀ méjì ni ó wà: (i) ìṣù èèmọ̀ oní-jẹjẹrẹ (cancerous tumor) tí a tún le pè ní ìṣù èèmọ̀ líle (malignat tumor), àti (ii) ìṣù èèmọ̀ lílẹ (benign tumor) èyí tí kò ní jẹjẹrẹ.
Àwọn ìṣù èèmọ̀ oní-jẹjẹrẹ máa ń tàn ká làti gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ìṣù ara ìtòòsí àti òkèrè nípasẹ̀ ìgbesẹ̀ kan tí a mọ̀ sí ìtànkà jẹjẹrẹ (matastasis). Ọ̀pọ̀ nínú àwọn jẹjẹrẹ ló jẹ́ pé alàdìpọ̀ (solid) ni wọ́n, sùgbọ́n àwọn jẹjẹrẹ inú ẹ̀jẹ̀ bíi àwọn àìsàn ẹ̀jẹ̀ (leukemias) kìí sábà jẹ́ aládìpọ̀.
Àwọn ìṣù èèmọ̀ lílẹ kìí sábà tàn ká tàbí gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ìṣù ara ìtòòsí tàbí ti òkèèrè. Àwọn ìṣù èèmọ̀ lílẹ kìí sábà gbérí padà bí wọ́n bá gé wọn, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ìṣù èèmọ̀ líle le gbérí padà lẹ́yìn tí wọ́n bá gé wọn. Ìṣù èèmọ̀ lílẹ leè tóbi gan-an, wọ́n leè yọrí sí àwọn àmì àìsàn tó léwu, wọ́n sì le dá ẹ̀mí ènìyàn légbodò. Àpẹẹrẹ èyí ni ìṣù èèmọ̀ lílẹ inú ọpọlọ.
Ní àkótán, àwọn hóró tí wọ́n ti bàjẹ́ tó yẹ kí wọn ó kú sùgbọ́n tí wọn ò kú tí wọn ń tóbi síi tí wọ́n sì ń pín di púpọ̀ síi ni wọn ń fa jẹjẹrẹ.
Òsùbà: cancer.gov
Hóró pínpín (Cell Division)| Adedoyinsọla Adegbaye& Raji Lateef
Lámèétọ́: Taofeeq Adebayo
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Hóró ni oun kan tó kéré jùlọ nínú ẹ̀dá oníyè. Òun náà sì ni ìpìlẹ̀ ìṣẹ̀mí ẹ̀dá oníyè. Bákan náà, a lè rí hóró bíi irinṣẹ́ tí àwọn àmúṣe-iṣẹ́ (active) ẹ̀dá-oníyè gbáralé, tí ó sì ń mú ìlọsíwájú bá ìgbé ayé irú àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ nítorí pé òun ni ọ̀pá-òdiwọ̀n tó kéré jùlọ fún ìṣẹ̀mí àwọn ẹ̀dá-oníyè.
Hóró pínpín
Èyí ni ètò bí hóró ìpìlẹ̀ (parent cell) ṣe ń pín sí hóró tuntun (daughter cells) méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ètò pínpín hóró máa ń wáyé nínú ètò ìyírapadà hóró (cell cycle). Nínú àwọn ẹ̀dá-oníyè abiwọ̀ kókó (eukaryotes), oríṣìí àwọn ẹ̀yà hóró pínpín méjì ni ó wà. Àwọn ni hóró pínpín oní-ìjọra (vegetative division/mitosis) àti hóró pínpín aláìní-ìjọra (reproductive division/meiosis). Hóró pínpín oní-ìjọra (vegetative division/mitosis) máa ń wáyé nígbà tí kò bá sí ìyàtọ̀ láàárín hóró tuntun àti hóró ìpìlẹ̀ nípa àwọn àbùdá ajẹmọ́ran tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀dá oníyè, hóró pínpín oní-ìjọra jẹ́ ètò ìyírapadà hóró (cell cycle) tó ń ṣe okùnfà kí kókó (nuclei) àwọn ẹ̀dà okùn-ìran (chromosomes) pín sí méjì. Irúu pínpín báyìí á fún wan ní àwọn hóró alábùdá ajẹmọ́ran kan náà (genetically identical cells) tí iye okùn-ìran ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò sì yàtọ̀ sí ara. Ṣaájú hóró pínpín oníjọra (mitosis) ni Ìpele S (S Stage of interphase). Ìpele yìí níí ṣe pẹ̀lú dídá (synthesis) àwọn kẹ́míkà atọ́ka ìrandíran (DNA). Ìfihàn Aṣòpinyà Èròjà Ajẹmọ́ran (telophase) àti Ètò Pínpín Aláfojúrí (Cytokinesis) ló máa ń tèlé Ìpele S. Ìfihàn Aṣòpinyà Èròjà Ajẹmọ́ran (telophase) ni ìpele tí àwọn èròjà ajẹmọ́ran (genetic materials) inú èso kókó hóró (nucleolus) ti máa ń di pínpín sínú àwọn hóró tuntun ajọra (identical daughter cells) láti ara hóró ìpìlẹ̀ (parent cells). Ètò Pínpín Aláfojúrí (Cytokinesis) ló máa ń ṣe àfihàn pínpín oje hóró (cytoplasm), ẹ̀ya hóró kékèré (organelle) àti ìwọ-hóró (cell membrane) hóró ìpìlẹ̀ (parent cell) sínú àwọn hóró tuntun (daughter cells) méjì. Èyí máa ń wáyé pẹ̀lú pínpín kókó hóró, ní èyí tí a óò wá rí hóró tuntun méjì, tí àkónú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò sì ní yàtọ̀ sí ara wọn.
Ẹ̀dá Oníyè Aláìníwọ̀ Hóró (Prokaryotes) máa ń tèlé ìlànà hóró pínpín oníjọra (vegetative cell division) tí a mọ̀ sí hóró pínpín alójúlódì (binary fission). Ìlànà yìí ló máa ń mú kí pínpín àwọn èròjà ajẹmọ́ran (genetic materias) sínú hóró tuntun méjì tí ọ̀kan ò níí ju èkejì wáyé. Yàtọ̀ sí ìlànà pínpín hóró alájúlódì (binary fission) tó máa ń wáyé nínú àwọn Ẹ̀dá Oníyè Aláìníwọ̀ Hóró (Prokaryotes), a ṣàkíyèsí ìlànà mííràn tí a mọ̀ sí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ (budding).
Fún àwọn ẹ̀dá oníyè oníhóró kan (unicellular organism), (bí àpẹrẹ Àmóẹbà (Amoeba)), pínpín hóró kan túmọ̀ sí ètò bíbí (reproduction) – èyí túmọ̀ sí pé ìṣẹ̀dá odidi ẹ̀dá oníyè kan ló wáyé. Nígbà mííràn hóró pínpín oníjọra (mitotic cell division) lè ṣẹ̀dá ẹ̀dá oníyè tuntun nínú ẹ̀dá oníyè oníhóró púpọ̀ (multicellular organism), bí àpẹrẹ, igi oko tó hù ní ìlànà gígé (cutting). Hóró pínpín oníjọra (mitotic cell division) máa ran ẹ̀dá oníyè oníbìí ìbálòpọ̀ (sexually reproducing organism) lówọ́ láti wáyé látara ọlẹ̀ oníhóró kan (tí òun fúnra rẹ̀ wáyé látara hóró pínpín aláìní-ìjọra – meiosis – tó wáyé látara ètò ìbísí takọtabo – gametes).
Hóró pínpín ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè, àtúnse àti dídá hóró tuntun nínú àgọ́ ara. Ohun tó jẹ́ àfojúsùn pàtàkì nínú ètò hóró pínpín ni ìdáàbò bò apó ẹyọ-ìran (genome) inú hóró ìpìlẹ̀ (original or parent cell). Kí hóró tóó di pínpín, a gbọ́dọ̀ ṣe ẹ̀dà ìmọ̀ ajẹmọ́ apó ẹyọ-ìran (genomic information) tí ó wà ní ìpamọ́ nínú okùn ìran àtipé ẹ̀dà náà gbódọ̀ jẹ́ pínpín lókan-ò-ju-ọ̀kan láàárín àwọn hóró tuntun tó wáyé.
Ẹ̀jẹ̀ (blood)| Olubayọde Martins Afuyẹ
Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ
Ki a tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí, kí ni ẹ̀jẹ̀? Ẹ̀jẹ̀ jẹ́ àkójọpọ̀ oje ẹ̀jẹ̀ (plasma) àti àwọn hóró (cell) tó ń yíká nínu ara. Bákan náà, a lè rí ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi èròjà tó ń gbé àwọn ohun aṣaralóore (nutrients) kiri ara eranko ọlọ́pǎ-ẹ̀yin (vertebrate animals). Nínú mùdùnmúdùn (bone marrow) ni ìpèsè hóró ẹ̀jẹ̀ ti máa ń wáyé. Nínú ihò egungun ni a ti máa ń bá mùdùn-múdùn eegun. Mùdùn-múdùn eegun yìí ni àwọn ẹ̀yà hóró ìpìlẹ̀ (stem cell) tí wọ́n kápá làti yíra padà sí hóró ẹ̀jẹ̀ pupa (red blood cells), hóró ẹ̀jẹ̀ funfun (white blood cells) àti oje ẹ̀jẹ̀ (plasma).
Àwọn ohun tó kóra jọ di ẹ̀jẹ̀ jẹ́ àwọn ohun méjì pàtàkì. Àwọn ni: èròjà olómi (liquid item) àti èròjà líle (solid item):
- Èròjà Olómi inú ẹ̀jẹ̀ là ń pè ní oje ẹ̀jẹ̀. Bí a bá ṣe àtúpalẹ̀ àkóónú ẹ̀jẹ̀, ìdá tí oje ẹ̀jẹ̀ kó, tó ìdá àádọ́ta sì ọgọ́ta (50-60%). Àwọn ohun tí a óò bá nínú oje ẹ̀jẹ̀ fúnra rẹ̀ ni omi, iyọ̀ àti purotéèni (protein).
- Èròjà líle inú ẹ̀jẹ̀ pín sí mẹta. Àwọn ni: hóró ẹ̀jẹ̀ pupa (red blood cells), hóró ẹ̀jẹ̀ funfun (white blood cells) àti hóró amẹ́jẹ̀dì (platelets).
Hóró-amẹ́jẹ̀dì (Platelet): Èyí jẹ́ hóró tó kéré, tí kò sì ní àwọ̀ (colourless). Òun ni ó máa ń ran ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ lati dìpọ̀ (to clot) nígbàtí a bá farapa, tí ó sì lójú (wound). Ó kápá láti dènà tàbí dẹkùn ẹ̀jẹ̀ tó ń jáde lójú ọgbẹ́. Hóró-amẹ́jẹ̀dì tó wà nínú máìkíròlítà (microliter) ẹ̀jẹ̀ kan yóò tó ọ̀kẹ́ méje àti ẹgbàá sí ogun ọ̀kẹ́ lé méjì àti ẹgbàá (150,000 – 450,000).
Hóró ẹ̀jẹ̀ Pupa tàbí ẹ̀rítírósáìtì (Red blood cells/erythrocytes): Hóró ẹ̀jẹ̀ pupa yìí náà ni a mọ̀ sí ẹ̀rítírósáìtì (erythrocytes – ìtumọ̀ èyí kò yàtọ̀ sí tí hóró ẹ̀jẹ̀ pupa). Ọ̀rọ̀ Gíríkì (Greek) ní, tí ìpìlẹ̀ ìṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ “ẹ̀rítíròsì” (erythros) tó dúró fún pupa àti “sáìtì” (cyte) tó dúró fún hóró. Hóró ẹ̀jẹ̀ pupa ló gbajúmọ̀ jù nínú àwọn hóró ẹ̀jẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì fún gbígbé òyì-iná/ọ́ksíjìnì (oxygen) láti inú ẹ̀dọ̀fóró sì èya ara gbogbo, ó sì tún jẹ́ ohun ayí-àwọ̀padà (pigment) tí ó fún ẹ̀jẹ̀ ní àwọ pupa rẹ̀. Bákan náà, ó ní purotéènì táà ń pè ní agbọ́ksíjìn-kánú-ẹ̀jẹ̀ (hemoglobin). Hóró ẹ̀jẹ̀ pupa ni hóró tó pọ̀ jù nínú àgọ́ ara ọmọ-ènìyàn, a sì máa tó bí ogún sì ọgbọ̀n tírílíọ̀nù (20-30 trillion) nínú ara. Ẹ̀jẹ̀ ara ọkùnrin máa ń pò ju ti obìnrin lọ. Hóró ẹ̀jẹ̀ pupa kọ̀ọ̀kan a máa lo tó oṣù mẹ́rin kí ó tó di aláìsí. Ojoójúmọ́ ni ara máa pèsè hóró ẹ̀jẹ̀ pupa tuntun láti rọ́pò àwọn tí o tí ku tàbí àwọn tí ara pàdánù.
Hóró ẹ̀jẹ̀ funfun tàbí lúkósáìtì (white blood cells/leukocytes): Àwọn hóró ẹ̀jẹ̀ funfun jẹ́ àwọn hóró tó ń ṣiṣẹ́ fún ètò-àjẹsára (immune system) tó ń dáàbò bo ara níbi àwọn àìsan alákóràn (infectious diseases) àti àwọn ohun àjèjì (foreign invader). Orisun àwọn hóró ẹ̀jẹ̀ funfun ni mùdùn-múdùn inú eegun. Nínú gbogbo ẹ̀yà ara pátá ni a ti lè rí hóró ẹ̀jẹ̀ funfun. Èyí túmọ̀ sí pé a óò ma ṣalábàpádèé wọn nínú ètò ẹ̀jẹ̀ (blood system) àti ètò omi-ara (lymphatic system).
Hóró (cell)| Raji Lateef & Taofeeq Adebayọ
Lámèétọ́: Adedoyin Adegbaye
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ
Nínú ìmọ̀ ẹ̀dá oníyè (biology), hóró (cell) ni ẹyọ tó kéré jù tó le dá sẹ̀mí tó sì jẹ́ pé òhun ló pilẹ̀ gbogbo ẹ̀dá alààyè. Ẹ̀yà mẹ̀ta gbòógì ni hóró ní: kókó (nucleus), oje hóró (cytoplasm), ati iwọ̀ọ hóró (cell membrane).
Iwọ̀ọ hóró ni ó yí hóró po, òun ni ó sì n darí àwọn èròjà tó ń wọ́lé sinú hóró àti àwọn èyí tó ń jáde láti inú rẹ. Kókó jẹ́ ẹ̀yà pàtàkì ti ó wa nínú hóró tí ó jẹ́ pé nínú rẹ̀ ni a ti máa ń rí púpọ̀ nínú DNA (kẹ́míkà atọ́ka ìrandíràn) hóro. Inú kókó ni èso kókó (nucleolus) wà, inú rẹ̀ náà sì ni ìpèsè (production) púpọ̀ nínú àwọn RNA (áásììdì òjíṣẹ́) ti máa ń wáyé. Oje hóró ni èrojà olómi tí ó wà nínú hóró.
Ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ẹ̀yà hóró míràn ló wà nínú oje hóró tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Díẹ̀ nínú wọn ni: èròjà okùn-ìran (chromatin), hihò kókó (nucleopore), abbl. Inú oje hóró ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsesí kẹ́míkà (chemical process) ti má ń wáyé. Nínú oje hóró náà ni ipèsè púpọ̀ ninu àwọn purotéènì ti máa ń ṣẹlẹ̀.
Ẹ̀mí (life) ni a lè fi ṣàlàyé àwọn àbùdá tì àwọn ẹ̀dá-oníyè (living organism) ní tàbí iṣẹ́ tí wọn kápá làti ṣe, bíi ìrìn, íjẹ-ímu, ìbímọ, ìdàgbàsókè, abbl. Gbogbo àwọn ẹ̀dá-oníyè ni wọ́n ní agbára láti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, yálà wọ́n jẹ́ ẹ̀dá-oníyè oníhóró-kan (unicellular organism) tàbí ẹ̀dá-oníyè oníhórópúpọ̀ (multicellular organism). Hóró ni ọ̀pá-òdiwọ̀n tó kéré jùlọ tí a lè fi ṣe òdiwọ̀n ẹ̀mí tí ẹ̀dá-oníyè n lò fún àgbéjáde àwọn àbùdáa wọn. Èyí túmọ̀ sí pé tí a bá ṣe àtúpalẹ̀ àkóónú ẹ̀dá-oníyè oníhórópúpọ̀, hóró ni a óò bá nípele tó kéré jùlọ:
Ohun tí àtẹ yìí ń ṣàlàyé ni pé àkójọpọ̀ hóró ni a óò bá nínú ìṣù-ara, nígbà tí a óò bá àkójọpọ̀ ìṣù-ara nínú ẹ̀yà-ara. Àtòpọ̀ ẹ̀yà ara ni yóò fún wa ni ètò-ara (system), tí a óò sì wáá bá oríṣìíríṣìí ètò ara nínú odidi ẹ̀da oníyè. Àwọn hóró tí ara ọmọ ẹ̀dá ènìyàn kó sìnú ju ọgbọ̀n trílíọ̀ọ̀nù (trillion) lọ.
Àwọn ẹ̀yà hóró
- iwọ̀ hóró: cell membrane
- apààrè {a-pa-ààrè(killer of strange item)}: lysosome
- oje hóró: cytoplasm
- kókó: nucleus
- iwọ̀ kókó: nuclear membrane
- afọ̀dọ̀ti hóró vacuole
- apèsè-agbára mitochondrion
- apèsè puroteènì ribosome
- èso kókó nucleoid
- oje hóró-òun-kókó protoplasm
Àti eranko àti ewéko ni hóró wọn ni àwọn ẹ̀yà 1-10, ṣùgbọ́n nínú ti ewéko nì a óò ti má ṣe alábàápàdé ẹ̀yà 11 àti 12:
- odii hóró cell wall
- asọ̀mọ́lẹ̀dikẹ́míka chloroplast