Ìṣípòpadà (motion)| Gbenga Ọlabiyi
Lámèétọ́: Bọde Ọjẹ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Kí ni à ń pè ní ìṣípòpadà (motion)? Ìsípòpadà jẹ́ ìpapòdà láti ibìkan dé ibòmíràn. Fún àpeere, ohun ti ọkọ̀ tó n lọ láti ìlú Èkó ṣí ìlú Ìbàdàn ń se ni pé ó ń pa ipò dà. Fún ìdí èyí, a lè sọ pé ọkọ̀ yi wa lórí ìṣípòpadà. Irúfẹ́ ìṣípòpadà gbòógì mẹ́rin ni ó wà:
Ìṣípòpadà aláìlétò (random motion): èyí ni ìpapòdà ohun kan láti ibìkan sí ibòmíràn láì ní pàtó ibìkan ti o dorí kọ. Ọ̀nà púpọ̀ la lè fi se àpẹẹre irú ìṣípòpadà yíì. Àkọ́kọ́ ni èèta (particle) èéfín tí ó ń jáde sínu afẹ́fẹ́ tí a bá sun igbó tàbí tí a bá ń dá iná igi. Tí a bá wò ó dáadáa, a ó ríi pé ó sòro fún wa láti mọ pàtó bí àwọn èèta yíì ṣe ń lọ láti bìkan sí ibòmíràn. Ohun tó tún dàbí rẹ̀ ni ìkọlùkọgbà láàrin àwọn èèta omi tí ó ń hó tàbí láàrin àwọn èèta òyì (gas).
Ìṣípòpadà atibìkandébòmíràn (translational motion). A lè fi àpẹẹrẹ ìṣípòpadà yí hàn nípa ọkọ̀-ojúrin tó ń lọ láti ibùdó kan sí òmíràn. Bákan náà, labalábá tó ń fò láti ọ̀dọ̀ òdòdó kan sí òmíràn náà ń se àkọ̀júwe ìṣípòpadà atibìkandébòmíràn.
Ìsípòpadà lááláámìlooloo (oscillatory motion): èyí ni ìṣípòpadà ǹkan tó ń lọ síwájú lọ sẹ́yìn tàbí sí ọ̀tún sí òsì. Ẹrù tí a so rọ̀ s’ókè tí ó ń lọ sí ọ̀tún lọ sí òsì ń ṣe àkọ̀júwe ìṣípòpadà láámìlooloo.
Irúfẹ́ ìṣípòpadà kẹrin ni ìṣípòpadà olóbìrípo (rotational motion) tí àárín rẹ̀ wà lórí ìlà-àkóso ìyípo (axis of rotation) rẹ̀ . Fún àpẹẹrẹ, ohun tí ilé-ayé (earth) tí ó ń yí ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìlà-àkóso ìyípo rẹ̀ ń ṣe ni ìṣípòpadà olóbìrípo . Àpẹẹrẹ míràn tí a lè tọ́ka sí ni táyà ọkọ́ tó wà lórí ìrìn.
Làkótán, a lérò wípé ẹ ti fi ìmò kún ìmò bẹ́ sì ni ẹti fi òye kún òye. A ó ri pé òye ìṣípòpadà ṣe pàtàkì. Pàápàá jùlọ àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ ń fara hàn nínú ìṣe wa yálà ní ilè tàbí lóko. Sùgbọ́n ká tó lọ, kí gan-an ni ó ń se okùnfà ìṣípòpadà? A ó máa dáhùn ìbéérè yíi àti ohun tó rọ̀ mọ́ọ nínú apákejì.
Ẹ kú iṣẹ́ ọpọlọ sà!
Òṣùbà ràbàǹdẹ̀ fun yín.
Great job. E ku ise takuntakun
This is indeed beautiful.
Our mother tongue will be saved from going into into extinction.
Emu ise opoloo inu mi dun lati ri iru nkan yi
Ọjọ́ ti pẹ́ tí mo ti ń retí irú ǹkan báyìí. Bóyá tí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wa bá ń fi èdè abínibí kọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, bóyá á túbọ̀ yé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa