Category: Ìmọ̀ Kẹ́míkà (Chemistry)
Mọnamọna ninu ọpọlọ (Electricity in the brain)
We are all electricity generators (Ẹrọ amunawa ni gbogbo wa)We are all electricity generators (Ẹrọ amunawa ni gbogbo wa)
Posted by Science in Yoruba on Tuesday, August 8, 2023
Àtẹ èròjà aláìlábùlà (The periodic table of elements)
Àtẹ èròjà aláìlábùlàYoruba description of the periodic table of elements #Yoruba #Yorubanimi
Posted by Science in Yoruba on Sunday, September 13, 2020
Ihun atọmu (structure of an atom)
Ìhun átọ́ọ̀mùThe structure of an atom explained in Yoruba
Posted by Science in Yoruba on Sunday, August 16, 2020
Ki ni atọmu (What is an atom)?
Yoruba description of atom (átọ́ọ̀mù)Yoruba description of atom (átọ́ọ̀mù)
Posted by Science in Yoruba on Sunday, July 19, 2020
Kẹ́mísírì| Ọjọgbọn Lawrence Adewọle (OAU) & A. A. Fabeku
Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ
Kẹ́mísírì (1) jẹ́ ẹ̀ka sáyẹ́ǹsì àrígbéwọ̀n (physical science) (2) tí ó ṣeé dán wò (2) tí ó jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ tí ó ń kọ́ ni nípa èròjà (4), ìhun (5) àti ìyídà (6) ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) tí ó wà ní àgbáálá ayé (7). Kẹ́míìsírì tún máa ń kọ́ ni nípa òfin tí ó ṣe àlàyé ìyídà yìí. Kẹ́mísírì níí ṣe pẹ̀lú àtòpọ̀ (combination) tàbí àsèìtakora (reaction) èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (substance). Ìyẹn ni bí a ṣe lè to èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n kan pọ̀ mọ́ òmíràn tàbí bí a ṣe lè fi èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n kan ta ko òmíràn.
Kí ni ọ̀gbààyègbéwọ̀n?
Ọ̀gbààyègbéwọ̀n (8) jẹ́ ohunkóhun tí ó ní ìwọ̀n-okun (9) tí ó sì gba áyè. Ohun tí a pè ní ọ̀gbààyègbéwọ̀n yìí lè tóbí, ó sì lè kéré. A lè fi ojú rí i (tí ó bá tóbi tó nǹkan tí a lè fojú rí tàbí kí a má fi ojú rí i tí ó bá kéré ju ohun ti a lè fi ojú wa lásán rí tí ó jẹ́ pé a ó nílò awò amóhuntóbi (‘magnifying glass’) kí á tó lè rí i). Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé bí ó ti wù kí ó kéré tó, ohunkóhun tí ó bá ti ní ìwọ̀n-okun tí ó sì gba àyè ni a mọ̀ sí ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter). Ìwọ̀n-okun àti ìwúwo (10) bá ara wọn tan ṣùgbọ́n, síbẹ̀, wọ́n yàtọ̀ sí ara wọn gédégédé. Àwọn àpẹẹrẹ ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni afẹ́fẹ́, omi, òkúta, igi, ohun ọ̀gbìn, ẹranko, ènìyàn, alùgbinrin (11) àti gbogbo ohun tí ó yí wa ká, yálà, èyí tí a lè fi ojú rí tàbí èyí tí a kò lè fi ojú lásán rí.
Kí ni Ìwọ̀n?
Iwọ̀n ni iye (12) ọ̀gbààyègbéwọ̀n (13) tí ó wà nínú èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (14). Ìwọ̀n ni àbùdá tí nǹkan ní tí ó fi máa ń fẹ́ wà lóju kan láìpara dà tàbí kí ó máa lọ láìdúró.
Kí ni ìwúwo?
Ìwúwo (‘weight’) ni ipa tí òòfa lááláátóròkè (gravity) ní lórí ìwọ̀n-okun (mass) (15).
Àbùdá ọ̀gbààyègbéwọ̀n
A lè dá ọ̀gbààyègbéwọ̀n (‘matter’) mọ̀ nípa wíwo oríṣiríṣi àbùdá (16) tí ó ní. Oríṣi àbùdá méjì ni ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni. Èkíní ni àbùdá òde (17) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni. Èkejì ni àbùdá inú (18) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní. Àbùdá òde ti ọ̀gbààyègbéwọ̀n jẹ́ èyí tí a lè rí, tí a lè fi ọwọ́ kàn tàbí tí a lè wọ̀n nípa lílo ojú wa, etí wa, imú wa, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé a máa nílò àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ẹ̀rọ kí á tó lè lo ọ̀kan tàbí òmíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara láti fi mọ àwọn àbùdá wọ̀nyí (19) .
Àyànkọ (note)
- Orúkọ mìíràn fún kẹ́mísírì ni ìmọ̀ èrójà ẹ̀dá. Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, a máa ń pe nǹkan kan ní ‘substance’. ‘Substance’ yìí ni a lè pè ní ohun tí ó níí ṣẹ pẹ̀lú ọ̀gbààyègbéwọ̀n tí ó jẹ́ pé a lè fojú rí i tàbí kí a fọwọ́ kàn àn tàbí kí ó ṣeé wọ̀n. Tí a bá ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ohun tí a pè ní ‘substance’ yìí àti ọ̀nà tí a fi lè tò ó mọ́ irú rẹ̀ mìíràn (combine) tàbí kí ohun tí a pè ní ‘substance’ yìí torí nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí irú rẹ̀ mìíràn (act) ṣe nǹkan kan (react), irú ẹ̀kọ́ yìí ni a ń pè ní Kẹ́mísírì.
- À̀rígbéwọ̀n ni ohun tí a lè fojú rí tàbí tí a lè fọwọ ́kàn tàbí tí a lè wọ̀n.
- Bí a bá dán nǹkan wò ni a fi máa ń mọ bí nǹkan náà ṣe rí gan-an.
- Bí a bá fọ́ nǹkan kan sí wẹ́wẹ́, àwọn nǹkan tí a lè bá nínú nǹkan náà ni èròjà nǹkan náà
- Ìhun ni bí a ṣe to nǹkan pọ̀̀. Ètò tí a lè sọ pé nǹkan kan ní ni a ń pè ní ìhun nǹkan náà.
- Ìyídà máa ń yí ìrísí tàbí àbùdá nǹkan padà, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kí nǹkan náà lè dára sí i
- Àgbáálá ayé dúró fún àwọn ìràwọ, ayé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
- Ẹ̀dá ni a ń pè ní ‘matter’ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ̀dá máa ń ní èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (‘substance’).
- Nìnù Kẹ́mísírì, ohun tí a ń pè ní ìwọ̀n-okun ni ‘mass’. Tí ó bá jẹ́ inú Físíìsì ni, ìṣù tàbí títóbi nǹkan ni a ń pè ni ‘mass’.
- ‘Weight’ yìí ni a ń pè ní ìtẹ̀wọ̀n nínú ẹ̀kọ́ Físíìsì. Lára oríkì (definition) tí a lè fún ìtẹ̀wọ̀n yìí ni (i) ipá (force) tí ó dorí kọ ilẹ̀ tí nǹkan kan ní nítorí títóbi (mass) rẹ̀ (ii) ìmúrasaré (acceleration) nítorí ìfàlọsílẹ̀ (pull) ilẹ̀ ayé.
- Àwọn ohun tí a bá lù tí ó bá ń dún bí irin ni a ń pè ní alugbinrin.
- Iye dúró fún bí nǹkan kan ṣe pọ̀ tó.
- Ọ̀gbààyègbéwọ̀n dúró fún ‘matter’.
- Èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n dúró fún ‘substance’.
- Ayé ní òǹfà tí ó fi ń fa àwọn ohun tí ó wà ní inú rẹ̀ wá sí orí ilẹ̀ tàbí kí ó fa nǹkan kan mọ́ra. Èyí ni a ń pè ní ipá òòfa lááláátóròkè (‘force of gravity’).
- Àbùdá ni ìrísí tí nǹkan kan ní. Èyí ni àwọn ohun tí a ń wọ mọ́ ǹnkan lára tí ó fi ƴàtọ̀ sí nǹkan mìíràn.
- ‘Physical properties’ ni àwọn àbùdá òde tí ẹ̀dá ní.
- ‘Chemical properties’ ni àwọn àbùdá inú tí ẹ̀dá ni.
- Bí àpẹẹrẹ, bí nǹkan kan bá kéré jù, a lè nílò awò amóhuntóbi (magnifying glass) kí a tó lè rí i dáadáa.
Èròjà aláìlábùla (pure elements)
Ki ni awọn onimọ ijinlẹ n pe ni èròjà alailabula (pure element)? Bi a ba wo ayika, orisirisi nnkan ni a o rii ti o yi wa ka. Bi a ṣe n ri awọn nnkan didi ni a o maa rii awọn nkan olomi. Bi a ṣe n ri awọn nkan to jẹ gaasi ni a o màa ri awọn ohun miran ti wọn o fara jọ gaasi rara. Bi a ba waa ro arojinlẹ, o ye ki a le beere awọn ibeere kan Kilo de ti igi fi jẹ ohun lile ti omi si jẹ ohun to n san? Kilo de ti awọn ohun elepo fi maa n fa jọọ ti eyi ko si ri bẹẹ fun omi? Kilo de ti awọn igi fi le dagba sii ti okuta ko si le tobi ju bi o ṣe wa lọ? Ki a to le dahun gbogbo awọn ibeere yi, a ni lati mọ itumọ ohun ti wọn n pe ni eroja alailabula.
Eroja alailabula ni eroja kẹmika ti o jẹ pe ohun nikan ni o pilẹ ohun kan. Ẹ jẹ ki a fi góòlù ṣe apejuwe. Ti a ba fọ góòlù si wẹwẹ debi kẹmika to kere ju ninu góòlù, kẹmika góòlù naa ni a o ba nibẹ. Eyi tumọ si pe góòlù jẹ eroja alailabula. Eyi ko ri bẹẹ fun omi. Ti a ba fọ omi si wẹwẹ debi awọn kẹmika to kere ju ti o jẹ pe awọn ni wọn pilẹ omi, eroja alailabula meji ọtọọtọ Ọksijin (oxygen) ati Haidirojiini (hydrogen) ni a o ba nibẹ. Eyi tumọ si pe omi kii ṣe eroja alailabula. Akanpọ eroja (compound) nii ṣe.
Orisirisi eroja alailabula ni awọn onimọ ijinlẹ ti ṣe awari wọn. Apẹẹrẹ awọn eroja alailabula yi ni wúra (gold), baba (copper), fadaka (silver) imi ọjọ (sulphur), ọksijin (oxygen) ati haidrojin (hydrogen).
Ọgọfa-din-meji (118) ni awọn eroja alailabula ti a ti ṣe awari wọn. Ninu eyi, mẹrinlelaadọrun (94) ni o jẹ pe wọn jẹ eroja alailabula aitọwọda, nigba ti awọn eroja alailabula mẹrinlelogun (24) yoku jẹ atọwọda. Gbogbo awọn eroja alailabula yi ni awọn onimọ ijinlẹ to sinu atẹ eroja alailabula (Periodic table).
Ohun gbogbo ti o wa ni orilẹ aye pata lo jẹ pe awọn eroja alailabula yi ni o pilẹ wọn. Fun apẹẹrẹ bi a ba fọ ọmọ ẹda eniyan si wẹwẹ debi awọn kẹmika to kere julọ, a o rii pe ọksijin, kabọn (carbon), haidirojin (hydrogen) ati naitrojin (nitogen) ni o ko mẹrindinlọgọrun ninu ida ọgọrun (96%) gbogbo ohun ti a n pe ni ara ọmọ eda eniyan.
Awọn eroja alailabula yi ati bi a ṣe kan wọn pọ ni o n sọ bi nnkan ti wọn pilẹ rẹ yoo ṣe ri. Fun itẹsiwaju lori ẹkọ yii, ẹ jẹ ka pade lori apa keji