Àtẹ̀jáde

Ìgbà Àìtíìsítàn 2: Ìgba àwọn dáínósọ̀ àti ìgbà tí ọmọ ẹ̀dá ènìyà dé orí ilẹ́

When did modern humans start living on Earth? Here is what we know (Igba wo ni awa eeyan ode oni bẹrẹ si nii gbe orilẹ aye? Eyi ni ohun ti a mọ)

When did modern humans start living on Earth? Here is what we know (Igba wo ni awa eeyan ode oni bẹrẹ si nii gbe orilẹ aye? Eyi ni ohun ti a mọ)

Posted by Science in Yoruba on Sunday, September 24, 2023

Ayé Nẹ́ptúùn (Neptune)| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́: Alabi Sherif
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ó yá ẹ dáhun ìbéèrè yìí: ayé wo ló jìnà jù sí òòrùn nínú sàkáání òòrùn wa? Ẹ tún wá nǹkan fìdí lé bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú apá kẹtàlá yìí lórí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Níbáyìí, ẹ bá wa kálọ sí orí ayé tí a mọ́ orúkọ rẹ̀ sí Nẹ́ptúùn.

Nẹ́ptúùn ni ó súnmọ́ òòrùn sìkẹjọ. Nẹ́ptúùn yí kan náà ni ó jìnà sí òòrùn jù nínú gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn (solar system) wa. Òótọ́ ni pé àwọn abara òfuurufú (celestial body) kan wà bíi Plútò tí àwọn tún jìnà ju Nẹ́ptúùn lọ, sùgbọ́n àwọn abara òfuurufú yíì kíì ṣe ayé; aràrá ayé (dwarf planet) ni wọ́n.

Ìgbóná-tutù (temperature) tó wọ́pọ̀ jù lórí Nẹ́ptúùn jẹ́ Sẹ́síọ́sì igba-lé-mẹ́wàá òdì (-210 Celsius). Wákàtí mẹ̀rìndínlógún lórílẹ̀ ayé wa yí ni ọjọ́ kan lórí Nẹ́ptúùn. A ó ka bíi ọdún márùn-dín-láàdọ́sǎn (165) lórílẹ̀ ayé kí ọdún kan ó tó pé lórí rẹ̀.

Bí a bá fi ojú àyípo (circumference) wòó, Nẹ́ptúùn ló tóbi sìkẹrin nínú sàkáání òòrùn wa. Yóò tó mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ilé-ayé tí à ń gbé orí rẹ̀ yí tí yóò parapọ̀ kí á tó leè mú Nẹ́ptúùn ẹyọ kan jáde.

Gẹ́gẹ́ bíi Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn jẹ́ ayé ràbàtà oní-yìnyín (ice giant). Àwọn ayé ràbàtà (giants) mẹ́rin ló wà ní sàkáání òòrùn wa. Àwọn ayé ràbàtà yi ni Júpítà, Sátọ̀n, Yúránọ́ọ̀sì àti Nẹ́ptúùn. Nẹ́ptúùn ló kéré jù láàrin àwọn ayé wọ̀nyìí.

Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn kò ní orílẹ̀ kankan tí ènìyàn le dúró lé lórí. Alagbalúgbú òyì (gas) ló yí orí rẹ̀ po. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn náa ní àwọn òrùka. Àwọn òrùka mẹ́fà gbòógì ló pagbo yíi ká.

Bákanáà, mẹ́rìnlá ní àwọn òsùpá tí ìwádǐ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ń rábàbà yípo Nẹ́ptúùn.

Gẹ́gẹ́ bí Mẹ́kíúrì, Àgùàlà, Júpítà, Sátọ̀n àti Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn kò leè jẹ́ ibùgbé fún àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wọ́n.

Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Biology)| Raji Lateef

Lámèétọ́: Taofeeq Adebayọ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

Látìgbà láéláé ni àwọn ènìyàn ti máa ń fẹ láti mọ̀ síi nípa àwọn nǹkan tó wà ní àyíkáa wọn, pàápàá àwọn ohun abẹ̀mí. Èyí ló fa ẹ̀kọ́ nípa àwọn ẹ̀dá-oníyè – Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Biology).

Oríkì (Definition) àti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè (Branches of Biology)

Ara ọ̀rọ̀ Gíríkì méjì ni wọ́n ti ṣẹ̀dá Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè, tí ń ṣe ‘Biology.’ Àkọ́kọ́ ni bios tó túmọ̀ sí ẹ̀mí nígbà tí èkejì tó jẹ́ logos túmọ̀ sí ẹ̀kọ́. Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀mí (life). A lè rí Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀kọ́ nípà àwọn ewé (plants) àti àwọn ẹran (animals).

Ẹ̀ka méjì gbòógì ni Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè ní. Èyí kò sọ pé kò sí àwọn ẹ̀ka mííràn:

  1. Ẹ̀kọ́ Ẹranko (Zoology): Èyí ni ẹ̀kọ́ nípa gbogbo àwọn ìran ẹran (animals).
  2. Ẹkọ́ Ewé (Botany) ni ẹ̀kọ́ nípa gbogbo ìran ewé àti igi. 

Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ka méjì òkè yìí, àwọn ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè mííràn ló wà ní ìsàlẹ̀ yìí: 

  1. Ẹkọ́lọ́jì (Ecology) ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun abẹ̀mí (living things) – yálà ewé àbí ẹran – àti àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àyíká.
  2. Mọfọ́lọ́jì (Morphology) ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn àbùdá-òde (external features) àwọn ewé àti ẹran.
  3. Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́-ìrísí-inú (Anatomy): Ẹ̀yí ni ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè mííràn tó ń ṣàlàyé àwọn ìrísí inú (internal structures) àwọn ewé àti ẹran.
  4. Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́ran (Genetics): Èyí ni ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì tó jẹ́ ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá-oníyè tó ń ṣàlàyé nípa àwọn àbùdá àjogúnbá (heredity) àti ìyàtọ̀/àìjọra (variations) àwọn àbùdá bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ẹ̀dá oníyè (living things).
  5.  Ẹ̀kọ́ Ajẹmọ́-Ìṣesí Ẹ̀dá-oníyè (Physiology): Èyí ló ń ṣàlàyé nípa àwọn ìṣesí, ìwúlò tàbí àǹfàní (functions) àwọn ewé àti ẹran (living things).

Orísun: Essential Biology for Senior Secondary School (Ninth Edition)
Orísun àwòrán: https://english-online.org.ua/materials/13468

Apata yiyọ (lava) ni Grindavik, Iceland

Hot lava currently erupting in Grindavik. Will this town be safe? (Apata yiyọ n tujade lọwọ bayii ni Grindavik. Njẹ ilu yi yoo bọ ninu ewu?)

Hot lava currently erupting in Grindavik. Will this town be safe? (Apata yiyọ n tujade lọwọ bayii ni Grindavik. Njẹ ilu yi yoo bọ ninu ewu?)

Posted by Science in Yoruba on Thursday, December 21, 2023

Nibo ni mọnamọna ati ara ti n wa?

Where do thunder and lightning come from? Let's go find out on this airplane. (Nibo ni mọnmọna ati ara ti n wa? Ẹ jẹ ka lọ wo ibi ti wọn ti wa ninu baalu yi)

Where do thunder and lightning come from? Let's go find out on this airplane. (Nibo ni mọnamọna ati ara ti n wa? Ẹ jẹ ka lọ wo ibi ti wọn ti wa ninu baalu yi)

Posted by Science in Yoruba on Sunday, November 26, 2023

Ilẹ lanu ni orilẹ-ede Iceland: Ilẹ riri 1700 sẹlẹ laarin wakati 24

Land split open in Iceland; 1700 earthquakes in 24 hours

Land split open in Iceland; 1700 earthquakes in 24 hours (Ilẹ lanu ni orilẹ-ede Iceland; Ilẹ riri 1700 sẹlẹ laarin wakati 24)

Posted by Science in Yoruba on Saturday, November 18, 2023

Mọnamọna alaisunra (Static electricity)

Here is a quick science trick you can do right now (Eyi ni idan imọ ijinlẹ kan ti ẹ le se papa niisin niisin)

Here is a quick science trick you can do right now (Eyi ni idan imọ ijinlẹ kan ti ẹ le se papa niisin niisin) #staticelectricity #yoruba #science #scienceinyoruba

Posted by Science in Yoruba on Sunday, November 12, 2023