Jẹjẹrẹ (cancer)| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́: Adedoyin Adegbaye
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Jẹjẹrẹ (cancer) jẹ́ àrùn tí ó máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn hóró (cell) kan nínú ara bá tóbi síi láìní ìjánu, tí wọ́n sì tàn ká lọ sí àwọn ẹ̀yà ara míràn.

Kò sí ibi tí jẹjẹrẹ kò ti lè jẹ yọ nínú àgọ́ ara ọmọ ẹ̀dá ènìyàn.  Ẹ jẹ́ ká rántí pé gbogbo ẹ̀yà ara wa ló jẹ́ pé àwọn hóró (cells) ni wọ́n pilẹ̀ wọn. Èyíkèyí nínú àwọn hóró yìí ló lè lùgbàdì jẹjẹrẹ. 

Ìdàgbàsókè ọmọ ẹ̀dá ènìyàn nííṣe pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ (process) méjì gbòógì kan: ìdàgbà hóró (cell growth) àti hóró pínpín (cell division). Ìdàgbà hóró ni bí hóró ṣe máa ń tóbi síi tí yóò sì dẹ́kun títóbi tí ó bá ti tóbi dé ààyè kan.  Hóró pínpín ni bí hóró ẹyọ kan ṣe máa ń pín di méjì, mẹ́rin àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Fún àpẹẹre, ọmọ kékeré tí ó dàgbà di àgbàlagbà ni o jẹ́ pé àgọ́ ara rẹ̀ ti la àwọn ìgbésẹ̀ méjèèjì yí kọjá: àwọn hóró ara rẹ̀ ti tóbi síì wọ́n sì ti pín síi di púpọ̀, tí ó fi jẹ́ pé orí rẹ̀ tó kéré tẹ́lẹ̀ ti wá di títóbi báyìí. 

Àwọn hóró a máa bàjẹ́, bẹ́ẹ̀ wọn a máa kú. Nígbà tí èyi bá sẹlẹ̀, àwọn hóró tuntun á rọ́pò wọn nípaṣè hóró pínpín àti ìdàgbà hóró. Àpẹẹrẹ tí a lè fi ṣe àlàyé èyí ni bí ènìyàn bá ní egbò tí egbò yí sì san. Awọ tuntun tí ó wà lójú àpá náà jẹ́ àwọn hóró tuntun, nígbà tí èépá tí a já kúrò lójú rẹ̀ jẹ́ àwọn hóró tí wọ́n ti di òkú.

Ní ìgbà míràn ìgbésè elétò yí le forisánpọ́n, tí àwọn hóró tó ti bàjẹ́ yóò sì máa tóbi síi tí wọn ó sì máa pín di púpọ̀ bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí wọn ó kú ni. Àwọn hóró bíbàjẹ́ yíì lè sarajọ di ìṣù èèmọ̀ (tumor). Ìṣù èèmọ̀ ni àkójọpọ̀ àwọn ìṣù ara (tissues) tí wọ́n tóbi ju bí ó ṣe yẹ lọ, tí títóbi yí kò sì wúlò fún nǹkankan nínú àgọ́ ara. Irúfẹ́ ìṣù èèmọ̀ méjì ni ó wà: (i) ìṣù èèmọ̀ oní-jẹjẹrẹ (cancerous tumor) tí a tún le pè ní ìṣù èèmọ̀ líle (malignat tumor), àti (ii) ìṣù èèmọ̀ lílẹ (benign tumor) èyí tí kò ní jẹjẹrẹ.

Àwọn ìṣù èèmọ̀ oní-jẹjẹrẹ máa ń tàn ká làti gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ìṣù ara ìtòòsí  àti òkèrè nípasẹ̀ ìgbesẹ̀ kan tí a mọ̀ sí  ìtànkà jẹjẹrẹ (matastasis). Ọ̀pọ̀ nínú àwọn jẹjẹrẹ ló jẹ́ pé alàdìpọ̀ (solid) ni wọ́n, sùgbọ́n àwọn jẹjẹrẹ inú ẹ̀jẹ̀ bíi àwọn àìsàn ẹ̀jẹ̀ (leukemias) kìí sábà jẹ́ aládìpọ̀.

Àwọn ìṣù èèmọ̀ lílẹ kìí sábà tàn ká tàbí gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ìṣù ara ìtòòsí tàbí ti òkèèrè. Àwọn ìṣù èèmọ̀ lílẹ kìí sábà gbérí padà bí wọ́n bá gé wọn, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ìṣù èèmọ̀ líle le gbérí padà lẹ́yìn tí wọ́n bá gé wọn. Ìṣù èèmọ̀ lílẹ  leè tóbi gan-an, wọ́n leè yọrí sí àwọn àmì àìsàn tó léwu, wọ́n sì le dá ẹ̀mí ènìyàn légbodò. Àpẹẹrẹ èyí ni ìṣù èèmọ̀ lílẹ inú ọpọlọ.

Ní àkótán, àwọn hóró tí wọ́n ti bàjẹ́ tó yẹ kí wọn ó kú sùgbọ́n tí wọn ò kú tí wọn ń tóbi síi tí wọ́n sì ń pín di púpọ̀ síi ni wọn ń fa jẹjẹrẹ.

Òsùbà: cancer.gov

Atakóró wo̩nú wínní-wínní 2| Fààbú sáyẹ́ǹsì láti ọwọ́ Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀

Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Atakóró wọnú wínní-wínní 1

Ìdájí o̩jó̩ àbámé̩ta kan ni bàbá náà jí o̩mo̩ àti ìyá pé ìrìn-àjò náà yá, tòun taṣọ òògùn lọ́rùn. S̩ùgbó̩n kí wó̩n tóó lọ, bàbá ní kí o̩mo̩débìrin náà da àbá mé̩ta tó fẹ́ kó wá sí ìmúṣẹ nípa ti è̩kó̩ rè̩. Ìmó̩wùnmí so̩ fún bàbá rè̩ wípé:

  1. Mo fé̩é̩ ní è̩kúnré̩ré̩ ìmò̩ nípa ìmò̩ ìjìnlè̩ àti ibi tí ó ti bè̩rè̩
  2. Mo fé̩é̩ ní è̩kúnré̩ré̩ ìmò̩ nípa ìmò̩-è̩ro̩ pè̩lú
  3. Mo sì fé̩é̩ ní è̩kúnré̩ré̩ ìmò̩ nípa ìs̩irò.

Wó̩n rìn ìrìn-àjò lo̩ síbì kan tí o̩mo̩débìrin náà kò mò̩ ní ìlú Afìmò̩s̩o̩rò̩, wó̩n wo̩ inú ilé ńlá kan tí a kó̩ àkó̩lé ńlá kan sí wí pé “ÌKÒ̩LÉ ÒFEEFÈÉ.” Ìmó̩wùnmí bi bàbá rè̩ ohun tí ń jẹ́ bé̩è̩, s̩ùgbó̩n bàbá rè̩ kò fesi. Kàkà kò fèsì, ń ṣe ló fún un ní ìyè̩fun kan wípé kó fi sẹ́nu, s̩ùgbó̩n kò fún ìyá rè̩. Ó ní ìyáa rè̩ ni yóò fa àwo̩n méjéèjí yọ jáde padà níbi tí àwo̩n ń lọ. Ó ní àwo̩n fẹ́ẹ́ takóró wọ inú wínní-wínní títí lo̩ dé inú wínnípin. Ìmó̩wùnmí tún béèrè pe kí ní ń jẹ́ wínnípin, bàbáa rè̩ si dá a lóhùn wípé ibi tí wínní-wínní pín sí ló ń jẹ́ bé̩è̩, òògùn tí òun sì fún o̩mo̩ náà ni yóò jẹ́ kí àwo̩n wa lóòyè̩ nítorí pé àwo̩n yóò di kékeré jọjọ láti lè ríbi tí wínní-wínní pin sí. Kíákíá ni bàbáa rè̩ ti gbé a̩s̩o̩ gbérí-o̩de̩ kan wò̩ só̩rùn, ó sì bèèrè bí o̩mo̩ náà mú ìwé àti ìkọ̀wé rè̩ ló̩wó̩. S̩ùgbó̩n è̩rù wà lójú o̩mo̩dé náà bí ó tilè̩ jé̩ pé ó ti mú ohun ìkò̩wé rè̩ ló̩wó̩. Ó so mó̩ bàbáa rè̩. Bí wó̩n ti ń s̩e èyí ni ìyáa rè̩ tún bú sè̩rín. Wó̩n kó sínú o̩kò̩ ojú-omi kékeré kan tí wó̩n s̩e bíi bàtà aláwò̩tán, ìyáa rè̩ sì tì wó̩n sójú òpó kan tó ń yọ́ bíi pé wó̩n da ilá sóríi rẹ̀. Bàbá ní orúko̩ o̩kò̩ tí àwo̩n wọ̀ yìí ni wó̩n ń pè ní ò̩ge̩re̩re̩. Bí wó̩n ti ń yò̩ lo̩ sí ìsàlè̩ ihò ńlá náà ni wó̩n ń yípo lọ. 

Inú ihò náà dàbíi ihò ìgò tí ènìyàn lè rí òdì-kejì. Bí Ìmó̩wùnmí sì ti wò ó lórí bí ìyáa rè̩ tí wó̩n fi sé̩yìn s̩e bè̩rè̩ síí tóbi. Ó sì ríi pé àwòrán ìyá náà ń yí ihò ìgò náà ká. Tìyanu-tìyanu ló fi so̩ èyí fún bàbáa rè̩, bàbá náà si so̩ fún un pé èyí ló ń ṣe àfihàn bí àwo̩n ṣe ń di kékeré síi nínú ìrìn-àjò àwo̩n. Nígbà ti o̩mo̩ náà kò fi ní rí ìyáa rè̩ mọ́, èékánná àtàm̀pàkò ìyá náà ti tóbi to orí pápá ibi tí wó̩n ti ń ṣeré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá, àmì dúdú kan bíi àmì-ọ̀run wà lórí èékánná ìyáa rè̩, ọ̀gangan ibẹ̀ sì ni o̩kò̩ náà forí lé, bó ti ń yò̩ lo̩ sí ìsàlè̩. O tóbi títí, afiiwimu!

Lójijì ni òkùnkùn s̩ú, ó sì dàbí pé o̩kò̩ wó̩n wà nínú òkùnkùn, wó̩n sì ń lọ sísàlè̩ pè̩lú eré burúkú. O̩mo̩débìrin náà di mó̩ bàbáa rè̩ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á gidigidi. Nígbà tí ó yá, iná funfun kan tàn ní ọ̀kánkán, nísàlè̩ ló̩hùn-ún, o̩kò̩ ò̩ge̩re̩re̩ náà sì ń gbé wó̩n lo̩ síbi tí iná náà wà. Bí wó̩n ti ń súnmọ́ ọn ni iná náà ń pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Bí wó̩n ti ń súnmó̩ àwo̩n iná yìí ni ìtànsán-ìmọ́lẹ̀ wó̩n kò mọ́lẹ̀ púpò̩ mọ́. Nígbà tí wó̩n yóò fi dé ìwọ̀n òkìtì mélòó kan sí ìdíi rè̩, gbogbo wó̩n rí win-in-rin bí e̩yin onígo amọ́roro, ò̩kò̩ò̩kan wó̩n sì ti tóbi tó odidi ìkòkò ńlá kan. Ìrínìmò̩ bè̩rè̩ ò̩rò̩ rè̩ wípé:  “Ibi a wí la dé, o̩mo̩ò̩ mi. Wá mú gègé rè̩, kí o sì máa ko̩ ò̩rò̩ mi sílẹ̀.” Ọmo̩ náà s̩e bí bàbáa rè̩ ti wí. Ó bè̩rè̩ si ko̩ ò̩rò̩ bàbáa rè̩ sílè̩, bákan náà ló ń ya àwòrán ohun tó rí.

Láti ìgbàa láéláé ni àwo̩n oníròrí ti lérò rè̩ lọ́kan pé ó ní ààyè kan tí ohun kan le kéré mọ; ìyẹn nibi tí wínní-wínní pin sí. S̩ùgbó̩n sá ní ti ìmò̩-ìjìnlè̩, John Dalton ló kó̩kó̩ wòye pé níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àwo̩n èròjà-àbámáyé (1) kan wà ti wó̩n máa ń yapa lo̩ dara pò̩ mó̩ èròjà-àbámáyé mííràn láti di èròjà ọ̀tun, ó ní láti jẹ́ pé ibi tí wínní wínní pin sí ni èyí ti bè̩rè̩ síí ṣẹlẹ̀.

Jẹ́ ki n sa´re´ sọ fun o nipa èròjà-àbámáyé tí a óò gé kúrú sí èròjáyé láti ìsinsinyi lọ. Èròjáyé ni èròjà ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé àti ìsálálú. Láyé àtijọ́, mẹ́rín-in péré ni àwọn ènìyàn gbà pé èyí jẹ́: iná, omi, ẹ̀rùpẹ̀ àti afẹ́fẹ́. Ṣùgbọ́n ṣáá, ní ayé òde òní, ìmò-ìjìnlẹ̀ ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé a tún lè pín àwọn mẹ́rín-in yìí sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Nítorí náà, èròjáyé mọ́kàndílọ́ọ́gọ́fà (118) ni a ti fidí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó wà, yálà nípa àbámáyé ni tàbí àto̩wó̩dá.”

Ìmọ́wùnmí sọ fún bàbáa rẹ̀ pẹ́, “Lọ́rọ̀ kan, èròjà tó já ayé ni èròjáyé, ìtumò èyí sì ni pé kìkìdá wọn ló di ohun gbogbo tí a lè rí nínú ayé.”  Bàbáa rẹ̀ ní, “bẹ́ẹ̀ ni. O káre láé ọmọọ̀ mi.” Ó sì tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pẹ́:

“Ní òde gbangba níbi tí a tí ń bọ̀, ǹ jé̩ iná lè darapò̩ mó̩ ilè̩ tàbí omi bi? O ó rí i pé èyí kò ṣeé ṣe. S̩ùgbó̩n bí wínní-wínní iná bá darapọ̀ mọ́ wínní-wínní até̩gùn kan, ohun kan lè ti ìdí èyí jáde tí yóò jẹ́ èròjà tuntun. Dalton so̩ pé ibi tí wínní-wínní pin sí ni ibi tí ó ti ṣeé ṣe fún díẹ̀ lára èròjà-àbámáyé kan láti darapò mó̩ èròjà-àbámáyé mííràn láti di ohun mííràn. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti jẹ́ ibì yìí ni ohun kan ti máa ń darapò̩ mó̩ ohun mííràn, ó gbà pé ibí ni wínní-wínní pin sí ní ìbámu pè̩lú èrò-orí àwo̩n oníròrí ilè̩ Greek àti India nígbà láéláé. Erwin Wilhelm Muller o̩mo̩ ilè̩ Germany ló sì kó̩kó̩ rí wínnípin yìí pè̩lú ìrànwó̩ è̩ro̩-awohun-wínní-wínní.Dalton jánà níbìkan, ó sì tún kùnà níbìkan. Àwo̩n ohun tí ó ń wò wò̩nyí ló para pò̩ di oun gbogbo tí ń bẹ nílé ayé àti ní gbogbo inú ò̩salalu lóòtọ́,  nínú ìparapò̩, ìyapa àti ìdarapò̩ mó̩ òmíràn ni àwo̩n èròjà-àbámáyé orísìíríṣìí ti s̩e wáyé lóòtọ́. È̩̩wè̩, ìgbọ̀nrìrì àti ìdúró-lójúkan àwo̩n wínnípin yìí ló ń fa gbogbo ipo tí ohun gbogbo wà, bíi ìgbóná, ìtutù, ìdìpò̩, ìlekoko, ìs̩àn-bí-omi àt iìjé̩-afé̩fé̩. Fun àpe̩e̩re̩, bí a bá gbé omi sórí iná, tí a sì dáná sí I lábẹ́, ìgbọ̀nrìrì wínnípin iná yóò kóbá wínnípin irin tí a fi ṣe ìkòkò, tí àwo̩n náà yóò sì bè̩rè̩ síí gbọ̀n, ìgbọ̀nrìrì wó̩n yí kan náà yóò kó ba ìgbọ̀nrìrì wínnípin omi, àwo̩n náà yóò sì bè̩rè̩ síí gbọ̀n. Jẹ́ kí á wá sún mọ́ ọ̀kan nínú àwo̩n wínnípin yìí láti mò̩ bóyá níbi ni wínní-wínní pin sí lóòótó.”

Bi Ìrínìmò̩ ti so̩ bé̩è̩ tán, ó yọ fèrè kan jáde, ó fún o̩mo̩débìrin rè̩ pé kó fun fèèrè náà sí èyíkèyí tí ó bá wù ú nínú àwo̩n wínnípin náà. Ó ní èyíkèyí tó bá fọn fèrè náà sí yóò wú débi pé àwo̩n yóò lè wọ inú rè̩ lo̩.

Nígbà tí wó̩n sún mọ òkan nínú àwo̩n wò̩nyí tí Ìmó̩wùnmí sì fọn fèrè náà si, ló tóó wá mò̩ pé ohun tí ó dúró bíi èèpo ẹyin tàbí ikaraun wò̩nyí kìí s̩e ìgò tàbí ìkaraun rárá, àwo̩n ohun kan tí ènìyàn kò leè rí nítorí erée wo̩n pò̩ púpò̩ bi wó̩n ti ń jù ràn-ìn ràn-ìn yí ká àárin gbùngbùn kan náà. Kí bàbá náà tó sọ̀rọ̀ ni o̩mo̩ rè̩ ti sọ̀rọ̀ pé “Baba mi, wínní-pin yìí dà bíi ido-ayíbiri kékeré kan tí kókó àárín yìí dúró nípò òòrùn, tí àwo̩n ohun tí ń jù ràìn-ràìn wò̩nyí sì dà bíi àwo̩n ayíbiiri nínú ìdo-ayíbiiri-móòrùn (2), lára èyí táyé tiwa yìí wà.”  Inú bàbá rè̩ dùn fún àkíyèsí yìí, ó sì bè̩rè̩ ò̩rò̩ rè̩, Ìrínìmò̩ wípé:

“Níbí ni Dalton kò ti jánà wípé ibi tí wínní-wínní parí sí ni èyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun ti wó̩n ní lọ́kàn nígbà tí wó̩n bá so̩ pé wínnípin ni a timò̩ báyìí pé ó pín sí yẹ́leyẹ̀lẹ, síbẹ̀ ,àwo̩n onímò̩-ìjìnlè̩ sì toro mó̩ ò̩rò̩ ìperí náà. Bóyá nítorí pé gbogbo ohun tó tún kéré kọjá wínnípin, tí wínnípin dì síkùn jẹ́ oníbáméjì (3) ni. Ìtumọ̀ èyí ni pé kò ì sí ìfẹnukò pé kóró (4) ni wọ́n ni tàbí ìbìlà (5).” Wínnípin nìkan ni ìfenukò wà pé kóró ni.

Inú Ìmó̩wùnmí dùn, ara rè̩ sì yá gágá láti mò̩ si nípa wínnípin. Ó ko̩ ọ́ sínú ìwé rè̩ wípé “ibi tí wínní-wínní pin sí ní ti kóró, là á pè ní wínnípin. Bi wínní-wínní bá fi le pín lé̩yìn èyí, oníbáméjì ló dì síkùn.

Àyànkọ

  1. èròjà-àbámáyé-èròjáyé – elements (chemistry)
  2. ìdo-ayíbiiri-móòrùn – solar system (for example, our solar system)
  3. Oníbáméjì–èyí tí ó wà ní ìwà méjì; kóró àtiìbìlà. (particle and wave)
  4. Kóró–particle
  5. Ìbìlà–wave

Iṣẹ́ (Work) 1| Olugbenga Ọlabiyi

Lámèétọ́: Taofeeq Adebayo
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ǹjẹ́ kíni àwọn ònimọ̀-ìjìnlẹ̀ ń pè ní iṣẹ́ (work)? Àwọn ìṣe (acts) àwa ẹ̀dá wo ni ó  ń ṣe àpẹẹrẹ iṣẹ́? Bákan náà, àwọn ìṣe wo ni a ò leè kà sí iṣẹ́? A ó màá fi ìdáhùn sí àwọn ìbéèré wọ̀nyí nínú ẹ̀kọ́ yìí. Nítorínà, ẹ fì ìkàlẹ̀ síi; ẹ mú kálámù àti ìwé yín láti se àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ bá rí gbámú.

Kí a tó wọ inú tìfuntẹ̀dọ̀ ohun tí àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ń pè ní iṣẹ́ (nínú apá 2), ẹ jẹ́ kí á kọ́kọ́ ṣọ̀rọ̀ lérèfé nípa ǹkan tí gbogbo wa mọ̀ sí iṣẹ́ (work). Iṣẹ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ kan gbòógì tí a máa ń lò ní gbogbo ìgbà. Orísirísi ọ̀nà ni ẹ̀dá ènìyàn ń gbà lo ọ̀rọ̀ tí à ń pè ní “iṣẹ̀”. Fún àpẹẹrẹ:

  1. Mò ń lọ síbi iṣẹ̀
  2. Tádé ń sisẹ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ girama ní agbègbè mi
  3. Ọlá ṣe àlàyé bí ẹ̀rọ amúsẹ́yá (machine) rẹ̀ se ń se isẹ́
  4. Ọlá ṣe iṣẹ́ ọpọlọ

Pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí, a ó ripé ọ̀rọ̀ tí à ń pè ní iṣẹ́ (work) máa ń farahàn nínú ìse wa, pàápàá jùlọ a máa ń se àmúlò iṣẹ́ nípa agbára káká (physical strength) tàbí ọgbọ́n àtinúdá (mental effort).

Níbìyí la o fi àgbàdá ètò rọ̀ sí lòní. A ó máa tẹ̀sìwájú nínú apá 2.

Ẹ seun púpọ̀!

Àwọn àbùdá òde tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) ní| Ọjọgbọn Lawrence Adewọle (OAU) & A. A. Fabeku

Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Àwọn àbùdá òde (physyical characteristics) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní ni:

(i) Àwọ̀: Àwọ̀ ni ó ń jẹ́ kí á mọ̀ bóyá funfun (white) ni nǹkan kan tàbí gbúre (pink) t̀abí pupa (red) tàbí òfèéfèé (yellow) tàbí omi ọsàn (orange) tàbí sànyán (brown) tàbí dúdú (black) tàbí aró (blue) tàbí eerú (grey) tàbí ẹsẹ̀ àlùkò (purple) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

(ii) Ìtọ́wò: Ìtọ́wò ni ó ń jẹ́ kí á mọ bí nǹkan kan bá dùn tàbí ó korò tàbí ó kan.

(iii) Òórùn: Òórun lè jẹ́ òórùn dídùn, òórùn kíkan, òórùn ìdíbajẹ, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

(iv) Yíyòòrò: Yíyòòrò níí ṣẹ pẹ̀lú pé ṣé nǹkan kan lè yòòrò tàbí kí ó yọ́ kí ó di omíyòòrò (1). 

(v) Líle: Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé ṣé nǹkan tí a ń ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ le, ṣé ó sòro láti tẹ̀, ṣé ó ṣòro láti gé tàbí pé ṣé ó ṣòro láti kán. 

(vi) Ọ̀rìn (dẹńsítì): Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú fífúyẹ́ tàbí wíwúwo nǹkan kan tí a bá fi ojú àlàfo (2) tí nǹkan náà gbà wò ó. Dẹ́ńsítì níí ṣe pẹ̀lú fífúyẹ́ tàbí títóbi nǹkan. A lè rí nǹkan tí ó tóbi tí ó sì fúyẹ́ a sì lè rí nǹkan tí ó kéré tí ó sì wúwo. Tí a bá fi ojú àbùdá báyìí wo nǹkan, ojú dẹ́ńsítì ni a fi ń wo nǹkan náà nìyẹn.

(vii) Ìrára-yí-padà (3): Awọn ohun-ẹ̀dá (substance) kan wà tí ìrísi wọn rọrùn láti yí padà. Bí apẹẹrẹ, alugbinrin (4) kan tí ó rọrùn láti yí padà sí ìrísí mìíràn ni òjé (5). Ìyẹn ni pé tí ìrísí rẹ̀ bá rí pẹlẹbẹ, ó rọrùn láti yí padà sí ìrísí tí ó dà bí okùn, bẹ́ẹ̀ ni, bí irísí rẹ̀ bá dà bí okùn, ó rọrùn láti yí i padà sí pẹlẹbẹ. 

(viii) Ìrísí Ìdì (6): Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé bóyá ohun-ẹ̀dá (substance) kan ti dì tí ó sì ní ìwò (7) kan tàbí òmíràn. 

(ix) Bí ìwò nǹkan ṣe rí nígbà tí ìgbóná ojú ọjọ́ bá bá ti inú ilé dọ́gba (room temperature) (8): Ní àsìkò tí ìgbóná ojú ọjọ bá bá ti inú ilé dọ́gba, ṅ̀jẹ́ a lè sọ pé ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) kan jẹ́ ohun tí ó dì (9) tàbí tí ó jẹ́ olómi(10) tàbí kí ó jẹ òyì/gáàsì (gas) (11). 

(x) Ọ̀gangan Yíyọ́ (12): Ọ̀gangan yíyọ́ yìí ni ibi tí ìgbóná (13) yóò dé tí ohun-ẹ̀dá (substance) yóò fi yọ́ tàbí tí yóò fi yòrò. Bí àpẹẹrẹ, ìgbóná tàbí iná tí yóò mú òrí (shea-butter) yọ́ tàbí tí yóò mú un yòrò kò lè tó èyí tí yóò mu irin yọ́. Ìyẹn ni pé iná tí yóò mú irin yọ́ yóò ju ti òrí lọ. Ọ̀gangan yíyọ́ ni ibi tí nǹkan abara-líle máa ń gbóná dé kí ó tó yọ di olómi. 

(xi) Ọ̀gangan Híhó (14): Ọ̀gangan híhó ni ibi tí iná yóò se nǹkan dé tí nǹkan olómi náà yóò fi máa hó. Ọ̀gangan híhó yìí ni nǹkan olómi ti máa ń di nǹkan aláfẹ́fẹ́, ìyẹn òyì/gáàsì (gas). Bí àpẹẹrẹ, epo máań tètè hó lórí iná ju omi lọ. Èyí fi hàn pé ìgbóná tí yóò mu epo yí padà sí òyì (gáàsì)́ kò lè tó ti omi.

Yàtọ̀ sí ìtọ́wò (taste) àti òórùn (odour) tí wọ́n ṣòro láti ṣe ìgbéléwọ̀n (15) bí wọ́n ṣe tó, gbogbo àwọn àbùdá yòókù ni a lè lò láti fi ìyàtọ̀ hàn láàrin ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) kan sí òmíràn.

Àyànkọ (note)

  1. ‘Solution’ ni a ń pè ní omíyòòrò.
  2. ‘Volume’ ni a ń pè ní àlàfo tí nǹkan gbà.
  3. ‘Malleability’ ni a pè ní ìrára-yí-padà.
  4. Metal’ ni a ń pè ní alugbinrin. Alugbinrin dúró fún ohun tí ó lè dún bí irin bí a bá lù ú.
  5. ‘Lead’ ni a ń pè ní òjé.
  6. ‘Crystalline form’ ni a ń pè ní ìdì.
  7. ‘Shape’ ni a ń pè ní ìwò.
  8. ‘Physical shape at room temperature’ ni eléyìí dúró fún. Ní àsìkò yìí ni a máa ń sọ pé nǹkan kan kò gbóná jù bẹ́ẹ̀ ni kò tutù jù.
  9. ‘Solid’ ni a pè ní ohun tí ó dì. Èyí ni nǹkan tí ó jẹ abara-líle tí ó ṣeé gbámú.
  10.  ‘Liquid’ ni a pè ní olómi.
  11.  Nǹkan aláfẹ́fẹ́ ni gáàsì, bí àpẹẹrẹ, isó, afẹ́fẹ́ tàbí ooru. Gáàsì kò ṣeé gbé dání bẹ́ẹ̀ ni kò ṣeé gbámu. A lè gbé omi (liquid) dáni ṣụgbọ́n kò ṣeé gbámú. A lè gbá nǹkan tí ó ba dì (solid) mú a sì lè gbé e dáni.
  12.  ‘Melting point’ ni a pè ní ọ̀gangan yíyọ.
  13.  ‘Temperature’ ni a pè ní ìgbóná.
  14.  ‘Boiling point’ ni a ń pè ní ọ̀gangan híhó.
  15.  ‘Quantitative evaluation’ ni a  pè ní ìgbéléwọ̀n bí wọ́n ṣe tó. Bí wọ́n ṣe tó yìí lè jẹ́ nípa kíkà tàbí wíwọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, a kò lè ka òórùn bẹ́ẹ̀ ni a kò lè ka bí títọ́ tí a tọ́ nǹkan wò ṣe tó.

Ayé Yúránọ́ọ̀sì (Uranus)| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Apá kejìlá nì yí lórí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Ní ọ̀tẹ̀ yí, ìrìn àjò di orí ayé tí à ń pè ní Ayé Yúránọ́ọ̀sì. Yúránọ́ọ̀sì ni ó súnmọ́ òòrùn sìkeje.

Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ ayé ràbàtà oní-yìnyín (ice giant). Òhun gan-an náà sì ni ayé tó tutù jù nínú sàkáání òòrùn (solar system) wa. Ìgbóná tó kéré jù lórí Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ Sẹ́síọ̀sì igba-lé-mẹ̀rínlélógún òdì (-224 Celcius).

Bí a bá fi ojú ààrindétí (ààrin-dé-etí, radius) wòó, Yúránọ́ọ̀sì ni ó tóbi sìkẹta nínú sàkáání òòrùn wa. Yóò tó mẹ́tàlélọ́gọ́ta ilé ayé wa yí tí yóò para pọ̀ kí á tó le mú Yúránọ́ọ̀sì ẹyọ kan jáde.

Yúránọ́ọ̀sì kò ní orílẹ̀ kankan tí ènìyàn ti le rìn gẹ́gẹ́ bíi ilé ayé. Àwọn ohun ajẹmọ́-yìnyín tó dà gẹ́gẹ́ bíi omi ni ó yí orí rẹ̀ po. Àwon ohun ajẹmọ́ yìnyín yí ni omi, àmóníà àti mẹtéènì. Sùgbọ́n sá o, ààrin gbùngbùn Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ ohun líle tó jẹ́ kìkì apáta. Àwọn òyì (gas) bíi áídrójìn, mẹtéèni, àti hílíọ̀mù ni ó sara jọ sí ojú òfurufú (atmosphere) Yúránọ́ọ̀sì.

Bí a bá fi ojú bí a ṣe ń ka ọjọ́ àti ọdún lórílẹ̀ ayé wo Yúránọ́ọ̀sì, a ó ríi pe ọjọ́ lórí rẹ̀ kéré bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún kan lórí rẹ̀ pẹ́ gan-an. Wákàtí mẹ́tàdínlógún ni ọjọ́ kan lorí Yúránọ́ọ̀sì. A ó ka ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin lórílẹ̀ ayé kí ọdún kan ó tó pé lórí Yúránọ́ọ̀sì.

Gẹ́gẹ́ bíi Sátọ̀n, Yúránọ́ọ̀sì náà ní àwọn òrùka, sùgbọ́n àwọn òrùká rẹ̀ kò rinlẹ̀ bíi ti Sátọ̀n. Àwọn òrùka mẹ́tàlá ni a tíi mọ̀ tí wọ́n pagbo yí Yúránọ́ọ̀sì ká. Yúránọ́ọ̀sì dáyàtọ̀ láàrin gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn wa pẹ̀lú bí ó se jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ ni ó fi ń pòòyì (rotate). Gẹ́gẹ́ bíi Àgùàlà (Venus), ìlà oòrùn (east) sí ìwọ̀ oòrùn (west) ni ìpòyì rẹ̀. Àwọn òsùpá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni wọn n rabababa yipo Yúránọ́ọ̀sì.

Yúránọ́ọ̀sì ko le fi ayé gba awọn ẹda abẹmi gẹgẹ bi a ṣe mọ wọn.

Atakóró wo̩nú wínní-wínní 1| Fààbú sáyẹ́ǹsì láti ọwọ́ Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀

Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Pè̩lú ìfajúro ni o̩mo̩débìrin kan tí orúko̩ rè̩ ń jé̩ Ìmó̩wùnmí fi délé lọ́sàn-án o̩jó̩ kan láti ilé-è̩kó̩ọ rè̩. Kìí s̩e pé olùkó̩ rè̩ nà án lẹ́gba tàbí fi ìyà kan jẹ ẹ́. Wó̩n kan so̩ fún un pé bóyá ni yóò lè máa tẹ̀ síwájú ní ẹ̀ka ìmò̩-ìjìnlè̩ ní ìpele As̩è̩gbó̩n-kìnni nílé è̩kó̩-gíga ni. Ó ti ka ìwé kẹta ní ìpele As̩àbúrò yege, ò sì ti bọ́ sí ìpele àkọ́kọ́ As̩è̩gbó̩n. S̩ùgbó̩n àwo̩n olùkọ́ọ rè̩ ti so̩ fún un pé ó ní láti ta yọ dáadáa nínú ìdánwó rè̩ tó ḿ bọ̀ ló̩nà. Eléyìí ni wó̩n yóò fi mo̩ àwo̩n ti yóò kù ní ẹ̀ka ìmò̩-ìjìnlè̩. Ọ̀rọ̀ yìí ka iyáa rè̩ tó ń jẹ́ Ìmò̩níyì lára nítorí kò fe ki o̩mo̩débìrin ọ̀un máà wà nínú ìbànújẹ́ kan niti è̩kó̩ rè̩. Pàápàá jùlo̩, èrò o̩mo̩débìrin náà wípé àyàfi tí òun ba s̩e òògùn ìsọ̀yẹ̀ kí òún tóó lè mo̩ ohun tí wó̩n ń kó̩ oun nínú ìmò̩-ìjìnlè̩. Ìyá rè̩ pàrọwà fún un títí pé bí òógún ìsọ̀yè bá tilẹ̀ wà, yóò kàn jẹ́ kó ranti ohun tó ti kó̩ tó sì mò̩ nìkan ni, s̩ùgbó̩n ohun tá à ń pè ni kénìyàn mo̩ ohun kan ni kó mo̩ igbà tí óun lè s̩e àmúlò ìmò̩ bé̩è̩.

Wọ́n kó ò̩rò̩ yìí dé ọ̀dọ̀ bàbáa rè̩ tó ń jẹ́ Ìrínìmò̩. Bàbá náà gbà láti ran o̩mo̩ rè̩ ló̩wó̩ ní ti è̩kó̩ rè̩ kó lè gbé igbá-orókè. Ó so̩ fún un pé òun yóò s̩e òògùn kan fún un tí yóò fi mo̩ ìwé rè̩ dáradára. Ó wí fún o̩mo̩ rè̩ pé òògùn yìí ti wà ní ìdílé àwo̩n fún o̩jó̩ pípé, òun ni àwo̩n bàbá ńlá òun máa ń lo tí ọ̀ràn kan kò bá yé wọn. Gbogbo bi bàbá náà ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí ni ìyáa rè̩ ń fi ojú ré̩rìn-ín tí kò sì jẹ́ kí o̩mo̩débìrin náà mọ̀. Bàbá náà ní kí o̩mo̩ òun pèlò sílẹ̀ nítorí àwo̩n yóò rìnrìn-àjò àràm̀barà kan. Ó ní kí ó mú ìwé pélébé kan àti gègé ìkọ̀wé ló̩wó̩ fún àkọsílẹ̀. Pàápàá jùlọ, ó so̩ fún un kó rán òun létí láti má gbàgbé fèrè-òwú bàǹtù kan tí òun fé̩é̩ fún un. Bàbá rè̩ s̩àlàyé pé, fèrè yìí máa ń mú kí ohunkóhun tí ènìyàn ba fo̩n ọ́n sí wú bàǹtùbàǹtù. Ó ní kí o̩mo̩débìrin náà máa lo̩ s̩erée rè̩ níta pè̩lú àwo̩n ake̩gbé̩ rè̩, kó sì má mikàn mọ́.

O̩mo̩débìrin náà lo̩ darapò̩ mó̩ àwo̩n ake̩gbé̩ rè̩, wó̩n sì bè̩rè̩ eréé ṣe. Wó̩n ń kọrin pé:

Lílé: Ó di kóro, 
Gbígbè: Kòro
Lílé: Ó di kóro, 
Gbígbè: Kòro
Lílé: Ó para pò̩, 
Gbígbè: E̩ja dúdú parapò̩ mó̩ è̩gúsí
Lílé: Ó para pò̩, 
Gbígbè: E̩ja dúdú parapò̩ m’é̩gúsí

Bàbá àti ìyá ń wo o̩mo̩ wó̩n bó ṣe ń bá àwo̩n ake̩gbé̩ rè̩ ṣeré, wó̩n sì ń tàkurọ̀ so̩ pé ìbá jẹ́ pé ó mo̩ bí orin tí wó̩n ń ko̩ náà ṣe ṣàfihàn ohun tó bi ìmò̩-ìjìnlè̩ tòní, kò bá tí so̩ pé òun kò lè mo̩ ìmò̩-ìjìnlè̩ àyàfi bí òun bá s̩e òògùn ìsò̩yè. Ìmò̩níyì, ìyá o̩mo̩ náà sì bè̩rè̩ ò̩rò̩ wí pé: 

“Ohun gbogbo tó ń bẹ láyé ló ní kóro bí e̩yin e̩ja. Omi, afé̩fé̩, erùpè̩ àti ìmó̩lè̩. Kóro wínní-wínní parapò̩ wó̩n di mó̩lékù, ìye̩n ohun tó mo̩ lé ara rè̩ títí tí. Mó̩lékù parapò̩ wó̩n di èròjà-àbámáyé gbogbo. Nígbà miran è̩wè̩, kóro wínní-wínní èròjà kan lè parapò̩ mó̩ ti òmíràn, bi kóro wínní-wínní ẹyin ẹja ti lè parapò̩ mó̩ kóro wínní-wínní è̩gúsí, láti bè̩, èròjà mííràn a sis̩è̩ wáyé.”

Lé̩yìn èyí, àwọn o̩mo̩dé náà tún ṣe eré mííràn. Wọ́n sì tún ń ko̩rin:

Lílé: Olú pagbo yí mi ká
Gbígbè: Pagbo
Lílé: Ògè̩dè̩ pagboy’ódò ká
Gbígbè: Pagbo
Lílé: Olú pagbo yí mi ká
Gbígbè: Pagbo
Lílé: Ògè̩dè̩ pagbo rìbìtì
Gbígbè: Pagbo Ìyá

Ìmó̩wùnmí tún sò̩rò̩. Ó ní, “Àwo̩n ohun kan máa ń pagbo yí olódì kejì rè̩ tó wa láàárín ká ni ninu ohun gbogbo. Bó ti wà nínú agbáre̩re̩ (1) bó ti tóbi tó náà ló wà nínú wínnípin bó ti kéré jo̩jo̩ tó. Agbára olódì-kejì yìí yóò sì máa gbé wo̩n yí ká rè̩. Bó ti rí nínú ìdo-ayíbiiri-móòrùn (2) náà nìye̩n. Nínú agbáre̩re̩, ò̩gbún-òkùnkùn (3) kán wà láàárín tí ìtàns̩án ìmó̩lè̩ kò leè wò̩, nítorí náà a kò mo̩ ohun tó dì sí’kùn, agbára rè̩ ló sì ń gbé ohun gbogbo ló̩wó̩jà rè̩ yí biiri. Nínú ìdo-ayíbiiri-móòrùn pè̩lú, ò̩rara-òòrùn wà láàárín, òun ló sì ń gbé ohun gbogbo lákàtàa rè̩ yí biiri. Bákan náà nínú wínnípin, olódì-kejì kan àti èkejì rè̩ ló wà níbè̩, ò̩kan sì ń gbé èkejì yíká ara rè̩.”

  1. agbáre̩re̩ – galaxy (láti inú oríkì kan tó wípé “Ò̩rúngbá re̩re̩ lójú o̩mo̩dé.” Lóòótó̩, eléyìí ń so̩ nípa ìkuùkú ojú ò̩run, s̩ùgbó̩n àwo̩n gálásì náà ń gbá re̩re̩ lo̩ nínú òfurú jágádo ni)
  2. ìdo-ayíbiiri móòrùn – solar system. Literally, it means ‘group encircling sun.’
  3. ò̩gbún-òkùnkùn – black hole

Hóró pínpín (Cell Division)| Adedoyinsọla Adegbaye& Raji Lateef

Lámèétọ́: Taofeeq Adebayo
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Hóró ni oun kan tó kéré jùlọ nínú ẹ̀dá oníyè. Òun náà sì ni ìpìlẹ̀ ìṣẹ̀mí ẹ̀dá oníyè. Bákan náà, a lè rí hóró bíi irinṣẹ́ tí àwọn àmúṣe-iṣẹ́ (active) ẹ̀dá-oníyè gbáralé, tí ó sì ń mú ìlọsíwájú bá ìgbé ayé irú àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ nítorí pé òun ni ọ̀pá-òdiwọ̀n tó kéré jùlọ fún ìṣẹ̀mí àwọn ẹ̀dá-oníyè. 

Hóró pínpín 
Èyí ni ètò bí hóró ìpìlẹ̀ (parent cell) ṣe ń pín sí hóró tuntun (daughter cells) méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ètò pínpín hóró máa ń wáyé nínú ètò ìyírapadà hóró (cell cycle). Nínú àwọn ẹ̀dá-oníyè abiwọ̀ kókó (eukaryotes), oríṣìí àwọn ẹ̀yà hóró pínpín méjì ni ó wà. Àwọn ni hóró pínpín oní-ìjọra (vegetative division/mitosis) àti hóró pínpín aláìní-ìjọra (reproductive division/meiosis). Hóró pínpín oní-ìjọra (vegetative division/mitosis) máa ń wáyé nígbà tí kò bá sí ìyàtọ̀ láàárín hóró tuntun àti hóró ìpìlẹ̀ nípa àwọn àbùdá ajẹmọ́ran tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀dá oníyè, hóró pínpín oní-ìjọra jẹ́ ètò ìyírapadà hóró (cell cycle) tó ń ṣe okùnfà kí kókó (nuclei) àwọn ẹ̀dà okùn-ìran (chromosomes) pín sí méjì. Irúu pínpín báyìí á fún wan ní àwọn hóró alábùdá ajẹmọ́ran kan náà (genetically identical cells) tí iye okùn-ìran ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò sì yàtọ̀ sí ara. Ṣaájú hóró pínpín oníjọra (mitosis) ni Ìpele S (S Stage of interphase). Ìpele yìí níí ṣe pẹ̀lú dídá (synthesis) àwọn kẹ́míkà atọ́ka ìrandíran (DNA). Ìfihàn Aṣòpinyà Èròjà Ajẹmọ́ran (telophase) àti Ètò Pínpín Aláfojúrí (Cytokinesis) ló máa ń tèlé Ìpele S. Ìfihàn Aṣòpinyà Èròjà Ajẹmọ́ran (telophase) ni ìpele tí àwọn èròjà ajẹmọ́ran (genetic materials) inú èso kókó hóró (nucleolus) ti máa ń di pínpín sínú àwọn hóró tuntun ajọra (identical daughter cells) láti ara hóró ìpìlẹ̀ (parent cells). Ètò Pínpín Aláfojúrí (Cytokinesis) ló máa ń ṣe àfihàn pínpín oje hóró (cytoplasm), ẹ̀ya hóró kékèré (organelle) àti ìwọ-hóró (cell membrane) hóró ìpìlẹ̀ (parent cell) sínú àwọn hóró tuntun (daughter cells) méjì. Èyí máa ń wáyé pẹ̀lú pínpín kókó hóró, ní èyí tí a óò wá rí hóró tuntun méjì, tí àkónú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò sì ní yàtọ̀ sí ara wọn. 

Ẹ̀dá Oníyè Aláìníwọ̀ Hóró (Prokaryotes) máa ń tèlé ìlànà hóró pínpín oníjọra (vegetative cell division) tí a mọ̀ sí hóró pínpín alójúlódì (binary fission). Ìlànà yìí ló máa ń mú kí pínpín àwọn èròjà ajẹmọ́ran (genetic materias) sínú hóró tuntun méjì tí ọ̀kan ò níí ju èkejì wáyé. Yàtọ̀ sí ìlànà pínpín hóró alájúlódì (binary fission) tó máa ń wáyé nínú àwọn Ẹ̀dá Oníyè Aláìníwọ̀ Hóró (Prokaryotes), a ṣàkíyèsí ìlànà mííràn tí a mọ̀ sí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ (budding).

Fún àwọn ẹ̀dá oníyè oníhóró kan (unicellular organism), (bí àpẹrẹ Àmóẹbà (Amoeba)), pínpín hóró kan túmọ̀ sí ètò bíbí (reproduction) – èyí túmọ̀ sí pé ìṣẹ̀dá odidi ẹ̀dá oníyè kan ló wáyé. Nígbà mííràn hóró pínpín oníjọra (mitotic cell division) lè ṣẹ̀dá ẹ̀dá oníyè tuntun nínú ẹ̀dá oníyè oníhóró púpọ̀ (multicellular organism), bí àpẹrẹ, igi oko tó hù ní ìlànà gígé (cutting). Hóró pínpín oníjọra (mitotic cell division) máa ran ẹ̀dá oníyè oníbìí ìbálòpọ̀ (sexually reproducing organism) lówọ́ láti wáyé látara ọlẹ̀ oníhóró kan (tí òun fúnra rẹ̀ wáyé látara hóró pínpín aláìní-ìjọra – meiosis – tó wáyé látara ètò ìbísí takọtabo – gametes).

Hóró pínpín ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè, àtúnse àti dídá hóró tuntun nínú àgọ́ ara. Ohun tó jẹ́ àfojúsùn pàtàkì nínú ètò hóró pínpín ni ìdáàbò bò apó ẹyọ-ìran (genome) inú hóró ìpìlẹ̀ (original or parent cell). Kí hóró tóó di pínpín, a gbọ́dọ̀ ṣe ẹ̀dà ìmọ̀ ajẹmọ́ apó ẹyọ-ìran (genomic information) tí ó wà ní ìpamọ́ nínú okùn ìran àtipé ẹ̀dà náà gbódọ̀ jẹ́ pínpín lókan-ò-ju-ọ̀kan láàárín àwọn hóró tuntun tó wáyé.

Kẹ́mísírì| Ọjọgbọn Lawrence Adewọle (OAU) & A. A. Fabeku

Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

Kẹ́mísírì (1) jẹ́ ẹ̀ka sáyẹ́ǹsì àrígbéwọ̀n (physical science) (2) tí ó ṣeé dán wò (2) tí ó jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ tí ó ń kọ́ ni nípa èròjà (4), ìhun (5) àti ìyídà (6) ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) tí ó wà ní àgbáálá ayé (7). Kẹ́míìsírì tún máa ń kọ́ ni nípa òfin tí ó ṣe àlàyé ìyídà yìí. Kẹ́mísírì níí ṣe pẹ̀lú àtòpọ̀ (combination) tàbí àsèìtakora (reaction) èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (substance). Ìyẹn ni bí a ṣe lè to èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n kan pọ̀ mọ́ òmíràn tàbí bí a ṣe lè fi èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n kan ta ko òmíràn.

Kí ni ọ̀gbààyègbéwọ̀n?
Ọ̀gbààyègbéwọ̀n (8) jẹ́ ohunkóhun tí ó ní ìwọ̀n-okun (9) tí ó sì gba áyè. Ohun tí a pè ní ọ̀gbààyègbéwọ̀n yìí lè tóbí, ó sì lè kéré. A lè fi ojú rí i (tí ó bá tóbi tó nǹkan tí a lè fojú rí tàbí kí a má fi ojú rí i tí ó bá kéré ju ohun ti a lè fi ojú wa lásán rí tí ó jẹ́ pé a ó nílò awò amóhuntóbi (‘magnifying glass’) kí á tó lè rí i). Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé bí ó ti wù kí ó kéré tó, ohunkóhun tí ó bá ti ní ìwọ̀n-okun tí ó sì gba àyè ni a mọ̀ sí ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter). Ìwọ̀n-okun àti ìwúwo (10) bá ara wọn tan ṣùgbọ́n, síbẹ̀, wọ́n yàtọ̀ sí ara wọn gédégédé. Àwọn àpẹẹrẹ ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni afẹ́fẹ́, omi, òkúta, igi, ohun ọ̀gbìn, ẹranko, ènìyàn, alùgbinrin (11) àti gbogbo ohun tí ó yí wa ká, yálà, èyí tí a lè fi ojú rí tàbí èyí tí a kò lè fi ojú lásán rí.

Kí ni Ìwọ̀n?
Iwọ̀n ni iye (12) ọ̀gbààyègbéwọ̀n (13) tí ó wà nínú èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (14). Ìwọ̀n ni àbùdá tí nǹkan ní tí ó fi máa ń fẹ́ wà lóju kan láìpara dà tàbí kí ó máa lọ láìdúró.

Kí ni ìwúwo?
Ìwúwo (‘weight’) ni ipa tí òòfa lááláátóròkè (gravity) ní lórí ìwọ̀n-okun (mass) (15).

Àbùdá ọ̀gbààyègbéwọ̀n
A lè dá ọ̀gbààyègbéwọ̀n (‘matter’) mọ̀ nípa wíwo oríṣiríṣi àbùdá (16) tí ó ní. Oríṣi àbùdá méjì ni ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni. Èkíní ni àbùdá òde (17) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni. Èkejì ni àbùdá inú (18) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní. Àbùdá òde ti ọ̀gbààyègbéwọ̀n jẹ́ èyí tí a lè rí, tí a lè fi ọwọ́ kàn tàbí tí a lè wọ̀n nípa lílo ojú wa, etí wa, imú wa, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé a máa nílò àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ẹ̀rọ kí á tó lè lo ọ̀kan tàbí òmíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara láti fi mọ àwọn àbùdá wọ̀nyí (19) .

Àyànkọ (note)

  1. Orúkọ mìíràn fún kẹ́mísírì ni ìmọ̀ èrójà ẹ̀dá. Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, a máa ń pe nǹkan kan ní ‘substance’. ‘Substance’ yìí ni a lè pè ní ohun tí ó níí ṣẹ pẹ̀lú ọ̀gbààyègbéwọ̀n tí ó jẹ́ pé a lè fojú rí i tàbí kí a fọwọ́ kàn àn tàbí kí ó ṣeé wọ̀n. Tí a bá ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ohun tí a pè ní ‘substance’ yìí àti ọ̀nà tí a fi lè tò ó mọ́ irú rẹ̀ mìíràn (combine) tàbí kí ohun tí a pè ní ‘substance’ yìí torí nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí irú rẹ̀ mìíràn (act) ṣe nǹkan kan (react), irú ẹ̀kọ́ yìí ni a ń pè ní Kẹ́mísírì.
  2. À̀rígbéwọ̀n ni ohun tí a lè fojú rí tàbí tí a lè fọwọ ́kàn tàbí tí a lè wọ̀n.
  3.  Bí a bá dán nǹkan wò ni a fi máa ń mọ bí nǹkan náà ṣe rí gan-an.
  4. Bí a bá fọ́ nǹkan kan sí wẹ́wẹ́, àwọn nǹkan tí a lè bá nínú nǹkan náà ni èròjà nǹkan náà
  5. Ìhun ni bí a ṣe to nǹkan pọ̀̀. Ètò tí a lè sọ pé nǹkan kan ní ni a ń pè ní ìhun nǹkan náà.
  6. Ìyídà máa ń yí ìrísí tàbí àbùdá nǹkan padà, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kí nǹkan náà lè dára sí i
  7. Àgbáálá ayé dúró fún àwọn ìràwọ, ayé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
  8. Ẹ̀dá ni a ń pè ní ‘matter’ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ̀dá máa ń ní èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (‘substance’).
  9. Nìnù Kẹ́mísírì, ohun tí a ń pè ní ìwọ̀n-okun ni ‘mass’. Tí ó bá jẹ́ inú Físíìsì ni, ìṣù tàbí títóbi nǹkan ni a ń pè ni ‘mass’.
  10. ‘Weight’ yìí ni a ń pè ní  ìtẹ̀wọ̀n nínú ẹ̀kọ́ Físíìsì. Lára oríkì (definition) tí a lè fún ìtẹ̀wọ̀n yìí ni (i) ipá (force) tí ó dorí kọ ilẹ̀ tí nǹkan kan ní nítorí títóbi (mass) rẹ̀ (ii) ìmúrasaré (acceleration) nítorí ìfàlọsílẹ̀ (pull) ilẹ̀ ayé.
  11. Àwọn ohun tí a bá lù tí ó bá ń dún bí irin ni a ń pè ní alugbinrin.
  12. Iye dúró fún bí nǹkan kan ṣe pọ̀ tó.
  13. Ọ̀gbààyègbéwọ̀n dúró fún ‘matter’.
  14. Èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n dúró fún ‘substance’.
  15. Ayé ní òǹfà tí ó fi ń fa àwọn ohun tí ó wà ní inú rẹ̀ wá sí orí ilẹ̀ tàbí kí ó fa nǹkan kan mọ́ra. Èyí ni a ń pè ní ipá òòfa lááláátóròkè  (‘force of gravity’).
  16. Àbùdá ni ìrísí tí nǹkan kan ní. Èyí ni àwọn ohun tí a ń wọ mọ́ ǹnkan lára tí ó fi ƴàtọ̀ sí nǹkan mìíràn.
  17. ‘Physical properties’ ni àwọn àbùdá òde tí ẹ̀dá ní.
  18. ‘Chemical properties’ ni àwọn àbùdá inú tí ẹ̀dá ni.
  19. Bí àpẹẹrẹ, bí nǹkan kan bá kéré jù, a lè nílò awò amóhuntóbi (magnifying glass) kí a tó lè rí i dáadáa.

Ipá (force)| Olugbenga Ọlabiyi

Lámèétọ́: Lateef Adeleke
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

A ti sọ̀rọ̀ nípa ìsípòpadà (motion), èyí tí ó túmọ̀ sí ìpapòdà láti ibìkan sí ibòmíràn. Ní báyǐ, a fẹ́ ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tó ń fa ìpapòdà nkán láti ibìkan sí ibòmíràn. Kí ni ohun tó ń se okùnfà ìṣípòpadà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fi yé wa pé ipá (force) ni ó ń ṣe okùnfà bí nkan se n lọ síwájú, sẹ́yìn tàbí bí ó se ń  yí ní òbírípo (rotation). Ǹjẹ́ kínni ipá tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yíí?

Ipá ni a lè pè ní ohun tí ó le mù kí ǹkan kúrò ní ojú kan tàbí kí ìyára (velocity) rẹ̀ yí padà. Ipá jẹ́ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ṣòro láti se àlàyé sùngbọ́n ó jẹ́ ọ̀rọ́ tí a máa ńlò ní ìgbà dé ìgbà. Síwájú si, ipá jẹ́ ohun tí ó lágbára tí ó sì le mú kí nkàn tó wà lójúkan sún (move). Bákan náà, ipá le sè àyípadà ètò ọkọ̀ tí ó wà lórí ìrìn. Fún àpẹẹrẹ, abọ́ ìmùkọ wa yíò wà ní ibi tí a fi sí àfi tí a bá lo ipá. Bẹ́ẹ̀ni, ipá le è ṣe àyípadà eré (speed) ọkọ̀ tó ń lọ, yàlá láti yára síi (speed up) tàbí lọ́ra (slow down). Láfikún, ipá le rọ irin, ó le è tẹ agolo, ó le è da ètò nǹkàn rú, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìsọ̀rí méjì ni à le pín ipá sí. Àwọn nì wọ̀nyí:

  1. Ipá ìfarakínra (contact force). Èyi jẹ́ ipá tí ó gbọ́dọ̀ fara kan ohun tí a fẹ́ lò ó fún. Àpẹẹrẹ: fífa (pulling) nǹkan, tìti (pushing) nǹkan, ìfàle líle (tension), ipá ìfaragbora (frictional force), ̣ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
  2. Ipá áìfarakínra (non-conatct force)/ force field (pápá ipá): irú ipá yìí jẹ́ èyí tí kò ní lò kí á fi  ara kan ohun tí a fẹ́ lò ó fún. Èyí ni àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀: ípá òòfà-laáláatóròkè (gravitational force), ipá òòfà (magnetic force), ipá òjíjí (electrical force), àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ẹ̀jẹ̀ (blood)| Olubayọde Martins Afuyẹ

Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ

Ki a tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí, kí ni ẹ̀jẹ̀? Ẹ̀jẹ̀ jẹ́ àkójọpọ̀  oje ẹ̀jẹ̀ (plasma) àti àwọn hóró (cell) tó ń yíká nínu ara. Bákan náà, a lè rí ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi èròjà tó ń gbé àwọn ohun aṣaralóore (nutrients) kiri ara eranko ọlọ́pǎ-ẹ̀yin (vertebrate animals). Nínú mùdùnmúdùn (bone marrow) ni ìpèsè hóró ẹ̀jẹ̀ ti máa ń wáyé. Nínú ihò egungun ni a ti máa ń bá mùdùn-múdùn eegun. Mùdùn-múdùn eegun yìí ni àwọn ẹ̀yà hóró ìpìlẹ̀ (stem cell) tí wọ́n kápá làti yíra padà sí hóró ẹ̀jẹ̀ pupa (red blood cells), hóró ẹ̀jẹ̀ funfun (white blood cells) àti oje ẹ̀jẹ̀ (plasma). 

Àwọn ohun tó kóra jọ di ẹ̀jẹ̀ jẹ́ àwọn ohun méjì pàtàkì. Àwọn ni: èròjà olómi (liquid item) àti èròjà líle (solid item):

  1. Èròjà Olómi inú ẹ̀jẹ̀ là ń pè ní oje ẹ̀jẹ̀. Bí a bá ṣe àtúpalẹ̀ àkóónú ẹ̀jẹ̀, ìdá tí oje ẹ̀jẹ̀ kó, tó ìdá àádọ́ta sì ọgọ́ta (50-60%). Àwọn ohun tí a óò bá nínú oje ẹ̀jẹ̀ fúnra rẹ̀ ni omi, iyọ̀ àti purotéèni (protein).
  2. Èròjà líle inú ẹ̀jẹ̀ pín sí mẹta. Àwọn ni: hóró ẹ̀jẹ̀ pupa (red blood cells), hóró ẹ̀jẹ̀ funfun (white blood cells) àti hóró amẹ́jẹ̀dì (platelets).

Hóró-amẹ́jẹ̀dì (Platelet): Èyí jẹ́ hóró tó kéré, tí kò sì ní àwọ̀ (colourless). Òun ni ó  máa ń ran ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ lati dìpọ̀ (to clot) nígbàtí  a bá farapa, tí ó sì lójú (wound). Ó kápá láti dènà tàbí dẹkùn ẹ̀jẹ̀ tó ń jáde lójú ọgbẹ́. Hóró-amẹ́jẹ̀dì tó wà nínú máìkíròlítà (microliter) ẹ̀jẹ̀ kan yóò tó ọ̀kẹ́ méje àti ẹgbàá sí ogun ọ̀kẹ́ lé méjì àti ẹgbàá (150,000 – 450,000). 

Hóró ẹ̀jẹ̀ Pupa tàbí ẹ̀rítírósáìtì (Red blood cells/erythrocytes): Hóró ẹ̀jẹ̀ pupa yìí náà ni a mọ̀ sí ẹ̀rítírósáìtì (erythrocytes – ìtumọ̀ èyí kò yàtọ̀ sí tí hóró ẹ̀jẹ̀ pupa). Ọ̀rọ̀ Gíríkì (Greek) ní, tí ìpìlẹ̀ ìṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ “ẹ̀rítíròsì” (erythros) tó dúró fún pupa àti “sáìtì” (cyte) tó dúró fún hóró. Hóró ẹ̀jẹ̀ pupa ló gbajúmọ̀ jù nínú àwọn hóró ẹ̀jẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì fún gbígbé òyì-iná/ọ́ksíjìnì (oxygen) láti inú ẹ̀dọ̀fóró sì èya ara gbogbo, ó sì tún jẹ́ ohun ayí-àwọ̀padà (pigment) tí ó fún ẹ̀jẹ̀ ní àwọ pupa rẹ̀. Bákan náà, ó ní purotéènì táà ń pè ní agbọ́ksíjìn-kánú-ẹ̀jẹ̀ (hemoglobin). Hóró ẹ̀jẹ̀ pupa ni hóró tó pọ̀ jù nínú àgọ́ ara ọmọ-ènìyàn, a sì máa tó bí ogún sì ọgbọ̀n tírílíọ̀nù (20-30 trillion) nínú ara. Ẹ̀jẹ̀ ara ọkùnrin máa ń pò ju ti obìnrin lọ. Hóró ẹ̀jẹ̀ pupa kọ̀ọ̀kan a máa  lo tó oṣù mẹ́rin kí ó tó di aláìsí. Ojoójúmọ́ ni ara máa pèsè hóró ẹ̀jẹ̀ pupa tuntun láti rọ́pò àwọn tí o tí ku tàbí àwọn tí ara pàdánù. 

Hóró ẹ̀jẹ̀ funfun tàbí lúkósáìtì (white blood cells/leukocytes): Àwọn hóró ẹ̀jẹ̀ funfun jẹ́ àwọn hóró tó ń ṣiṣẹ́ fún ètò-àjẹsára (immune system) tó ń dáàbò bo ara níbi àwọn àìsan alákóràn (infectious diseases) àti àwọn ohun àjèjì (foreign invader). Orisun àwọn hóró ẹ̀jẹ̀ funfun ni mùdùn-múdùn inú eegun. Nínú gbogbo ẹ̀yà ara pátá ni a ti lè rí hóró ẹ̀jẹ̀ funfun. Èyí túmọ̀ sí pé a óò ma ṣalábàpádèé wọn nínú ètò ẹ̀jẹ̀ (blood system) àti ètò omi-ara (lymphatic system).