Awọn abara ofuurufu (Celestial bodies)

Irinkerindo ninu agbanla aye 5: Sàkáání òòrùn apa 2 (Expedition within the universe 5: The solar system 2)

Irinkerindo ninu agbanla aye 5: Sàkáání òòrùn apa 2 (Expedition within the universe 5: The solar system 2)

Posted by Science in Yoruba on Sunday, June 7, 2020

Irinkerindo ninu agbanla aye 2: ipooyi ile aye ati irababa rẹ yipo oorun

Irinkerindo ninu agbanla aye 2: ipooyi ile aye ati irababa rẹ yipo oorun (Expedition within the universe 2: Earth’s rotation and its revolution around the sun)

Irinkerindo ninu agbanla aye 2: ipooyi ile aye ati irababa rẹ yipo oorun (Expedition within the universe 2: Earth’s rotation and its revolution around the sun)

Posted by Science in Yoruba on Sunday, May 17, 2020

Ayé Nẹ́ptúùn (Neptune)| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́: Alabi Sherif
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ó yá ẹ dáhun ìbéèrè yìí: ayé wo ló jìnà jù sí òòrùn nínú sàkáání òòrùn wa? Ẹ tún wá nǹkan fìdí lé bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú apá kẹtàlá yìí lórí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Níbáyìí, ẹ bá wa kálọ sí orí ayé tí a mọ́ orúkọ rẹ̀ sí Nẹ́ptúùn.

Nẹ́ptúùn ni ó súnmọ́ òòrùn sìkẹjọ. Nẹ́ptúùn yí kan náà ni ó jìnà sí òòrùn jù nínú gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn (solar system) wa. Òótọ́ ni pé àwọn abara òfuurufú (celestial body) kan wà bíi Plútò tí àwọn tún jìnà ju Nẹ́ptúùn lọ, sùgbọ́n àwọn abara òfuurufú yíì kíì ṣe ayé; aràrá ayé (dwarf planet) ni wọ́n.

Ìgbóná-tutù (temperature) tó wọ́pọ̀ jù lórí Nẹ́ptúùn jẹ́ Sẹ́síọ́sì igba-lé-mẹ́wàá òdì (-210 Celsius). Wákàtí mẹ̀rìndínlógún lórílẹ̀ ayé wa yí ni ọjọ́ kan lórí Nẹ́ptúùn. A ó ka bíi ọdún márùn-dín-láàdọ́sǎn (165) lórílẹ̀ ayé kí ọdún kan ó tó pé lórí rẹ̀.

Bí a bá fi ojú àyípo (circumference) wòó, Nẹ́ptúùn ló tóbi sìkẹrin nínú sàkáání òòrùn wa. Yóò tó mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ilé-ayé tí à ń gbé orí rẹ̀ yí tí yóò parapọ̀ kí á tó leè mú Nẹ́ptúùn ẹyọ kan jáde.

Gẹ́gẹ́ bíi Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn jẹ́ ayé ràbàtà oní-yìnyín (ice giant). Àwọn ayé ràbàtà (giants) mẹ́rin ló wà ní sàkáání òòrùn wa. Àwọn ayé ràbàtà yi ni Júpítà, Sátọ̀n, Yúránọ́ọ̀sì àti Nẹ́ptúùn. Nẹ́ptúùn ló kéré jù láàrin àwọn ayé wọ̀nyìí.

Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn kò ní orílẹ̀ kankan tí ènìyàn le dúró lé lórí. Alagbalúgbú òyì (gas) ló yí orí rẹ̀ po. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn náa ní àwọn òrùka. Àwọn òrùka mẹ́fà gbòógì ló pagbo yíi ká.

Bákanáà, mẹ́rìnlá ní àwọn òsùpá tí ìwádǐ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ń rábàbà yípo Nẹ́ptúùn.

Gẹ́gẹ́ bí Mẹ́kíúrì, Àgùàlà, Júpítà, Sátọ̀n àti Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn kò leè jẹ́ ibùgbé fún àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wọ́n.

Ayé Yúránọ́ọ̀sì (Uranus)| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Apá kejìlá nì yí lórí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Ní ọ̀tẹ̀ yí, ìrìn àjò di orí ayé tí à ń pè ní Ayé Yúránọ́ọ̀sì. Yúránọ́ọ̀sì ni ó súnmọ́ òòrùn sìkeje.

Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ ayé ràbàtà oní-yìnyín (ice giant). Òhun gan-an náà sì ni ayé tó tutù jù nínú sàkáání òòrùn (solar system) wa. Ìgbóná tó kéré jù lórí Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ Sẹ́síọ̀sì igba-lé-mẹ̀rínlélógún òdì (-224 Celcius).

Bí a bá fi ojú ààrindétí (ààrin-dé-etí, radius) wòó, Yúránọ́ọ̀sì ni ó tóbi sìkẹta nínú sàkáání òòrùn wa. Yóò tó mẹ́tàlélọ́gọ́ta ilé ayé wa yí tí yóò para pọ̀ kí á tó le mú Yúránọ́ọ̀sì ẹyọ kan jáde.

Yúránọ́ọ̀sì kò ní orílẹ̀ kankan tí ènìyàn ti le rìn gẹ́gẹ́ bíi ilé ayé. Àwọn ohun ajẹmọ́-yìnyín tó dà gẹ́gẹ́ bíi omi ni ó yí orí rẹ̀ po. Àwon ohun ajẹmọ́ yìnyín yí ni omi, àmóníà àti mẹtéènì. Sùgbọ́n sá o, ààrin gbùngbùn Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ ohun líle tó jẹ́ kìkì apáta. Àwọn òyì (gas) bíi áídrójìn, mẹtéèni, àti hílíọ̀mù ni ó sara jọ sí ojú òfurufú (atmosphere) Yúránọ́ọ̀sì.

Bí a bá fi ojú bí a ṣe ń ka ọjọ́ àti ọdún lórílẹ̀ ayé wo Yúránọ́ọ̀sì, a ó ríi pe ọjọ́ lórí rẹ̀ kéré bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún kan lórí rẹ̀ pẹ́ gan-an. Wákàtí mẹ́tàdínlógún ni ọjọ́ kan lorí Yúránọ́ọ̀sì. A ó ka ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin lórílẹ̀ ayé kí ọdún kan ó tó pé lórí Yúránọ́ọ̀sì.

Gẹ́gẹ́ bíi Sátọ̀n, Yúránọ́ọ̀sì náà ní àwọn òrùka, sùgbọ́n àwọn òrùká rẹ̀ kò rinlẹ̀ bíi ti Sátọ̀n. Àwọn òrùka mẹ́tàlá ni a tíi mọ̀ tí wọ́n pagbo yí Yúránọ́ọ̀sì ká. Yúránọ́ọ̀sì dáyàtọ̀ láàrin gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn wa pẹ̀lú bí ó se jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ ni ó fi ń pòòyì (rotate). Gẹ́gẹ́ bíi Àgùàlà (Venus), ìlà oòrùn (east) sí ìwọ̀ oòrùn (west) ni ìpòyì rẹ̀. Àwọn òsùpá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni wọn n rabababa yipo Yúránọ́ọ̀sì.

Yúránọ́ọ̀sì ko le fi ayé gba awọn ẹda abẹmi gẹgẹ bi a ṣe mọ wọn.

Ayé Sátọ̀n| Taofeeq Adebayo

Lámèétọ́ (proofreader): Bọde Ọjẹ
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo

Ẹ tún káàbọ̀ padà sí orí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Nínú apá kọkànlá yí, a ó máa tẹ̀ sí wájú sí orí ayé tí a mọ orúkọ rẹ̀ sí Sátọ̀n (Saturn).

Sátọ̀n ni ayé tí ó súnmọ́ òòrùn sìkẹfà. Sátọ̀n yí kan náà ni ó tóbi sìkejì nínú gbogbo àwọn ayé mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tó wà ní sàkáání òòrùn wa (our solar system). Gẹ́gẹ́ bíi Júpítà, Sátọ̀n jẹ ayé ràbàtà oní gáàsì (gas giant). Háídrójìn àti hílíọ́ọ̀mù ni gáàsì tí ó pọ̀ jù nínú àwọn ohun tó pilẹ̀ Sátọ̀n. Yóò ju ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta (700) ilé ayé wa yí lọ tí yóò parapọ̀ kí á tó le rí Sátọ̀n eyọ kan mú jáde.

Sátọ̀n dá yàtọ̀ láàrin àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn wa bí ó se jé pé òhun ló ní àwọn òrùka (rings) tó pọ̀ jù tí ó sì rinlẹ̀ jù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé yúránọ̀ọ̀sì náà ní àwọn òrùka, àwọn òrùka yúránọ́ọ̀sì kò rinlẹ̀ bíi ti Sátọ̀n. Yìyín àti àpáta èyí tí àwọn ohun bíi eruku ti yí lára ni ó parapọ̀ di àwọn òrùka Sátọ̀n. Àwọn ẹrun yìyín ati àpáta tí à ń sọ yí le kéré jọjọ, wọ́n sì leè tóbi tó odidi ilé. Mẹ́tàléláàdọ́ta (53) àwọn òsùpá ni ìwadìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ pé wọ́n ń rábàbà yípo (orbit) Sátọ̀n. Àwọn òsùpá Sátọ̀n mọ́kàndílọ́gbọ̀n (29) ni à ń dúró kí ìwadìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fi ìdí wọn múlẹ̀.

Ní ìwọ̀n bí Sátọ̀n ṣe jìnà sí òòrùn sí, yóò gba ìtànsán òòrùn ní ọgọ́rin ìṣẹ́jú kí ó tó dé orí Sátọ̀n. Ìsẹ́jú mẹ́jọ àti ogún ìṣẹ́jú àáyá ló má ń gba ìtànsán òòrùn láti rin ìrìn àjò láti orí òòrùn sí orílẹ̀ ayé. Nínú gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn wa, ọjọ́ lórí Sátọ̀n ló kéré sìkejì. Wákàtí mẹ́wǎ àti ìṣéjú méjìlélógójì tí à ń kà lórílẹ̀ ayé ni ọjọ́ kan lórí rẹ̀. Bákan náà, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, oṣù mẹ́rin àti bíi ọjọ́ mẹ́rìnlélógún tí à ń kà lórílẹ̀ ayé ni ọdún kan lórí rẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátọ̀n ní ààrin gbùngbùn (core) tó jẹ́ ohun líle, àwọn gáàsì tó dàbí omi ló yíi po. Èyí túmọ̀ sí pé Sátọ̀n kò ní orílẹ̀ tí ènìyàn le dúró lé lórí gẹ́gẹ́ bíi ayé wa yí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò súnmọ́ kí ìgbóná-tutù (temperature) orí Sátọ̀n fi ààyè gba ẹ̀dá abẹ̀mí, ó ṣeéṣe kí àwọn òsùpá rẹ̀ seé gbé fún àwọn ẹ̀dá alààyè.

Ǹjẹ́ ẹ́ gbádùn àkójọpọ̀ ìmọ̀ yí? Bí ó bá rí bákan náà, ẹ jẹ́ ká tún pàdé lórí apá kejìlá ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé níbi tí a ó ti máa ṣe àgbéyẹ̀wò ayé yuranọọsi.

Irinkerindo ninu agbanla aye (universe) kini: Ile aye

Ẹ jẹ ka bẹrẹ irinkerindo wa lati inu fasiti  UI ni ilu Ibadan. Bi o ba wuwa a le lọ si ilu miran bii Iseyin, Oyo ati bẹẹbẹẹ lọ. Akojọpọ awọn ilu ni o di ohun ti a n pe ni ipinlẹ. A le lọ lati ipinẹ Oyọ si ipinlẹ Eko. Bakan naa ni a le lọ si awọn ipinlẹ ni ilẹ awọn Ibo. A si le lọ si awọn ipinlẹ ni ilẹ awọn Hausa. Agbarijọpọ awọn ipinlẹ yi ni o di ohun ti an pe ni orilẹ-ede Nigeria.

A le kuro ni orilẹ ede Nigeria ki a lọ si orilẹ ede Chad. To ba wu wa a tun le lọ si orilẹ ede Ghana. A tun le lọ si Egypt ati bẹẹbẹẹ lọ. Awọn  orilẹ ede ti a ri ni sakaani wa lorileede Nigeria lo parapọ di orilẹ Africa (continent of Africa).

Awọn orilẹ miran naa tun wa. Lara wọn ni a ti ri, Orliẹ Europe, Orilẹ Asia, Orilẹ North America, Orilẹ South America, Orilẹ Australia ati orilẹ Antarctica. Yatọ si awọn orilẹ yii, a tun ni awọn erekuṣu (island) keekeeke. A pẹẹrẹ ni: Iceland

Awọn orilẹ, awọn erekuṣu ati okun to yi wọn ka lo parapọ di ile aye ti awọn oloyinbo n pe ni Earth. Gbogbo ohun ti a n pe ni ile aye ko ju eyi lọ: okun, awọn erekuṣu ati awọn orilẹ.

Gẹgẹ bi ile ise National Geographic ṣe tẹẹ jade, ti a ba da ile aye si mẹrin, o fẹẹ to ida mẹta ti okun ko ninu gbogbo ohun ti a n pe ni ile aye.