Category: Sáyẹ́ǹsì Àrígbéwọ̀n (Physical Sciences)
Irinkerindo ninu agbanla aye 3: Osupa
Irinkerindo ninu agbanla aye 3: Osupa (Expedition within the universe 3: The Moon)Irinkerindo ninu agbanla aye 3: Osupa (Expedition within the universe 3: The Moon)
Posted by Science in Yoruba on Monday, May 25, 2020
Irinkerindo ninu agbanla aye 2: ipooyi ile aye ati irababa rẹ yipo oorun
Irinkerindo ninu agbanla aye 2: ipooyi ile aye ati irababa rẹ yipo oorun (Expedition within the universe 2: Earth’s rotation and its revolution around the sun)Irinkerindo ninu agbanla aye 2: ipooyi ile aye ati irababa rẹ yipo oorun (Expedition within the universe 2: Earth’s rotation and its revolution around the sun)
Posted by Science in Yoruba on Sunday, May 17, 2020
Ayé Nẹ́ptúùn (Neptune)| Taofeeq Adebayo
Lámèétọ́: Alabi Sherif
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Ó yá ẹ dáhun ìbéèrè yìí: ayé wo ló jìnà jù sí òòrùn nínú sàkáání òòrùn wa? Ẹ tún wá nǹkan fìdí lé bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú apá kẹtàlá yìí lórí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Níbáyìí, ẹ bá wa kálọ sí orí ayé tí a mọ́ orúkọ rẹ̀ sí Nẹ́ptúùn.
Nẹ́ptúùn ni ó súnmọ́ òòrùn sìkẹjọ. Nẹ́ptúùn yí kan náà ni ó jìnà sí òòrùn jù nínú gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn (solar system) wa. Òótọ́ ni pé àwọn abara òfuurufú (celestial body) kan wà bíi Plútò tí àwọn tún jìnà ju Nẹ́ptúùn lọ, sùgbọ́n àwọn abara òfuurufú yíì kíì ṣe ayé; aràrá ayé (dwarf planet) ni wọ́n.
Ìgbóná-tutù (temperature) tó wọ́pọ̀ jù lórí Nẹ́ptúùn jẹ́ Sẹ́síọ́sì igba-lé-mẹ́wàá òdì (-210 Celsius). Wákàtí mẹ̀rìndínlógún lórílẹ̀ ayé wa yí ni ọjọ́ kan lórí Nẹ́ptúùn. A ó ka bíi ọdún márùn-dín-láàdọ́sǎn (165) lórílẹ̀ ayé kí ọdún kan ó tó pé lórí rẹ̀.
Bí a bá fi ojú àyípo (circumference) wòó, Nẹ́ptúùn ló tóbi sìkẹrin nínú sàkáání òòrùn wa. Yóò tó mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ilé-ayé tí à ń gbé orí rẹ̀ yí tí yóò parapọ̀ kí á tó leè mú Nẹ́ptúùn ẹyọ kan jáde.
Gẹ́gẹ́ bíi Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn jẹ́ ayé ràbàtà oní-yìnyín (ice giant). Àwọn ayé ràbàtà (giants) mẹ́rin ló wà ní sàkáání òòrùn wa. Àwọn ayé ràbàtà yi ni Júpítà, Sátọ̀n, Yúránọ́ọ̀sì àti Nẹ́ptúùn. Nẹ́ptúùn ló kéré jù láàrin àwọn ayé wọ̀nyìí.
Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn kò ní orílẹ̀ kankan tí ènìyàn le dúró lé lórí. Alagbalúgbú òyì (gas) ló yí orí rẹ̀ po. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ayé ràbàtà yókùn, Nẹ́ptúùn náa ní àwọn òrùka. Àwọn òrùka mẹ́fà gbòógì ló pagbo yíi ká.
Bákanáà, mẹ́rìnlá ní àwọn òsùpá tí ìwádǐ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ń rábàbà yípo Nẹ́ptúùn.
Gẹ́gẹ́ bí Mẹ́kíúrì, Àgùàlà, Júpítà, Sátọ̀n àti Yúránọ́ọ̀sì, Nẹ́ptúùn kò leè jẹ́ ibùgbé fún àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wọ́n.
Iṣẹ́ (Work) 2| Olugbenga Ọlabiyi
Lámèétọ́: Taofeeq Adebayo
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Ní báyìí, kí ni à ń pè ní iṣẹ́ nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ tí Físíìsì? Iṣẹ́ jẹ́ àmúlò ipá (force) láti mú ìṣípòpadà (motion) bá nǹkan. Èyí túmọ̀ sí pé ìsọdipúpọ̀ ìwọ̀n ipá (amount of force) àti ìwọ̀n-ìjìnà (distance) ní ọ̀gangan-àyè (direction) tí ipá ń lọ. Àwọn apẹẹrẹ isẹ́ máa ń farahàn nínú àwọn ìṣe (act) wọ̀nyí:
- Ẹni tó ń ti ọmọ-lanke (trolley) láti ibìkan sí ibòmíràn nínú ilé-ìtajà ńlá.
- Tí a bá gbé ẹrù láti ilẹ̀ sí orí tábìlì.
- Tí a bá gbé ẹrù sórí láti ibìkan dé ibòmíràn.
Àwọn àpẹẹrẹ tí a se yìí ń se àkọ̀júwe iṣẹ́ (work) ní ìbámu pẹ́lù bí àwọn onímọ̀ Físíìsì ṣe gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀.
Níbàyí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìṣẹ (acts) tí a ò le kà sí iṣẹ́, tàbí ká ṣọ wípé àwọn àpẹẹrẹ tí kò sàpèjúwe iṣẹ́. Àwọn nìwọ̀nyí:
- Ẹni to gbe apẹrẹ eṣo sori, to wa duro soju kan fun igba pipẹ tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí .
Fún àlàyé yéké, àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ fi yéwa wípé kò sí iṣẹ́ nínú kí a dúró sójú kan pẹ̀lú ẹrù lórí fún ìgbá pípẹ́ tàbí ìgbà díẹ̀.
Níparí, mo ní ìgbàgbọ́ wípé òye ohun tí à ń pè ní iṣẹ́ ti yé wa. Mo sì nígbàgbọ́ pé a ti rí ìyatọ̀ tó wà láàrin ohun tí gbogbo wa mọ̀ sí iṣẹ́ àti ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ń pè ní iṣẹ́. Ótún di ọjọ́ mì ọjọ́ ire.
Ẹ ṣeé pùpọ́!
Iṣẹ́ (Work) 1| Olugbenga Ọlabiyi
Lámèétọ́: Taofeeq Adebayo
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Ǹjẹ́ kíni àwọn ònimọ̀-ìjìnlẹ̀ ń pè ní iṣẹ́ (work)? Àwọn ìṣe (acts) àwa ẹ̀dá wo ni ó ń ṣe àpẹẹrẹ iṣẹ́? Bákan náà, àwọn ìṣe wo ni a ò leè kà sí iṣẹ́? A ó màá fi ìdáhùn sí àwọn ìbéèré wọ̀nyí nínú ẹ̀kọ́ yìí. Nítorínà, ẹ fì ìkàlẹ̀ síi; ẹ mú kálámù àti ìwé yín láti se àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ bá rí gbámú.
Kí a tó wọ inú tìfuntẹ̀dọ̀ ohun tí àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ń pè ní iṣẹ́ (nínú apá 2), ẹ jẹ́ kí á kọ́kọ́ ṣọ̀rọ̀ lérèfé nípa ǹkan tí gbogbo wa mọ̀ sí iṣẹ́ (work). Iṣẹ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ kan gbòógì tí a máa ń lò ní gbogbo ìgbà. Orísirísi ọ̀nà ni ẹ̀dá ènìyàn ń gbà lo ọ̀rọ̀ tí à ń pè ní “iṣẹ̀”. Fún àpẹẹrẹ:
- Mò ń lọ síbi iṣẹ̀
- Tádé ń sisẹ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ girama ní agbègbè mi
- Ọlá ṣe àlàyé bí ẹ̀rọ amúsẹ́yá (machine) rẹ̀ se ń se isẹ́
- Ọlá ṣe iṣẹ́ ọpọlọ
Pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí, a ó ripé ọ̀rọ̀ tí à ń pè ní iṣẹ́ (work) máa ń farahàn nínú ìse wa, pàápàá jùlọ a máa ń se àmúlò iṣẹ́ nípa agbára káká (physical strength) tàbí ọgbọ́n àtinúdá (mental effort).
Níbìyí la o fi àgbàdá ètò rọ̀ sí lòní. A ó máa tẹ̀sìwájú nínú apá 2.
Ẹ seun púpọ̀!
Àwọn àbùdá òde tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) ní| Ọjọgbọn Lawrence Adewọle (OAU) & A. A. Fabeku
Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Àwọn àbùdá òde (physyical characteristics) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní ni:
(i) Àwọ̀: Àwọ̀ ni ó ń jẹ́ kí á mọ̀ bóyá funfun (white) ni nǹkan kan tàbí gbúre (pink) t̀abí pupa (red) tàbí òfèéfèé (yellow) tàbí omi ọsàn (orange) tàbí sànyán (brown) tàbí dúdú (black) tàbí aró (blue) tàbí eerú (grey) tàbí ẹsẹ̀ àlùkò (purple) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
(ii) Ìtọ́wò: Ìtọ́wò ni ó ń jẹ́ kí á mọ bí nǹkan kan bá dùn tàbí ó korò tàbí ó kan.
(iii) Òórùn: Òórun lè jẹ́ òórùn dídùn, òórùn kíkan, òórùn ìdíbajẹ, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
(iv) Yíyòòrò: Yíyòòrò níí ṣẹ pẹ̀lú pé ṣé nǹkan kan lè yòòrò tàbí kí ó yọ́ kí ó di omíyòòrò (1).
(v) Líle: Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé ṣé nǹkan tí a ń ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ le, ṣé ó sòro láti tẹ̀, ṣé ó ṣòro láti gé tàbí pé ṣé ó ṣòro láti kán.
(vi) Ọ̀rìn (dẹńsítì): Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú fífúyẹ́ tàbí wíwúwo nǹkan kan tí a bá fi ojú àlàfo (2) tí nǹkan náà gbà wò ó. Dẹ́ńsítì níí ṣe pẹ̀lú fífúyẹ́ tàbí títóbi nǹkan. A lè rí nǹkan tí ó tóbi tí ó sì fúyẹ́ a sì lè rí nǹkan tí ó kéré tí ó sì wúwo. Tí a bá fi ojú àbùdá báyìí wo nǹkan, ojú dẹ́ńsítì ni a fi ń wo nǹkan náà nìyẹn.
(vii) Ìrára-yí-padà (3): Awọn ohun-ẹ̀dá (substance) kan wà tí ìrísi wọn rọrùn láti yí padà. Bí apẹẹrẹ, alugbinrin (4) kan tí ó rọrùn láti yí padà sí ìrísí mìíràn ni òjé (5). Ìyẹn ni pé tí ìrísí rẹ̀ bá rí pẹlẹbẹ, ó rọrùn láti yí padà sí ìrísí tí ó dà bí okùn, bẹ́ẹ̀ ni, bí irísí rẹ̀ bá dà bí okùn, ó rọrùn láti yí i padà sí pẹlẹbẹ.
(viii) Ìrísí Ìdì (6): Eléyìí níí ṣe pẹ̀lú pé bóyá ohun-ẹ̀dá (substance) kan ti dì tí ó sì ní ìwò (7) kan tàbí òmíràn.
(ix) Bí ìwò nǹkan ṣe rí nígbà tí ìgbóná ojú ọjọ́ bá bá ti inú ilé dọ́gba (room temperature) (8): Ní àsìkò tí ìgbóná ojú ọjọ bá bá ti inú ilé dọ́gba, ṅ̀jẹ́ a lè sọ pé ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) kan jẹ́ ohun tí ó dì (9) tàbí tí ó jẹ́ olómi(10) tàbí kí ó jẹ òyì/gáàsì (gas) (11).
(x) Ọ̀gangan Yíyọ́ (12): Ọ̀gangan yíyọ́ yìí ni ibi tí ìgbóná (13) yóò dé tí ohun-ẹ̀dá (substance) yóò fi yọ́ tàbí tí yóò fi yòrò. Bí àpẹẹrẹ, ìgbóná tàbí iná tí yóò mú òrí (shea-butter) yọ́ tàbí tí yóò mú un yòrò kò lè tó èyí tí yóò mu irin yọ́. Ìyẹn ni pé iná tí yóò mú irin yọ́ yóò ju ti òrí lọ. Ọ̀gangan yíyọ́ ni ibi tí nǹkan abara-líle máa ń gbóná dé kí ó tó yọ di olómi.
(xi) Ọ̀gangan Híhó (14): Ọ̀gangan híhó ni ibi tí iná yóò se nǹkan dé tí nǹkan olómi náà yóò fi máa hó. Ọ̀gangan híhó yìí ni nǹkan olómi ti máa ń di nǹkan aláfẹ́fẹ́, ìyẹn òyì/gáàsì (gas). Bí àpẹẹrẹ, epo máań tètè hó lórí iná ju omi lọ. Èyí fi hàn pé ìgbóná tí yóò mu epo yí padà sí òyì (gáàsì)́ kò lè tó ti omi.
Yàtọ̀ sí ìtọ́wò (taste) àti òórùn (odour) tí wọ́n ṣòro láti ṣe ìgbéléwọ̀n (15) bí wọ́n ṣe tó, gbogbo àwọn àbùdá yòókù ni a lè lò láti fi ìyàtọ̀ hàn láàrin ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) kan sí òmíràn.
Àyànkọ (note)
- ‘Solution’ ni a ń pè ní omíyòòrò.
- ‘Volume’ ni a ń pè ní àlàfo tí nǹkan gbà.
- ‘Malleability’ ni a pè ní ìrára-yí-padà.
- Metal’ ni a ń pè ní alugbinrin. Alugbinrin dúró fún ohun tí ó lè dún bí irin bí a bá lù ú.
- ‘Lead’ ni a ń pè ní òjé.
- ‘Crystalline form’ ni a ń pè ní ìdì.
- ‘Shape’ ni a ń pè ní ìwò.
- ‘Physical shape at room temperature’ ni eléyìí dúró fún. Ní àsìkò yìí ni a máa ń sọ pé nǹkan kan kò gbóná jù bẹ́ẹ̀ ni kò tutù jù.
- ‘Solid’ ni a pè ní ohun tí ó dì. Èyí ni nǹkan tí ó jẹ abara-líle tí ó ṣeé gbámú.
- ‘Liquid’ ni a pè ní olómi.
- Nǹkan aláfẹ́fẹ́ ni gáàsì, bí àpẹẹrẹ, isó, afẹ́fẹ́ tàbí ooru. Gáàsì kò ṣeé gbé dání bẹ́ẹ̀ ni kò ṣeé gbámu. A lè gbé omi (liquid) dáni ṣụgbọ́n kò ṣeé gbámú. A lè gbá nǹkan tí ó ba dì (solid) mú a sì lè gbé e dáni.
- ‘Melting point’ ni a pè ní ọ̀gangan yíyọ.
- ‘Temperature’ ni a pè ní ìgbóná.
- ‘Boiling point’ ni a ń pè ní ọ̀gangan híhó.
- ‘Quantitative evaluation’ ni a pè ní ìgbéléwọ̀n bí wọ́n ṣe tó. Bí wọ́n ṣe tó yìí lè jẹ́ nípa kíkà tàbí wíwọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, a kò lè ka òórùn bẹ́ẹ̀ ni a kò lè ka bí títọ́ tí a tọ́ nǹkan wò ṣe tó.
Ayé Yúránọ́ọ̀sì (Uranus)| Taofeeq Adebayo
Lámèétọ́: Raji Lateef
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayo
Apá kejìlá nì yí lórí ìrìnkèrindò wa nínú àgbáńlá ayé. Ní ọ̀tẹ̀ yí, ìrìn àjò di orí ayé tí à ń pè ní Ayé Yúránọ́ọ̀sì. Yúránọ́ọ̀sì ni ó súnmọ́ òòrùn sìkeje.
Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ ayé ràbàtà oní-yìnyín (ice giant). Òhun gan-an náà sì ni ayé tó tutù jù nínú sàkáání òòrùn (solar system) wa. Ìgbóná tó kéré jù lórí Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ Sẹ́síọ̀sì igba-lé-mẹ̀rínlélógún òdì (-224 Celcius).
Bí a bá fi ojú ààrindétí (ààrin-dé-etí, radius) wòó, Yúránọ́ọ̀sì ni ó tóbi sìkẹta nínú sàkáání òòrùn wa. Yóò tó mẹ́tàlélọ́gọ́ta ilé ayé wa yí tí yóò para pọ̀ kí á tó le mú Yúránọ́ọ̀sì ẹyọ kan jáde.
Yúránọ́ọ̀sì kò ní orílẹ̀ kankan tí ènìyàn ti le rìn gẹ́gẹ́ bíi ilé ayé. Àwọn ohun ajẹmọ́-yìnyín tó dà gẹ́gẹ́ bíi omi ni ó yí orí rẹ̀ po. Àwon ohun ajẹmọ́ yìnyín yí ni omi, àmóníà àti mẹtéènì. Sùgbọ́n sá o, ààrin gbùngbùn Yúránọ́ọ̀sì jẹ́ ohun líle tó jẹ́ kìkì apáta. Àwọn òyì (gas) bíi áídrójìn, mẹtéèni, àti hílíọ̀mù ni ó sara jọ sí ojú òfurufú (atmosphere) Yúránọ́ọ̀sì.
Bí a bá fi ojú bí a ṣe ń ka ọjọ́ àti ọdún lórílẹ̀ ayé wo Yúránọ́ọ̀sì, a ó ríi pe ọjọ́ lórí rẹ̀ kéré bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún kan lórí rẹ̀ pẹ́ gan-an. Wákàtí mẹ́tàdínlógún ni ọjọ́ kan lorí Yúránọ́ọ̀sì. A ó ka ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin lórílẹ̀ ayé kí ọdún kan ó tó pé lórí Yúránọ́ọ̀sì.
Gẹ́gẹ́ bíi Sátọ̀n, Yúránọ́ọ̀sì náà ní àwọn òrùka, sùgbọ́n àwọn òrùká rẹ̀ kò rinlẹ̀ bíi ti Sátọ̀n. Àwọn òrùka mẹ́tàlá ni a tíi mọ̀ tí wọ́n pagbo yí Yúránọ́ọ̀sì ká. Yúránọ́ọ̀sì dáyàtọ̀ láàrin gbogbo àwọn ayé tó wà ní sàkáání òòrùn wa pẹ̀lú bí ó se jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ ni ó fi ń pòòyì (rotate). Gẹ́gẹ́ bíi Àgùàlà (Venus), ìlà oòrùn (east) sí ìwọ̀ oòrùn (west) ni ìpòyì rẹ̀. Àwọn òsùpá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni wọn n rabababa yipo Yúránọ́ọ̀sì.
Yúránọ́ọ̀sì ko le fi ayé gba awọn ẹda abẹmi gẹgẹ bi a ṣe mọ wọn.
Kẹ́mísírì| Ọjọgbọn Lawrence Adewọle (OAU) & A. A. Fabeku
Lámèétọ́: Olugbenga Ọlabiyi
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ
Kẹ́mísírì (1) jẹ́ ẹ̀ka sáyẹ́ǹsì àrígbéwọ̀n (physical science) (2) tí ó ṣeé dán wò (2) tí ó jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ tí ó ń kọ́ ni nípa èròjà (4), ìhun (5) àti ìyídà (6) ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter) tí ó wà ní àgbáálá ayé (7). Kẹ́míìsírì tún máa ń kọ́ ni nípa òfin tí ó ṣe àlàyé ìyídà yìí. Kẹ́mísírì níí ṣe pẹ̀lú àtòpọ̀ (combination) tàbí àsèìtakora (reaction) èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (substance). Ìyẹn ni bí a ṣe lè to èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n kan pọ̀ mọ́ òmíràn tàbí bí a ṣe lè fi èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n kan ta ko òmíràn.
Kí ni ọ̀gbààyègbéwọ̀n?
Ọ̀gbààyègbéwọ̀n (8) jẹ́ ohunkóhun tí ó ní ìwọ̀n-okun (9) tí ó sì gba áyè. Ohun tí a pè ní ọ̀gbààyègbéwọ̀n yìí lè tóbí, ó sì lè kéré. A lè fi ojú rí i (tí ó bá tóbi tó nǹkan tí a lè fojú rí tàbí kí a má fi ojú rí i tí ó bá kéré ju ohun ti a lè fi ojú wa lásán rí tí ó jẹ́ pé a ó nílò awò amóhuntóbi (‘magnifying glass’) kí á tó lè rí i). Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé bí ó ti wù kí ó kéré tó, ohunkóhun tí ó bá ti ní ìwọ̀n-okun tí ó sì gba àyè ni a mọ̀ sí ọ̀gbààyègbéwọ̀n (matter). Ìwọ̀n-okun àti ìwúwo (10) bá ara wọn tan ṣùgbọ́n, síbẹ̀, wọ́n yàtọ̀ sí ara wọn gédégédé. Àwọn àpẹẹrẹ ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni afẹ́fẹ́, omi, òkúta, igi, ohun ọ̀gbìn, ẹranko, ènìyàn, alùgbinrin (11) àti gbogbo ohun tí ó yí wa ká, yálà, èyí tí a lè fi ojú rí tàbí èyí tí a kò lè fi ojú lásán rí.
Kí ni Ìwọ̀n?
Iwọ̀n ni iye (12) ọ̀gbààyègbéwọ̀n (13) tí ó wà nínú èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (14). Ìwọ̀n ni àbùdá tí nǹkan ní tí ó fi máa ń fẹ́ wà lóju kan láìpara dà tàbí kí ó máa lọ láìdúró.
Kí ni ìwúwo?
Ìwúwo (‘weight’) ni ipa tí òòfa lááláátóròkè (gravity) ní lórí ìwọ̀n-okun (mass) (15).
Àbùdá ọ̀gbààyègbéwọ̀n
A lè dá ọ̀gbààyègbéwọ̀n (‘matter’) mọ̀ nípa wíwo oríṣiríṣi àbùdá (16) tí ó ní. Oríṣi àbùdá méjì ni ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni. Èkíní ni àbùdá òde (17) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ni. Èkejì ni àbùdá inú (18) tí ọ̀gbààyègbéwọ̀n ní. Àbùdá òde ti ọ̀gbààyègbéwọ̀n jẹ́ èyí tí a lè rí, tí a lè fi ọwọ́ kàn tàbí tí a lè wọ̀n nípa lílo ojú wa, etí wa, imú wa, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé a máa nílò àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ẹ̀rọ kí á tó lè lo ọ̀kan tàbí òmíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara láti fi mọ àwọn àbùdá wọ̀nyí (19) .
Àyànkọ (note)
- Orúkọ mìíràn fún kẹ́mísírì ni ìmọ̀ èrójà ẹ̀dá. Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, a máa ń pe nǹkan kan ní ‘substance’. ‘Substance’ yìí ni a lè pè ní ohun tí ó níí ṣẹ pẹ̀lú ọ̀gbààyègbéwọ̀n tí ó jẹ́ pé a lè fojú rí i tàbí kí a fọwọ́ kàn àn tàbí kí ó ṣeé wọ̀n. Tí a bá ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ohun tí a pè ní ‘substance’ yìí àti ọ̀nà tí a fi lè tò ó mọ́ irú rẹ̀ mìíràn (combine) tàbí kí ohun tí a pè ní ‘substance’ yìí torí nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí irú rẹ̀ mìíràn (act) ṣe nǹkan kan (react), irú ẹ̀kọ́ yìí ni a ń pè ní Kẹ́mísírì.
- À̀rígbéwọ̀n ni ohun tí a lè fojú rí tàbí tí a lè fọwọ ́kàn tàbí tí a lè wọ̀n.
- Bí a bá dán nǹkan wò ni a fi máa ń mọ bí nǹkan náà ṣe rí gan-an.
- Bí a bá fọ́ nǹkan kan sí wẹ́wẹ́, àwọn nǹkan tí a lè bá nínú nǹkan náà ni èròjà nǹkan náà
- Ìhun ni bí a ṣe to nǹkan pọ̀̀. Ètò tí a lè sọ pé nǹkan kan ní ni a ń pè ní ìhun nǹkan náà.
- Ìyídà máa ń yí ìrísí tàbí àbùdá nǹkan padà, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kí nǹkan náà lè dára sí i
- Àgbáálá ayé dúró fún àwọn ìràwọ, ayé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
- Ẹ̀dá ni a ń pè ní ‘matter’ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ̀dá máa ń ní èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n (‘substance’).
- Nìnù Kẹ́mísírì, ohun tí a ń pè ní ìwọ̀n-okun ni ‘mass’. Tí ó bá jẹ́ inú Físíìsì ni, ìṣù tàbí títóbi nǹkan ni a ń pè ni ‘mass’.
- ‘Weight’ yìí ni a ń pè ní ìtẹ̀wọ̀n nínú ẹ̀kọ́ Físíìsì. Lára oríkì (definition) tí a lè fún ìtẹ̀wọ̀n yìí ni (i) ipá (force) tí ó dorí kọ ilẹ̀ tí nǹkan kan ní nítorí títóbi (mass) rẹ̀ (ii) ìmúrasaré (acceleration) nítorí ìfàlọsílẹ̀ (pull) ilẹ̀ ayé.
- Àwọn ohun tí a bá lù tí ó bá ń dún bí irin ni a ń pè ní alugbinrin.
- Iye dúró fún bí nǹkan kan ṣe pọ̀ tó.
- Ọ̀gbààyègbéwọ̀n dúró fún ‘matter’.
- Èròjà ọ̀gbààyègbéwọ̀n dúró fún ‘substance’.
- Ayé ní òǹfà tí ó fi ń fa àwọn ohun tí ó wà ní inú rẹ̀ wá sí orí ilẹ̀ tàbí kí ó fa nǹkan kan mọ́ra. Èyí ni a ń pè ní ipá òòfa lááláátóròkè (‘force of gravity’).
- Àbùdá ni ìrísí tí nǹkan kan ní. Èyí ni àwọn ohun tí a ń wọ mọ́ ǹnkan lára tí ó fi ƴàtọ̀ sí nǹkan mìíràn.
- ‘Physical properties’ ni àwọn àbùdá òde tí ẹ̀dá ní.
- ‘Chemical properties’ ni àwọn àbùdá inú tí ẹ̀dá ni.
- Bí àpẹẹrẹ, bí nǹkan kan bá kéré jù, a lè nílò awò amóhuntóbi (magnifying glass) kí a tó lè rí i dáadáa.
Ipá (force)| Olugbenga Ọlabiyi
Lámèétọ́: Lateef Adeleke
Aṣàgbéjáde: Taofeeq Adebayọ
A ti sọ̀rọ̀ nípa ìsípòpadà (motion), èyí tí ó túmọ̀ sí ìpapòdà láti ibìkan sí ibòmíràn. Ní báyǐ, a fẹ́ ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tó ń fa ìpapòdà nkán láti ibìkan sí ibòmíràn. Kí ni ohun tó ń se okùnfà ìṣípòpadà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fi yé wa pé ipá (force) ni ó ń ṣe okùnfà bí nkan se n lọ síwájú, sẹ́yìn tàbí bí ó se ń yí ní òbírípo (rotation). Ǹjẹ́ kínni ipá tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yíí?
Ipá ni a lè pè ní ohun tí ó le mù kí ǹkan kúrò ní ojú kan tàbí kí ìyára (velocity) rẹ̀ yí padà. Ipá jẹ́ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ṣòro láti se àlàyé sùngbọ́n ó jẹ́ ọ̀rọ́ tí a máa ńlò ní ìgbà dé ìgbà. Síwájú si, ipá jẹ́ ohun tí ó lágbára tí ó sì le mú kí nkàn tó wà lójúkan sún (move). Bákan náà, ipá le sè àyípadà ètò ọkọ̀ tí ó wà lórí ìrìn. Fún àpẹẹrẹ, abọ́ ìmùkọ wa yíò wà ní ibi tí a fi sí àfi tí a bá lo ipá. Bẹ́ẹ̀ni, ipá le è ṣe àyípadà eré (speed) ọkọ̀ tó ń lọ, yàlá láti yára síi (speed up) tàbí lọ́ra (slow down). Láfikún, ipá le rọ irin, ó le è tẹ agolo, ó le è da ètò nǹkàn rú, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìsọ̀rí méjì ni à le pín ipá sí. Àwọn nì wọ̀nyí:
- Ipá ìfarakínra (contact force). Èyi jẹ́ ipá tí ó gbọ́dọ̀ fara kan ohun tí a fẹ́ lò ó fún. Àpẹẹrẹ: fífa (pulling) nǹkan, tìti (pushing) nǹkan, ìfàle líle (tension), ipá ìfaragbora (frictional force), ̣ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
- Ipá áìfarakínra (non-conatct force)/ force field (pápá ipá): irú ipá yìí jẹ́ èyí tí kò ní lò kí á fi ara kan ohun tí a fẹ́ lò ó fún. Èyí ni àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀: ípá òòfà-laáláatóròkè (gravitational force), ipá òòfà (magnetic force), ipá òjíjí (electrical force), àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.